Originally posted 2017-12-06 00:23:08. Republished by Blog Post Promoter
Author Archives: Bim A
“A sọ̀rọ̀ ẹran ti o ni ìwo, igbin yọjú”: “Talking of animals with horns, the snail appeared”.
Ọ̀pọ̀ ẹranko ti ó ni ìwo lóri, ma nlo lati fi gbèjà ara wọ́n ti ewu bá dojú kọ wọ́n. Ni ìdà keji, ìwo igbin wà fún lati fura ninú ewu, nitorina, bi igbin bá rò pé ewu wa ni àyíká́, igbin àti ìwo rẹ̀, a kó wọ karaun fún àbò. Fún ẹranko àti igbin, ìwo ti ó le ẹranko àti ìwo rírọ̀ igbin wà fún iṣẹ́ kan naa, mejeeji wà fún àbò ṣùgbọ́n fún iwúlò ọ̀tọ̀tọ̀. O yẹ ki igbin mọ iwọn ara rẹ̀ lati mọ̀ pé irú ìwo ohun kò wà fún ohun ijà, lai si bẹ̃, wọ́n á tẹ igbin pa. A lè lo òwe Yorùbá ti ó ni “A sọ̀rọ̀ ẹran ti o ni ìwo, ìgbín yọjú” yi fún àwọn ẹ̀kọ́ wọnyi: a lè fi bá ẹni ti ó bá jọ ara rẹ lójú wi; aimọ iwọn ara ẹni léwu; ọgbọ́n wà ninu mi mọ agbára àti àbùkù ara ẹni; ki á lo ohun ti a ni fún ohun ti ó yẹ – bi a bá lo ìmọ̀ òṣìṣẹ́ fún irú iṣẹ́ ti wọn mọ̀, á din àkókò àti ìnáwó kù; àti bẹ̃bẹ lọ.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2013-08-23 11:48:23. Republished by Blog Post Promoter
Àmì – Yoruba Accent
Àmì – ṣe pàtàkì ni èdè Yorùbá nitori lai si àmì, àṣìwí tàbi àṣìsọ á pọ̀. Ọ̀rọ̀ kan ni èdè Yorùbá lè ni itumọ rẹpẹtẹ, lai si àmì yio ṣòro lati mọ ìyàtọ. Àmì jẹ ki èdè Yorùbá rọrùn lati ka.
Èdè Yorùbá dùn bi orin. Àwọn àmì mẹta wọnyi – ̀ – do, re, ́ – mi, (ko si ~ – àmì fàágùn mọ). Ori àwọn ọ̀rọ̀ ti a lè fi àmì si – A a, Ee, Ẹẹ, Ii, Oo, Ọọ, Uu. Ọ̀rọ̀ “i” kò ni àṣìpè nitori èyi a lè ma fi àmì si ni igbà miràn.
À̀pẹrẹ pọ, ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ li lo àmì lóri àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi:
ENGLISH TRANSLATION
Accent signs on words are very important in Yoruba language, because without it, there would be many mis-pronunciation. The same word in Yoruba language could have several meaning and knowing the difference could be difficult without the accent sign. Accent sign on words makes reading Yoruba easier. Continue reading
Originally posted 2019-02-10 03:12:41. Republished by Blog Post Promoter
Bi mo ṣe lo Ìsimi Àjíǹde tó kọjá – How I spent the last Easter Holiday
Ìsimi ọdún Àjíǹde tó kọjá dùn púpọ̀ nitori mo lọ lo ìsimi náà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ẹbí rẹ ni ilú Èkó.
Èkó jinà si ilú mi nitori a pẹ́ púpọ̀ ninú ọkọ̀ elérò ti àwọn òbí mi fi mi si ni idikọ̀ ni Ìkàrẹ́-Àkókó ni ipinlẹ̀ Ondó. Lára ilú ti mo ri ni ọ̀nà ni Ọ̀wọ̀, Àkúrẹ́, Ilé-Ifẹ̀ àti Ìbàdàn. A dúró lati ra àkàrà ni ìyànà Iléṣà. Ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ wa pàdé mi ni idikọ̀ ni Ọjọta ni Èkó lati gbémi dé ilé wọn.
Èkó tóbi púpọ̀, ilé gogoro pọ̀, ọkọ̀ oriṣiriṣi náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ti ilú mi lọ. Ilé ẹ̀gbọ́n Bàbá mi tóbi púpọ̀. Wọ́n fún èmi nikan ni yàrá. Yàrá mi dára púpọ̀, ó ni ilé-ìwẹ̀ àti ilé-ìgbẹ́ ti rẹ̀ lọ́tọ̀.
