Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

Ìgbéyàwó Ìbílẹ́ Yorùbá: “Ọ̀gá Méji Kò Lè Gbé inú Ọkọ̀” – Yoruba Traditional Marriage Ceremony: “Two Masters cannot steer a ship”

Adarí Ètò Ijoko àti “Adarí Ètò Ìdúró – Traditional Master of Ceremony.  Courtesy: @theyorubablog

Adarí Ètò Ijoko àti “Adarí Ètò Ìdúró – Traditional Master of Ceremony. Courtesy: @theyorubablog

A ṣe àkíyèsí pé wn ti s iṣẹ́ ìyàwó-ilé di òwò nibi ìgbéyàwó ìbíl̀̀̀̀̀̀ẹ̀, pàtàki ni àwn ilú nlá, nítorí èyí “ó ju alaga méjì tó ngbe inú ọkọ̀ bẹ .  Wọn pè ìkan ni “Alaga Ìdúró” wọn pe ìkejì ni “Alaga Ijoko”.  Gẹgẹbi àṣà ilẹ Yorùbá, kòsí bí “Ìyàwó ilé ti lè jẹ “Alaga” lórí ẹbí ọkọ tàbí ẹbí ìyàwó ti a ngbe.  Ọkunrin ti o ti ṣe ìyàwó ti o yọri fún ọpọlọpọ ọdún, ti o si gbayí láwùjọ, yálà ni ìdílé ìyàwó tàbí ìdílé ọkọ ni a nfi si ipò “ALAGA” tàbí “OLÓRÍ ÀPÈJỌ.

Ìyàwó àgbà ni ìdílé ọkọ àti ti ìyàwó ni o ma nṣe aṣájú fún áwọn ìyàwó ilé yoku lati gbé tàbí gba igbá ìyàwó ni ibi ìgbéyàwó ìbílẹ.  Ni ayé òde oni, a ṣe àkíyèsí wipé, ìdílé ìyàwó àti ọkọ, a san owó rẹpẹtẹ lati gba àwọn ti o yẹ ki a pè ni “Adarí Ètò Ijoko” fún bi Ìyàwó àti “Adarí Ètò Ìdúró” fún bi Ọkọ-ìyàwó”.  Lẹhin ti àwọn obìnrin àjòjì yi ti gba owó iṣẹ́, wọn a sọ ara wọn di “Ọ̀GÁ”, wọn a ma pàṣe, wọn a ma ṣe bí ó ti wù wọn lati tún rí owó gbà lọ́wọ́ àwọn ẹbí mejeeji.  Nípa ìwà yí, wọn a ma fi àkókò ṣòfò.  Yorùbá ni “Alágbàtà tó nsọ ọjà di ọ̀wọ́n”.

“Ṣe bí wọn ti nṣe, ki o ba le ri bi o ṣe nri”,   o yẹ ki  á ti ọẃọ àṣàkasà yi  bọlẹ̀.  Ko ba àṣà mu lati sọ “Aṣojú awọn ìyàwó-Ilé” di “ALAGA”.  Ipò méjèjì yàtọ sira, ó dẹ y ki o dúró bẹ nítorí ọ̀gá méjì kò lè gbé inú ọkọ̀ kan.

ENGLISH TRANSLATION

It can easily be observed that Traditional marriages have turned largely commercial in nature and as a result of this there are more than two captains in such a ship.  One is called “SEATING IN CHAIRMAN” while the second is called “STANDING IN CHAIRMAN”.  In Yoruba culture, “a Housewife” cannot be made the CHAIRMAN over her husband’s family in either the Bride or the Groom’s Family.  The Chairman in the Traditional Marriage is often an honourable man with many years of married life, carefully chosen from either the Bride or Groom’s family. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-24 23:25:22. Republished by Blog Post Promoter

“Èèmọ̀ ni ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin ni Àṣà Yorùbá ” – “Same Sex Marriage is a strage occurrence to Yoruba Traditional Marriage”

