Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

Ẹ̀rù ló sọ ọmọ Ẹkùn di Ológbò/Ológìní tó fi di ” Ẹran-àmúsìn – Ọdẹ peku-peku” – “It is fear that turned the Tiger’s cub to the cat, that became a “domesticated – Rat Hunter”

Ni igbà àtijọ́, ẹranko ti wọn pè ni Ẹkùn jẹ alágbára ẹranko, bẹni Kìnìún si jẹ́ alágbára ẹranko.  Bi Kìnìún ti lágbára tó ninú igbó, bi ó bá bú ramúramù, ohun gbogbo ninú igbó á pa kẹ́kẹ́ titi dé ori ẹranko yoku. Ti Ẹkùn nikan ló yàtọ̀, nitori Ọlọrun fún ni ẹ̀bùn igbóyà, idi niyi ti a fi ńpè ni “Baba Ẹranko”, ti a ńpè Kìnìún ni “Ọlọ́là Ijù”.

Ni ọjọ́ kan, Ẹkùn gbéra lọ sinú igbó lati lọ wa oúnjẹ fún àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ẹ kéré wọn kò lè yára bi iyá wọn.  Ó fún wọn ni imọ̀ràn pe ki wọn kó ara pọ̀ si ibi òkiti-ọ̀gán ti ohun ti lè tètè ri wọn, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù fún ohunkóhun tàbi ẹranko ti ó bá wá si sàkáni wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Kìnìún àti Ẹkùn, ọ̀gá ni onikálùkù láyé ara wọn, wọn ki ja.  Ibi ti Kìnìún bá wà Ẹkùn kò ni dé ibẹ̀, ibi ti Ẹkùn bá wà Kìnìún ò ni dé ibẹ̀.  Nitori èyi ni Yorùbá fi npa lowe pé “Kàkà ki Kìnìún ṣe akápò Ẹkùn, onikálùkù yio má ba ọdẹ rẹ̀ lọ”.

Lai fà ọ̀rọ̀ gùn àwọn ọmọ Ẹkùn gbọ́ igbe Kìnìún, wọn ri ti ó ré kọja, àwọn ọmọ Ẹkùn ti ẹ̀rù ba ti kò ṣe bi iyá wọn ti ṣe ìkìlọ̀, ìjáyà bá wọn, wọ́n sá.  Nigbati Ẹkùn dé ibùdó rẹ lati fún àwọn ọmọ rẹ ni ẹran jẹ, àwọn ọmọ rẹ kò pé, ṣ̀ugbọ́n àwọn ọmọ ti ijáyà bá padà wá bá iyá wọn, nigbà yi ni iyá wọn rán wọn leti ikilọ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jáyà.  Nitori èyi, ohun kọ̀ wọ́n lọ́mọ.

Nigbati iyá wọn kọ̀ wọ́n lọ́mọ, wọn kò lè ṣe ọdẹ inú igbó mọ́, wọn di ẹranko tó ńrágó, ti wọn ńsin ninú ilé, to ńpa eku kiri.  Idi èyi ni Yorùbá fi npa ni òwe pé “Ìjayà ló bá ọmọ Ẹkùn ti ó di Ológbò ti ó ńṣe ọde eku inú ilé.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-03-29 10:45:48. Republished by Blog Post Promoter

“Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà” – “Headship of a Family is the Father of Responsibilities”

Olóri Ẹbi - Head of the Family connotes responsibiliies.  Courtesy: @theyorubablog

Olóri Ẹbi – Head of the Family connotes responsibiliies. Courtesy: @theyorubablog

Olóri Ẹbi jẹ àkọ́bi ọkùnrin ni idilé.  Bi àkọ́bi bá kú, ọkùnrin ti ó bá tẹ̀le yio bọ si ipò.  Iṣẹ́ olóri ẹbi ni lati kó ẹbi jọ fún ilọsiwájú ẹbi, nipa pi pari ijà, ijoko àgbà ni ibi igbéyàwó, ìsìnkú, pi pin ogún, ìsọmọ-lórúkọ, ọdún ìbílẹ̀ àti ayẹyẹ yoku.