Ojojúmọ́ ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ ngbé mi jade lọ si oriṣiriṣi ibi ni Èkó. Ni ọjọ́ Ẹtì (Jimọ) Olóyin wọ́n gbé mi lọ si ilé-ìjọ́sìn, ẹsin ọjọ náà fa ìrònú nitori wọn ṣe eré bi wọn ṣe kan Jésù mọ́gi, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ Aj̀íǹde, èrò ti ó múra dáradára pọ̀ ni ilé-ìjọsìn, ẹ̀sìn dùn gidigidi. Mo wọ̀ lára aṣọ tuntun ti ìyàwó ẹ̀gbọ́n Bàbá mi rà fún mi fún ọdún Àjíǹde. Lati ilé-ìjọ́sìn ọmọdé, àwa ọmọdé jó wọ ilé-ìjọ́sìn àwọn àgbàlagbà. Wọn fún gbogbo wa ni oúnjẹ (ìrẹsì àti itan adìyẹ ti ó tóbi) lẹhin isin. Ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keji Àjíǹde, a lọ si etí òkun lati lọ gba afẹ́fẹ́. Ẹ̀rù omi nlá náà bà mi lakọkọ, ṣùgbọ́n nitori èrò àti àwọn ọmọdé pọ̀ léti òkun, nkò bẹ̀rù mọ. A jẹ oriṣiriṣi oúnjẹ, a jó, mo si tún gun ẹsin leti òkun.
Lẹhin ọ̀sẹ̀ meji ti ilé-iwé ti fẹ́ wọlé, ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ gbé mi padà lọ si idikọ̀ lati padà si ilú mi pẹ̀lú ẹ̀bún oriṣiriṣi lati fún ará ile. Inú mi bàjẹ́, kò wù mi lati padà, mo ké nitori mo gbádùn Èkó gidigidi.
ENGLISH TRANSLATION
I really had a nice time during the last Easter/Spring holiday because I spent the holiday with my paternal uncle (my father’s older brother) and his family in Lagos. Continue reading
Originally posted 2018-06-15 19:28:13. Republished by Blog Post Promoter
A ki sọ pé ki wèrè ṣe òkú ìyá rẹ̀ bi ó bá ṣe ri, bi ó bá ni òhun fẹ́ sún jẹ nkọ́? – Never trust an unstable/unpredictable person with life and death decision making
Oriṣiriṣi wèrè ló wà, nitori pé ki ṣe wèrè ti ó wọ àkísà ni ìgboro tàbi já sita nikan ni wèrè. Ẹnikẹni ti o nhu ìwà burúkú tàbi ṣe ìpinnu burúkú ni Yorùbá npè ni “wèrè”.
Ìpinnu ṣi ṣe, ṣe pàtàki ni ayé àtijọ́ àti òde òní. Òwe Yorùbá sọ wi pé “Bi ará ilé ẹni bá njẹ kòkòrò búburú, hẹ̀rẹ̀-huru rẹ̀ kò ni jẹ́ ki a sùn ni òru”. Àbáyọrí ìpinnu tàbi èrò burúkú kò pin si ọ̀dọ̀ ẹbi àwọn ti ó wà ni àyíká elérò burúkú, ó lè kan gbogbo àgbáyé. Fún àpẹrẹ, kò si ìyàtọ̀ laarin wèrè tó já sita nitori wèrè ni Yorùbá npe ọkọ tàbi ìyàwó ti ó ni ìwà burúkú, ẹbi burúkú, ọba ti ó nlo ipò rẹ lati rẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àti òṣèlu ti ó nja ilú ni olè lati kó owó ti wọn ji lọ si òkè òkun nibiti ohun amáyédẹrùn ti ilú wọn kò ni wà.
Gẹ́gẹ́ bi òwe Yoruba ti ó sọ wi pé “A ki sọ pé ki Wèrè ṣe òkú ìyá rẹ̀ bi ó bá ṣe ri, bi ó bá ni òhun fẹ́ sún jẹ nkọ́?” Ìtumọ̀ òwe yi ni wi pé ìpinnu pàtàki bi ìyè àti ikú kò ṣe é gbé lé wèrè lọ́wọ́. Ó yẹ ki àwọn ènìyàn gidi ti ori rẹ pé dásí ọkọ tàbi ìyàwó, ọba tàbi àwọn ti ó wà ni ipò agbára, òṣèlu ti o nfi ipò wọn jalè àti àwọn ti ó nhu ìwà burúkú yi lati din àbáyọrí ìwà burúkú lóri ẹbí, alá-dúgbò àti àgbáyé kù.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2017-11-03 22:47:56. Republished by Blog Post Promoter
BÍBẸ̀ ÈKÓ WÒ FÚN Ọ̀SẸ̀ KAN (ỌJỌ́ KEJÌ) – Visiting Lagos for a Week (Day 2)
You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 2(mp3)
Originally posted 2013-04-05 20:52:07. Republished by Blog Post Promoter
“Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” – “Not all that glitters is Gold”
Wúrà jẹ ikan ninú ohun àlùmọ́ni iyebiye, pàtàki fún ohun ẹ̀ṣọ́. Ẹwà Wúrà ki hàn, titi di ìgbà ti wọn bá yọ gbogbo ẹ̀gbin rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iná tó gbóná rara. Àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi fihàn pé bi Wúrà bá ti pọ̀ tó lára ohun ẹ̀sọ́ ló ṣe má wọn tó, ki ṣé bi ohun ẹ̀ṣọ́ bá ti dán tó tàbi tóbi. Fún àpẹrẹ, àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà kini tóbi, ó si dán ju àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà keji, ṣùgbọ́n ohun ẹ̀sọ́ Wúrà ninú aworan keji wọn ju ohun eso Wúrà kini ni ìlọ́po mẹwa. Ìyàtọ̀ ti ó wà ni Wúrà gidi àti àfarawé ni pé, Wúrà gidi ṣe é tà fún owó iyebiye lẹhin ti èniyàn ti lo o, kò lè bàjẹ, bi ó bá kán, ó ṣe túnṣe; ṣùgbọ́n àfarawé kò bá ara ẹlòmiràn mu, bi ó bá kán, kò ṣe é túnse; kò ki léwó.