Ilé Ẹjọ́ Àgbà yi Àṣà Ìgbéyàwó Àdáyébá padà ni ilú Àmẹ́ríka.  Ni ọjọ́ Ẹti, Oṣù kẹfà, ọjọ́ Kẹrindinlọ́gbọ́n, ọdún Ẹgbãlemẹdógún, Ilé Ẹjọ́ Àgbà ti ilú Àmẹ́ríkà ṣe òfin pé “Kò si Ìpínlẹ̀ Àmẹ́ríkà ti ó ni ẹ̀tọ́ lati kọ igbéyàwó laarin ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin tàbi obinrin pẹ̀lú obinrin”.  Ijà fún ẹ̀tọ́ lati ṣe irú igbeyawo yi ti wà lati bi ọdún mẹrindinlãdọta sẹhin, ṣùgbọ́n ni oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbãlemẹ́tàlá, Ilé Ẹjọ́ Àgbà fi àṣẹ si pé ki Ìjọba Àpapọ̀ gba àṣà ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin, lati jẹ ki àwọn ti ó bá ṣe irú igbéyàwó yi lè gba ẹ̀tọ́ ti ó tọ́ si igbéyàwó àdáyébá – ohun ti ó tọ́ si ọkùnrin ti o fẹ́ obinrin, nipa ogún pinpin, owó ori tàbi bi igbéyàwó ba túká.

Julia Tate, left, kisses her wife, Lisa McMillin, in Nashville, Tennessee, after the reading the results of the <a href="http://www.cnn.com/2013/06/26/politics/scotus-same-sex-main/index.html">Supreme Court rulings on same-sex marriage</a> on Wednesday, June 26. The high court struck down key parts of the <a href="http://www.cnn.com/interactive/2013/06/politics/scotus-ruling-windsor/index.html">Defense of Marriage Act</a> and cleared the way for same-sex marriages to resume in California by rejecting an appeal on the state's <a href="http://www.cnn.com/interactive/2013/06/politics/scotus-ruling-perry/index.html">Proposition 8</a>.

Obinrin fẹ́ obinrin – Lesbian Relationship reactions to the Supreme Court Ruling

Ìjọba-àpapọ̀ ti ilú Àmẹ́ríkà gba òfin yi wọlé nitori “Òfin-Òṣèlú ni wọn fi ndari ilú Àmẹ́ríkà”.  Lati igbà ti ìròyìn ìdájọ́ yi ti jade, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àgbáyé, pàtàki àwọn Ẹlẹ́sin Igbàgbọ́ ti nda ẹ̀bi fún Ìjọba Àmẹ́ríkà pé wọn rú òfin Ọlọrun nipa Igbéyàwó.

Ni àṣà igbéyàwó Yorùbá, èèmọ̀ ni ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin.  Ki ẹbi ma ba parẹ́, ọmọ bibi jẹ ikan ninú ohun pàtàki ni igbéyàwó.  Bi ọkùnrin bá fẹ́ ọkùnrin, wọn ò lè bi ọmọ lai si pé wọn gba ọmọ tọ́ tàbi ki wọn wa obinrin ti yio bá wọn bi ọmọ tàbi bi ó bá jẹ laarin obinrin meji ti ó fẹ́ ara, ikan ninú obinrin yi ti lè bimọ tẹ́lẹ̀ tàbi ki ó wá ọkùnrin ti yio fún ohun lóyún ki wọn lè ni ọmọ ni irú igbéyàwó yi.