Ni ayé òde òni, wọn ti fi owó dipò ipò àgbà, nitori ki wọn tó pe olóri ẹbi ti ó wà ni ìtòsí, wọn yio pe ẹni ti ó ni owó ninú ẹbi ti ó wà ni òkèrè pàtàki ti ó bá wà ni Èkó àti àwọn ilú nla miran tàbi Ilú-Òyinbó/Òkè-Òkun. Ai ṣe ojúṣe Ìjọba nipa ipèsè ilé-iwòsàn ti ó péye, Ilé-iwé, omi mimu àti ohun amáyédẹrùn yoku jẹ ki iṣẹ́ pọ fún olóri ẹbi.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ wi pé “Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà”, iṣẹ́ nla ni lati jẹ Olóri Ẹbi, ó gba ọgbọ́n, òye àti ìnáwó lati kó ẹbi jọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-02-12 10:30:05. Republished by Blog Post Promoter

“Ori bí bẹ́, kọ́ ni oògùn ori-fí fọ́” – A fi àsikò ọdún Keresimesi mú òbi àwọn ọmọbinrin ilé-iwé Chibok ti won ji ko, lọ́kàn le – Cutting off the head is not the antidote for headache – Using the Christmas season to encourage parents of the abducted Chibok School Girls to keep hope alive.

Yorùbá ni “Ibi ti ẹlẹ́kún ti nsun ẹkún ni aláyọ̀ gbe nyọ́”.  Òwe yi fihan ohun tó nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé.  Bi ọ̀pọ̀ àwọn ti ó wà ni Òkè-òkun ti nra ẹ̀bùn àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ ni oriṣiriṣi fún ọdún, bẹni àwọn ti kò ni owó lati ra oúnjẹ pọ ni àgbáyé.  Eyi ti ó burú jù ni àwọn ti ó wà ninú ibẹ̀rù pàtàki àwọn Onígbàgbọ́ ti kò lè lọ si ile-ijọsin lati yọ ayọ̀ ọdún iranti ọjọ́ ibi Jesu nitori ibẹ̀rù àwọn oniṣẹ ibi.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Ori bí bẹ́, kọ́ ni oògùn ori-fí fọ́”. Bawo ni pi pa èniyàn nitori kò gba ẹ̀sìn ṣe lè mú ki èrò pọ̀ si ni irú ẹ̀sìn bẹ́ ẹ̀?  Òkè-Ọya ni Àriwá Nàíjírià, Boko Haram npa èniyàn pẹ̀lú ibọn àti ohun ijà ti àwọn ti ó ka iwé ṣe, bẹni wọn korira, obinrin, iwé kikà, ẹlẹ́sìn- ìgbàgbọ́ ni Òkè-Ọya àti ẹni ti ó bá takò wọn pé ohun ti wọn nṣe kò dára.  Pi pa èniyàn kọ ni yio mu ki àwọn ará ilú gba ẹ̀sìn.

Free the Chibok Girls

Nigerian women protest against Government’s failure to rescue the abducted Chibok School Girls

A ki àwọn iyá àti bàbá àwọn ọmọ obirin ilú Chibok ti wọn ji kó lọ́ ni ilé-iwé, àwọn ẹbi ti ó pàdánù ọmọ, iyàwó, ọkọ, ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ibi – Boko Haram, pé ki Ọlọrun ki ó tù wọn ninú.  A fi àsikò ọdún Keresimesi mú òbi àwọn ọmọbinrin ilé-iwé Chibok ti won ji ko, lọ́kàn le, pé ki wọn ma ṣe sọ ìrètí nù, nitori “bi ẹ̀mi bá wà ìrètí nbẹ”.