Gẹ́gẹ́bi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà”, bẹni ki ṣe gbogbo èniyàn ti wọ̀n pè ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ló tó bi àwọn èniyàn ti rò. Ọ̀pọ̀ irú àwọn wọnyi, jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati ṣe àṣe hàn, òmiràn ja olè, gbọ́mọgbọ́mọ àti onirúurú iṣẹ́ ibi yoku. Gbogbo ohun ti wọn fi ọ̀nà èrú kó jọ wọnyi kò tó nkankan lára ọrọ̀ ti ẹlòmiràn ti ó ni iwà-irẹ̀lẹ̀ ni. Fún àpẹrẹ, owó ti àwọn Òṣèlú àti Òṣiṣẹ́-Ìjọba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fi èrú kó jọ, ti wọn nkó wá si Òkè-òkun tàbi fi mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú, kò tó ọrọ̀ ti ọmọdé ti ó ni ẹ̀bun-Ọlọrun ni Òkè-òkun ni.
A lè fi òwe “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” gba ẹnikẹ́ni ni iyànjú pé ki wọn ma ṣe àfarawé, tàbi kánjú lati kó ọrọ̀ jọ. Àfarawé léwu, nitori ki ṣe gbogbo ohun ti èniyàn ri ló mọ idi rẹ̀.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-09-30 22:55:23. Republished by Blog Post Promoter
“A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ” – “One does not acknowledge one’s child husband and also acknowledge her illicit affair”
Ni ayé àtijọ́, wọn ma ńfi obinrin fún ọkọ ni, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, obinrin á mú̀ àfẹ́sọ́nà lati fi hàn òbi, nitori Yorùbá gba ọmọ obinrin ni àyè lati lọ si ilé-iwé, tàbi kọ́ iṣẹ́-ọwọ́, àti lati ṣe òwò. Èyi jẹ ki obinrin kúrò lọ́dọ̀ obi wọn. Bi obinrin bá ti dàgbà tó bi ọdún meji-din-logun, ti ó tó wọ ilé-ọkọ, àwọn òbi yio ma ran léti pé, ó ti tó mú ọkọ wálé.
Ẹni ti obinrin mọ̀ pé òhun kò lè fẹ́, bi àfojúdi ni lati fi irú ọkùnrin bẹ̃ han òbi. Bi obinrin ti ó ti dàgbà tó lati wọ ilé ọkọ bá mú àfẹ́sọ́nà wá han òbi, wọn yio fi òwe Yorùbá ti ó ni “A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ” ṣe iwadi pé, ṣe ó da lójú pé òhun yio fẹ ọkùnrin ti ó mú wá? Òwe yi tún wúlò lati fi ṣe ikilọ nigbà igbéyàwó ibilẹ̀ fún obinrin pé kò lè mú ọkùnrin miràn wá lẹhin igbéyàwó.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-07-08 23:02:45. Republished by Blog Post Promoter
“ABD” ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ni èdè Yorùbá́ – Alphabets is the beginning of words in Yoruba Language
Bi ó ti ẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ nipa “abd” ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kikọ ni èdè Yorùbá sẹhin, a tu kọ fún iranti rẹ ni pi pè, kikọ àti lati tọka si ìyàtọ̀ larin ọ̀rọ̀ Yorùbá àti ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́si.
Fún àpẹrẹ, èdè Gẹ̀ẹ́si ni ibere oro mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nigbati èdè Yorùbá ni marun-din-lọgbọn. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn àwòrán ti o wa ni oju ewe wonyi:
ENGLISH TRANSLATION
Even though we have written about Yoruba Alphabets in the past, it is being re-written to remind readers on how it is pronounced, written and to point out the difference between the Yoruba and English Alphabets.
For example, English Alphabets are made up of twenty-six letter while Yoruba Alphabets are twenty-five. Check out the slides on this page.
Diference between Yoruba & English Alphabets
Originally posted 2014-02-04 19:04:40. Republished by Blog Post Promoter
ORÚKỌ ỌJỌ́: Days of the Week in Yoruba
Below are the Yoruba days of the week. Of course it is worth noting that very few native Yoruba speakers use these words in conversation.
SUNDAY ÀÌKÚ
MONDAY AJÉ
TUESDAY ÌṢẸ́GUN
WEDNESDAY ỌJỌ́RÚ
THURSDAY ỌJỌ́BỌ̀
FRIDAY ẸTÌ
SATURDAY ÀBÁMẸ́TA
Originally posted 2013-03-19 22:33:05. Republished by Blog Post Promoter