Yorùbá ni “Bi a ti nṣe ni ilé wa, èèwọ̀ ibòmíràn” òfin Àmẹ́ríkà yi jẹ́ èèmọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá nitori a kò gbọ tàbi ka a ninú itàn àṣà Yoruba  .  Ki ṣe gbogbo èèmọ̀ ni ó dára, fún àpẹrẹ, ni igbà kan ri èèmọ̀ ni ki èniyàn bi àfin, tàbi bi ibeji nitori eyi, wọn ma npa ikan ninú àwọn meji yi ni tàbi ki wọn jù wọn si igbó lati kú, ṣùgbọ́n láyé òde òni àṣà ji ju ibeji tàbi ibẹta si igbó ti dúró.  Kò yẹ ki ẹnikẹni pa ẹnikeji nitori àwọ̀ ara tàbi nitori ẹni ti èniyàn bá ni ìfẹ́ si.  Ni ilú Àmẹ́ríkà ni àwọn ti ó fi ẹsin Ìgbàgbọ́ bojú ti kó si abẹ́ àwọn Aṣòfin ilú Àmẹ́ríkà ni ayé àtijọ́ pé Aláwọ̀dúdú ki ṣe èniyàn, nitori eyi, ó lòdi si òfin ki Aláwọ̀dúdú fẹ́ Aláwọ̀funfun, bi wọn bá fẹ́ra, wọn kò kà wọn kún tàbi ka irú ọmọ bẹ ẹ si èniyàn gidi.  Bẹni wọn lo òfin burúkú yi naa lati pa Aláwọ̀dúdú lẹhin isin ni aarin igboro lai ya Aláwọ̀dúdú ti wọn kó lẹ́rú lati ilẹ Yorùbá sọtọ.  Ogun abẹ́lé àti ṣi ṣe Òfin Àpapọ̀ tuntun lẹhin ogun, ni wọn fi gba àwọn Aláwọ̀dúdú silẹ̀ ni ilú Àmẹ́ríkà.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-07-21 19:46:00. Republished by Blog Post Promoter

“A ò mọ èyi ti Ọlọrun yio ṣe, kò jẹ́ ki á binú kú” – “We know not what God will do, stops one from committing suicide”

Àṣà Yorùbá ma ńri ọpẹ́ ninú ohun gbogbo, nitori eyi ni àjọyọ̀ àti ayẹyẹ ṣe pọ ni ilẹ̀ Yorùbá.  Bi kò bá ṣe ayẹyẹ igbéyàwó; á jẹ́ idúpẹ́ fun ikómọ/isọmọlórúkọ; ìsìnku arúgbó; ikóyọ ninú ewu ijàmbá ọkọ̀; iṣile; oyè gbigbà ni ilé-iwé giga tàbi oyé ilú; idúpẹ́ ìparí ọdún tàbi ọdún tuntun àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  Kò si igbà ti àlejò kò ni ri ibi ti wọn ti ńṣe ayẹyẹ kan tàbi èkeji ni gbogbo ilẹ́ Yorùbá.  Eyi jẹ́ ki àlejò rò wipé igbà gbogbo ni Yorùbá fi ńṣọdún.

Kò si ẹni ti o ńdúpẹ́ ti inú rẹ ńbàjẹ́, tijó tayọ̀ ni enia fi nṣe idúpẹ́.  Ninú idúpẹ́ àti àjọyọ̀ yi ni ẹni ti inu rẹ bàjẹ́ miran ti lè ni ireti pé ire ti ohun naa yio dé.  Ni ilú Èkó, lati Ọjọ́bọ̀ titi dé ọjọ́ Àikú ni enia yio ri ibi ti wọn ti ńṣe ayẹyẹ.  Ọjọ́bọ̀ jẹ ọjọ́ ti wọn ńṣe àisùn-òkú; ọjọ́ Ẹti ni isinkú, ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ti ayẹyẹ igbéyàwó nigbati ọjọ́ Àikú wà fún idúpẹ́ pàtàki ni ilé ijọsin onigbàgbọ́.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayẹyẹ yi ló mú ipèsè jijẹ, mimu, ilù àti ijó lati ṣe àlejò fún ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ ti ó wá báni ṣe ayẹyẹ.