 

ENGLISH TRANSLATION

According to Yoruba saying “As some are mourning, some are rejoicing”.  This adage is apt to describe the happenings around the world.  As many Oversea or in the developed World are spending huge sum for gifts and so much food for the yuletide, so also are many people in the world facing starvation as they have no money to buy food.  The worst, are those living in fear particularly the Christians that cannot go to places of worship to celebrate Christmas because of fear of the terrorists. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-23 21:35:53. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹ Kú Ọwọ́ Lómi Là Nki Ọlọ́mọ Tuntun – Ìtọ́jú Ọmọ Tuntun ni Àtijọ́”: “Greetings to the Nursing Mothers whose hands are always wet – Yoruba Culture of Nursing a Baby in the Old Days”

Ni ayé àtijọ́, kò si itẹdi à lò sọnù bi ti ayé òde òni.   Bẹni wọn kò lo ìgò oúnjẹ lati fún ọmọ tuntun ni oúnjẹ.

Ri rọ ọmọ - Yoruba Traditional baby feeding. Courtesy:@theyorubablog

Ri rọ ọmọ – Yoruba Traditional baby feeding. Courtesy:@theyorubablog

Ọwọ́ ọlọ́mọ tuntun ki kúrò ni omi nitori omi ni wọn fi nto àgbo ti wọn nrọ ọmọ fún ìtọ́jú ọmọ tuntun.  Aṣọ àlòkù Bàbá, Ìyá àti ẹbi ni wọn nya si wẹ́wẹ́ lati ṣe itẹdi ọmọ nitori kò si itẹdi à lò sọnú bi ti ayé òde òni.

Ọmọ tuntun a ma ya ìgbẹ́ àti ìtọ̀ tó igbà mẹwa tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ ni ojúmọ́.  Ọmọ ki i sùn ni ọ̀tọ̀, ẹ̀gbẹ́ ìyá ọmọ ni wọn ntẹ́ ọmọ si.  Lẹhin ọsẹ̀ mẹ́fà tàbi ogoji ọjọ́ tàbi ó lé kan ti wọn ti bi ọmọ, ìyá àti ọmọ lè lọ òde, ìyá á pọn ọmọ lati jáde.

Nitori aṣọ ni itẹdi kò gba omi dúró, bi ọmọ bá tọ̀ tàbi ya ìgbẹ́, á yi aṣọ ìyá tàbi ẹni ti ó gbé ọmọ.  Kò si ẹ̀rọ ifọṣọ igbàlódé nitori na a, ó di dandan ki wọ́n fọ aṣọ ọmọ àti ẹni ti ó gbé ọmọ ni igbà gbogbo ni ilé ọlọ́mọ tuntun.  Eyi ni ó jẹ́ ki Yorùbá ma ki ẹni ti ó bá ntọ ọmọ lọ́wọ́ pé “Ẹ kú ọwọ lómi” nitori ọwọ́ ki kúrò ni omi aṣọ fí fọ̀.

 

 

ENGLISH TRANSLATION

In the old days, there were no disposable diaper as common as it has become in recent times. Also, babies were not bottle fed. Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-03-04 23:03:05. Republished by Blog Post Promoter

“Orúkọ Yorùbá ti o ti inu Ẹsin Ìgbàgbọ jade” – “Yoruba names that originated from Christian Religion”

Yorùbá jẹ èrè àti ka Ìwé Mímọ́ ti a mọ̀ si “Bibeli Mímọ́” nitori iṣẹ́ ribiribi ti Olõgbe Olóri àwọn Àlùfáà Samuel Ajayi-Crowther ṣe lati túmọ Bibeli Mímọ́ si èdè Yorùbá ni Àádóje ọdún sẹhin.  Lati igbàyi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ ti yipadà si “Olúwa” dipò orúkọ Òrìṣà ibilẹ̀ bi “Ògún, Ọya, Ṣàngó, Ifá”, pàtàki laarin àwọn Onigbàgbọ́.  Nitori eyi,ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Yorùbá jade ninú Bibeli Mímọ́ ni èdè Yorùba.  Fún àpẹrẹ, “Samueli” túmọ̀ si Mofifólúwa; “Imanueli” – túmọ̀ si Oluwapẹlumi; Grace – Oreọfe àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò díẹ̀ ninú orúkọ Yorùbá ti o wọ́pọ̀ laarin àwọn Onigbàgbọ́ ni ojú ewé yi:

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba people benefitted from reading the Holy Book known as the “Holy Bible” as a result of the great work carried out by Late Bishop Samuel Ajayi Crowther who translated the “Holy Bible” into Yoruba Language about one hundred and thirty years ago (1884).  From that time, many Yoruba names changed to include “God or Lord” in the place of the traditional belief in the Yoruba deities such as “Ogun – god of Iron; Oya – river goddess of Niger River;  Sango – god of thunder; Ifa – Yoruba divination”, particularly among the Christians.  As a result, many Yoruba names were coined from the “Holy Bible”.   For example, “Samuel was translated to “Dedicated to God in Yoruba; Emmanuel – God is with me in Yoruba; Grace – free gift in Yoruba” etc.  Check out some of these Yoruba names that are common, particularly among the Christians on this page.

Orúkọ Yorùbá – Yoruba names Àgékúrú r – Short Form English meaning of Yoruba names
Àánúolúwapọ̀ Àánú God’s mercy is much/Mercy
Adéolúwa Adé/Déolú God’s crown
Àyànfẹ́olúwa Àyànfẹ́ God chosen one
Bólúwatifẹ́ Bólú As God wish
Damilareoluwa Damilare Justify me God
Didesimioluwa Dide Rise for me God
Ẹ̀bùnolúwa Ẹ̀bùn God’s gift
Faramólúwa/Faramólú Fara Cleave to God
Fẹ̀hintolúwa Fẹhin/Fẹ̀hintolú Rely on God
Ibùkúnolúwa Ibukun God’s Blessing
Ìfẹ́olúwa Ìfẹ́ God’s love
Ìkórèoluwa Ìkórè God’s harvest
Imọlẹoluwa Ìmọ́lẹ̀ God’s light
Ìníolúwa Ìní God’s property
Ireolúwa Ire God’s goodness
Ìrètí Ireti Hope
Ìtùnúolúwa Ìtùnú God’s consolation
Iyanuoluwa Iyanu God’s wonder
Jadesimioluwa Jade Show up for me God
Lànàolú Lànà Open the way Lord
Mofẹ́molúwa Mofẹ́/Mofẹ́molú I want to know God
Mofẹ́tolúwa Mofẹ́ I want God’s wish
Mofifólúwa Mofifólú Samuel/I dedicate him to God
Mofolúwaṣọ́/Mofolúṣọ́ Folúṣọ́ I use God to guide
Olumuyiwa Muyiwa God has brought this
Oluwadamilare Dami God has justified me
Olúwadémiládé Démiládé God has crowned me
Olúwafẹ́mi Fẹ́mi God loves me
Olúwafèyíkẹ́mi Fèyi/Kẹ́mi God used this to honour me
Olúwagbémiga/Oluwagbenga Gbenga God has lifted me
Olúwajọmilójú Jọmilójú God surprised me
Olúwakẹ́mi Kẹ́mi God cares for me
Oluwanifẹmi Nifẹmi God loves me
Olúwaṣẹ́gun Ṣẹ́gun God has given me victory
Oluwaṣeun Ṣeun Thank God
Oluwaṣeyi Ṣeyi God has done this
Oluwaṣijibomi Ṣiji God has shielded me
Oluwatamilọre Tamilọre God has given me gift
Olúwatóbi Tóbi God is great
Olúwatófúnmi Tófúnmi God is enough for me
Olúwatómi Tómi God is enough for me
Olúwatómilọ́lá Tómilọ́lá God is enough wealth for me
Olúwatóní Tóní God is enough to have
Oluwatosin Tosin God is worthy to be worshiped
Olúwawẹ̀mimọ́ Wẹ̀mimọ́ God has cleansed me
Oluwayẹmisi Yẹmisi God has honoured me
Oreọ̀fẹ́/Oreọ̀fẹ́olúwa Oore Grace/God’s grace
Oreolúwa Oore God’s present
Pamilẹrinoluwa Pamilẹrin Make me laugh God
Ṣadéfúnmiolúwa Ṣadé Give me a crown Lord
Ṣijúsimioluwa Ṣijú Look down on me God
Similólúwa Simi/Similólú Rest on God
Tanitoluwa Tanitolu Who is great as God?
Tẹjúmólúwa Tẹjú Concentrate on God
Tèmilolúwa Temi/Tèmilolú God is mine
Tẹniolúwa Tẹni God’s person
Tẹramólúwa Tẹra Persist with God
Tẹ́tisolúwa Tẹti Listen to God
Tirẹnioluwa Tirẹni It is yours Lord
Titobioluwa Tító God’s greatness
Tojúolúwa Tojú Apple of God’s eyes
Tọ́miolúwa Tọ́mi Train me God

 

Share Button

Originally posted 2014-08-12 20:59:28. Republished by Blog Post Promoter

ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ – TRADITIONAL MARRIAGE

Traditional Wedding Picture

Gifts at a modern Yoruba Traditional wedding — courtesy of @theYorubablog

Ìgbéyàwó ìbíle ní Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ àsìkò ti ẹbí ọkọ àti ì̀yàwó ma nparapọ.  Ìyàwó ṣíṣe ni ilẹ̀ Yorùbá kò pin sí ãrin ọkọ àti ìyàwó nikan, ohun ti ẹbí nparapọ ṣe pẹ̀lú ìdùnnú nípàtàkì lati gbà wọ́n níyànjú àti lati gba àdúrà fún wọn.

A lè ṣe gbogbo ètò ìgb́eyàwó ìbílẹ̀ ni ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ púpọ̀ fún àpẹrẹ: mọ̀mí-nmọ̀ẹ lọjọkan ati idana lọ́jọ́ keji tàbi ọjọ miran.  Ní ayé àtijọ́, nígbàtí Yorùbá ma nṣe ayẹyẹ níwọ̀ntúnwọ̀sín, ilé ẹbí tàbi ọgbà bàbá àti ìyá iyawo ni wọn ti nṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n láyé òde òní, àyè ọ̀tọ̀ bi ilé ìlú, pápá ìṣeré, ilé àlejò àti bẹ̃bẹ lọ ni wọ́n nlo.  Àṣà gbígba àyè ọ̀tọ tógbòde bẹ̀rẹ̀ nítorí àwọn adigun jalè àti àwọn ènìyàn burúkú míràn ti o ma ndarapọ pẹ̀lú àwọn àlejò tí a pè sí ibi ìyàwó lati ṣe iṣẹ́ ibi.  Owó púpọ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma nfi gba à̀yè ibi ṣíṣe ìyàwó.

Bí òbí ba ti lọ́lá tó ni wọn ma náwó tó, nitori ìdùnnú ni fún òbí pé a tọ́mọ, wọ́n gbẹ̀kọ́, wọn fẹ di òmìnira lati bẹ̀rẹ̀ ẹbí tíwọn, ṣùgbọ́n àṣejù ati àṣehàn ti wa wọ́pọ̀ jù. Nítorí ìnáwó ìgbéyàwó, ilé ayẹyẹ pọ̀ju ilé ìkàwé lọ láyé òde òní. Kí ṣe bi a ti náwó tó níbi ìgbéyàwó lo nmu àṣeyorí ba ọkọ àti ìyàwo, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ntuka láìpẹ́ lẹ́hin ariwo rẹpẹtẹ yi.    Yorùbá ni “A ki fọlá jẹ iyọ̀”, nínú ìṣẹ layika ni ilẹ̀ Aláwọdúdú, ó yẹ ki a ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó níwọ̀ntúnwọ̀nsìn.  Ẹ fojú sọ́nà fún ètò ìgbéyàwó ibilè.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-12 21:00:05. Republished by Blog Post Promoter

Òṣèlú Ẹ Gbé Èdè Yorùbá Lárugẹ: Politicians – Promote Yoruba Language

Yoruba, other Nigerian languages on the verge of extinction, Prof Akinwunmi Isola warns - News Sunday