A lè fi òwe Yorùbá ti ó ni “A ò mọ èyi ti Ọlọrun yio ṣe, kò jẹ́ ki á binú kú”, tu ẹni ti ó bá ni ìrẹ̀wẹ̀sì ninú, pé ọjọ́ ọ̀la yio dára.   Yorùbá gbàgbọ́  pé ẹni ti kò ri jẹ loni, bi kò bá kú, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, lè di ọlọ́rọ̀ ni ọ̀la. Nitori eyi, kò yẹ ki enia “Kú silẹ̀ de ikú” nitorina, “Bi ẹ̀mi bá wà, ireti ḿbẹ”.

ENGLISH TRANSLATION
Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-04-15 10:03:30. Republished by Blog Post Promoter

Kò si ọgbọ́n to lè dá, kò si ìwà ti o lè hù, ti o lè fi tẹ́ aiyé lọ́rùn – Ìtàn Bàbá Oní-kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́: “No amount of wisdom or character displayed can please the world.

Oni - kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́  - The Horseman & his son

Oni – kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ – The Horseman & his son

Ni aiyé àtijọ́, ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ló dàbi ọkọ̀ igbàlódé ti wọn ńpè ni mọ́tò.  Ẹni ti ó jẹ́ ọlọ́rọ̀, ló lè ni ẹsin tàbi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Ẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ńrin irin àjò.

Ìtàn yi dá ló̀ri Bàbá àti ọmọ rẹ ti wọn ńsin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Wọn múra lati rin irin àjò.  Gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá lati bu ọ̀wọ̀ fún àgbà, Bàbá ló gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ rẹ bẹ̀rẹ̀ si rin tẹ̀lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Àwọn enia ti o ri wọn ni “Bàbá, iwọ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ ńrin ni ilẹ̀”.  Nitori ọ̀rọ̀ yi, Bàbá bọ́ silẹ̀, ó gbé ọmọ rẹ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Àwọn aiyé tún ri wọn ni “Bàbá ńrin nilẹ̀, ọmọ ńgun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́”.  kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ti dàgbà, ṣùgbọ́n tori ẹnu aiyé, Bàbá àti ọmọ bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn.  Wọn ko ti rin jinà nigbati àwọn ti ó ri wọn tún ni “Ẹ wo Bàbá àti ọmọ tó fẹ́ pa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́”.  Nitori àti tẹ́ aiyé lọ́run, Bàbá àti ọmọ bọ́ silẹ̀, wọn bẹ̀rẹ̀ si fi ẹsẹ̀ rin tẹ̀lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Àwọn arin irin àjò yókù tún ri wọn, wọn ni “Ẹrú aiyé ni àwọn eleyi, bawo ni wọn ṣe lè ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ki wọn ma fi ẹsẹ̀ rin?”

Nigbati Bàbá ti gbìyànjú titi, ti kò mọ ohun ti ó tún lè ṣe mọ́, lati tẹ́ aiyé lọ́rùn ni ó ránti ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ni “Kò si ọgbọ́n ti o lè dá, kò si iwà ti o lè hù, ti o lè fi tẹ́ aiyé lọ́rùn”.

Yorùbá ni “Ẹni à ḿbá ra ọjà là ńwò, a ki wó ariwo ọjà̀”.  Lára nkan ti itàn yi kọ́ wa ni pé: ohun ani là ńlò; ibi ti à ńlọ ni ká dojú kọ lai wo ariwo ọjà àti pé enia ni lati ni ọkàn tirẹ̀ nitori kò si ẹni ti ó lè tẹ́ aiyé lọ́rùn.

Ẹ gbọ bi ògúná gbòngbò ninú àwọn ọ̀gá ninú olórin ilẹ̀ Yorùbá àti ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú – “Chief Ebenezer Fabiyi” ti a mọ si “Olóyè Adarí” ti fi itàn yi kọrin.

Ebenezer Obey – The Horse, The Man and The Son

ENGLISH LANGUAGE Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-04-15 22:41:38. Republished by Blog Post Promoter

“Ilé làbọ̀ simi oko, ṣùgbọ́n bi ilé bá sanni àwọ̀ là nwò”: “Home is for rest on return from the farm, but the convenience of the home is a reflection on the skin”

sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ - Lagos Traffic jam.  Courtesy:  @theyorubablog

sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ – Lagos Traffic jam. Courtesy: @theyorubablog

Gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá, pataki àwọn ti o fi ìfẹ́ tẹ̀ lé  àkọ-sílẹ̀ ọ̀rọ̀ gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá́  lárugẹ lóri ẹ̀rọ ayélujára, mo jẹ yin ni àlàyé ohun ti ojú ri lẹhin àbọ̀ oko.  Ẹ o ṣe akiyesi wípé, ìwé kikọ wa din kù diẹ nitori adarí ìwé lọ bẹ ilé wò fún ìgbà diẹ.  Ni gbogbo àsìkò ti adarí ìwé fi wa ni ilé (Nigeria), ìṣòro nla ni lati lè kọ ìwé lori ayélujára nitori dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná.

Lagos

Lagos

Ó ṣeni lãnu pé “oko” ninu àlàyé yi (òkè-òkun/ìlú-oyinbo) sàn ju “ilé” Èkó.  Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, “kàkà ki ewé àgbọn dẹ, koko ló tún nle si”.  Ni totọ, àwọn Oní-ṣòwò ni orílẹ̀ èdè Nigeria ǹgbìyànjú, nitori kò rọrùn lati ṣòwò ni ìlú ti ohun amáyé-dẹrùn ti ìgbàlódé bi iná mona-mona, òpópónà tó dára, omi mimu, àbò, àti bẹbẹ̃ lọ, kò ti ṣe dẽde.  A ṣe akiyesi pé nkan wọ́n ni ilé ju oko lọ, pataki ìnáwó lórí ounjẹ, ẹrọ iná mọ̀nà-mọ́ná àti ọkọ̀ wíwọ̀.  Ai si iná, ariwo ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná, fèrè ọkọ̀ àti sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki akọ̀we yi gbádùn ilé bi oko.

A lè sọ wípé àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ngbiyanju, ṣùgbọ́n “omi pọ̀ ju ọkà lọ”.  Àyè iṣẹ́ ti ó yẹ ki Ìjọba àpapọ̀ ṣe ti wọn kò ṣe ńfa ìnira fún ará ìlú.  “Ẹ̀bẹ̀ là ńbẹ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe”, nitori eyi, a bẹ Ìjọba àti àwọn Gómìnà pé ki wọn sowọ́ pọ̀ lati tú orílẹ̀ èdè ṣe ni pataki ìpèsè ohun amáyé-dẹrùn.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-11-15 21:57:48. Republished by Blog Post Promoter

“Ránti Ọmọ Ẹni ti Iwọ Nṣe: Olè ki ṣe Orúkọ Rere lati fi Jogún” – “Remember the Child of Whom you are: Being labelled a ‘Thief’ is Not a Good Legacy”

Oriṣiriṣi òwe ni Yorùbá ni lati fihàn pé iwà rere ló ni ayé.  Iwà ni Yorùbá kàsí ni ayé àtijọ́ ju owó ti gbogbo ilú bẹ̀rẹ̀ si bọ ni ayé òde òni.  Fún àpẹrẹ, Yorùbá ni “Ẹni bá jalè ló bọmọ jẹ́”, lati gba òṣiṣẹ́ ni ìyànjú pé ki wọn tẹpámọ́ṣẹ́, ki wọn má jalè.

Ránti Ọmọ Ẹni ti Iwọ Nṣe - Leave a good legacy.  Courtesy: @theyorubablog

Ránti Ọmọ Ẹni ti Iwọ Nṣe – Leave a good legacy. Courtesy: @theyorubablog

Ni ayé òde òni, owó ti dipò iwà.  Olóri Ijọ, Olóri ilú àti Òṣèlú ti ó ja Ijọ àti ilú ni olè ni ará ilú bẹ̀rẹ̀ si i bọ ju àwọn Olóri ti kò lo ipò lati kó owó ijọ àti ilú fún ara wọn.  Owó ti ó yẹ ki Olóri Ijọ fi tọ́jú aláìní, tàbi ki Òṣèlú fi pèsè ohun amáyédẹrùn bi omi mimu, ọ̀nà tó dára, ilé ìwòsàn, ilé-iwé, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ ẹ bẹ ẹ lọ ni wọn kó si àpò, ti wọn nná èérún rẹ fún ijọ tàbi ará ilú ti ó bá sún mọ́ wọn.  Ará ilú ki ronú wi pé “Alaaru tó njẹ́ búrẹ́dì, awọ ori ẹ̀ ló njẹ ti kò mọ̀”.

Owé Yorùbá ti ó sọ wi pé “Ránti ọmọ Ẹni ti iwọ nṣe ” pin si ọ̀nà méji.  Ni apá kan, inú ọmọ ẹni ti ó hu iwà rere ni àwùjọ á dùn lati ránti ọmọ ẹni ti ó nṣe, ṣùgbọ́n inú ọmọ “Olè”, apànìyàn, àjẹ́, àti oniwà burúkú yoku, kò lè dùn lati ránti ọmọ ẹni ti wọn nṣe.  Nitori eyi, ki èniyàn hu iwà rere.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-09 15:29:50. Republished by Blog Post Promoter

Àgbo – Ewé àti Egbòigi fún ìtọ́jú – Yoruba Herbal remedies/Traditional medicine

Ki oògùn Òyinbó tó gbòde, ewé àti egbòigi ti ó wà ni oko tàbi àyíká ilé ni Yorùbá fi nki àgbo lati dí àisàn lọ́wọ́ tàbi wo àisàn.  Àwọn gbajúmọ̀ àti ọ̀dọ́ ayé òde òni ti kọ àgbo ti wọ́n fi ewé àti egbòigi ṣe fún oògùn àti iṣe Òyinbó.

Fún àkọsílẹ̀, Olùkọ̀wé èdè Yorùbá lóri ayélujára yi, yio bẹ̀rẹ̀ si ṣe àkọsílẹ̀ ewé àti egbòigi ti wọn fi ńto àgbo àti èyi ti ó wà fún itọ́jú ara.  A ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àgbo-ibà, nitori ibà ló wọ́pọ̀ jù ninú gbogbo oriṣiriṣi àrùn.

ENGLISH TRANSLATION

Most Yoruba elders above the age of fifty who grew up outside Lagos, were raised drinking herbal decoction or using herbs as preventive medicine or as curative.  Up till today, some Yoruba herbal decoction are still very popular for the prevention or cure of pile or haemorrhoid known in Yoruba as “Jẹ̀dí/Jẹ̀díjẹ̀dí”.

Prior to Western medicine, Yoruba people relied on local herbs as preventive medicine and for curing the sick.  There was a drift from exclusive reliant on herbal medicine for primary healthcare  to Western medicine and lifestyle, hence the neglect of local herbs especially by the elites and the youths. 

In order to preserve Yoruba traditional herbs, The Yoruba Blog and her team will begin to document online Yoruba local herbs and remedies.  Publication will begin with Malaria which is the most common ailment.

Share Button

Originally posted 2020-09-01 18:46:00. Republished by Blog Post Promoter

Ìkini Ọdún Ẹgbàálélógún – 2020 Yoruba Season Greetings

Share Button

Originally posted 2020-01-02 02:46:36. Republished by Blog Post Promoter

ỌJỌ GBOGBO NI TI OLÈ – Everyday is for the thief … a warning to fraudsters

ỌJỌ GBOGBO NI TI OLÈ, ỌJỌ KAN NI TOLÓHUN”: “EVERYDAY IS FOR THE THIEF, ONE DAY FOR THE OWNER”.

Ní ọjọ Ẹti ọjọ keji lelogun oṣu keji ọdún yi, Ẹrọ amóhùn máwòrán Iluọba (BBC 1) tu asiri ọmọkunrin kan ti o ni iwe ijẹri irina ọmọ Naijeria ni oruko ọtọtọ mẹta ti o fi nlu ìjọba ní jìbìtì gba iranlọwọ ti ko tọ si. O ti gba owó rẹpẹtẹ ki wọn to ri mu.

Ni Ìlú Ọba (United Kingdom) Ìjọba pese ilé fún awọn abirùn ati aláìní ti o jẹ ọmọ onilu ati iranlọwọ miran lati mu ayé dẹrùn fún wọn.  Àwọn àjòjì ti o fi èrú ati irọ gba àwọn iranlọwọ yi, wọn a dẹ tún fi ma yangan titi ọjọ ti olóhun yio fi muwọn.  Irú iwa burúkú bi ka fi èrú gba ohun ti ko tọ wọnyi mba orúkọ jẹ.

Ẹ jẹ ki a fi owé Yorùbá to wipe “Ọjọ gbogbo ni tolè, ọjọ kan ni tolóhun” se ikilo fun iru awọn oníjìbìtì bẹ ere jibiti, nitori bi o ti wu ko pẹ to, ọjọ kan ọwọ òfin a ba iru àwọn bẹ.  Nigbati wọn ba ri wọn mu, wọn a ko ìtìjú ba orúkọ idile ati ìlú wọn.

ENGLISH TRANSLATION

On Friday 22nd February 2013, BBC 1 Television Channel exposed a man with 3 Nigerian Passports in different names that he was using to defraud the Government by collecting benefits that he was not entitled to claim.  He had collected large sums of money before he was caught. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-22 20:58:21. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹ̀mí ti ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ”: “Life devoid of consumption of pepper is trifle”

Ata-ṣọmbọ, Ata-wẹ́wẹ́, Ata-Ijọsin, Ata gbigbẹ, Ata gígún àti awọn èlò ọbẹ̀ – Jalapeno, Serrano, Cayenne & various spices. Courtesy: @theyorubablog

Ata ṣe pàtàki ninu àwọn èlò ọbẹ̀.  Yorùbá ni “Ẹ̀mí ti ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ” nitori eyi, lai si ata ninu ọbẹ̀, ọbẹ̀ o pe.  Ko si ọbẹ̀ Yoruba ti enia ma jẹ lai ni ata, fún àpẹrẹ wọn ki jẹ ila funfun tàbi Ewédú ti wọn se lai ni ata lai bu ata ọbẹ̀ si.

Oriṣiriṣi ata: Ata-rodo, Ata-ṣọmbọ, Ata-wẹ́wẹ́, Ata-Ijọsin, Tataṣe, Ata gbigbẹ, Ata gígún

Àwòrán ata ti ó wá ni ojú ewé yi wọ́pọ̀ ni ọjà Yorùbá.

 

Atarodo – Habanero pepper. Courtesy: @theyorubablog

 

Tataṣe – Bell pepper. Courtesy: @theyorubablog

 

 

 

 

Ọbẹ̀ Yorùbá ti wọn fi ata gígún àti èlò ilẹ̀ wa se ki wọn bi ọbẹ̀ ìgbà lódé ti wọn fi èlò okere se.  Bi nkan ti wọn to ni ilu, a le fi Ẹ̃dẹgbẹrin Naira se ìkòkò àwọn ọbẹ̀ Yorùbá bi: ilá-àsèpọ̀, ẹ̀gúsí funfun, àpọ̀n, àjó àti bẹ̃bẹ lọ fún idile enia mẹfa.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-06 09:00:39. Republished by Blog Post Promoter