Yoruba, other Nigerian languages on the verge of extinction, Prof Akinwunmi Isola warns

Nínú ìwé ìròyìn “Vanguard”, ti ọjọ́ Àìkú, oṣù kẹta, ọjọ́ , ọdún kẹrinlélógún, Ẹgbaalémétàlá, Olùkọ́ àgbà ti Èdè ati Àṣà, Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, kébòsí wípé èdè Yorùbá àti èdè abínibí miran le parun ti a ko bá kíyèsára.  Ìkìlọ̀ yí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún akitiyan Olùkọ̀wé yi lati gbé èdè àti Yorùbá ga lórí ẹ̀rọ Ayélujára.

Àwọn Òṣèlú tó yẹ ki wọn gbé èdè ìlú wọn lárugẹ n dá kún pí pa èdè rẹ.  Òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá ko fi èdè na ṣe nkankan ni Ilé-òsèlú, wọn o sọ́, wọn ò kọ́, wọn ò ká.  Àwọn Òṣèlú ayé àtijọ́ bi Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀, Olóyè Ládòkè Akíntọlá, àti bẹ̃bẹ lọ gbé èdè wọn lárugẹ bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wípé wọn kàwé wọn gboyè rẹpẹtẹ. Yorùbá ní “Àgbà kì í wà lọ́jà kórí ọmọ tuntun wọ́”.  Ó yẹ ki àwọn àgbà kọ́ ọmọ lédè, kí à si gba àwọn ọmọ wa níyànjú wípé sí sọ èdè abínibí kò dá ìwè kíkà dúró ó fi kún ìmọ̀ ni.  Ó ṣeni lãnu wípé àkàkù ìwé ló pọ̀ laarin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ, wọn ò gbọ́ èdè Yorùbá wọn ò dẹ̀ tún gbọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì.

Yorùbá ní “Ẹ̀bẹ̀ la mbẹ òṣìkà pé kí ó tú ìlú rẹ ṣe”, A bẹ àwọn Òṣèlú́ Ilẹ̀ Yorùbá ni agbègbè Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀̀yọ́, lati ṣe òfin mí mú Kíkọ àti Kíkà èdè Yorùbá múlẹ̀ ní gbogbo ilé ìwé, ní pàtàkì ní ilé-ìwé alakọbẹrẹ ilẹ̀ Yorùbá nitori ki èdè Yorùbá ma ba a parẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-03-26 21:44:54. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹ̀gẹ́ ò lẹ́wà; lásán ló fara wé Iṣu” – “Cassava has no attraction, it only resembles yam in vain”

Ẹ̀gẹ́/Gbaguda/Pákí fi ara jọ Iṣu nitori àwọn mejeeji jẹ oúnjẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá ti wọn ńkọ ebè fún lati gbin.  Wọn ma nwa wọn lati inú ebè ti wọn bá ti gbó, wọn ni eèpo ti wọn ma ḿbẹ.

Ẹ̀gẹ́/Gbaguda/Pákí ni wọn fi ńṣe gaàrí, bẹni wọn lè ló fún oriṣiriṣi oúnjẹ miran bi wọn ti lè lo iṣu, ṣùgbọ́n oúnjẹ bi iyán ati àmàlà mú iṣu gbayì ju ẹ̀gẹ́ lọ.  Fún ẹ̀kọ́ yi, ohun ti a lè fi iṣu ṣe yàtọ̀ si, iyán àti àmàlà ni a fẹ́ sọ. A lè fi iṣu din dùndú, tàbi se lati fi jẹ ẹ̀wà rirò/epo/ẹ̀fọ́ rirò/ọbẹ̀ ata, tàbi fi se àsáró́/àṣáró.

Àsè tàbi àpèjẹ Yorùbá ayé òde òni, kò pé lai si àśaró/àṣáró ni ibi àsè igbéyàwó, ìsìnkú, àjọ̀dún àti bẹ̃bẹ lọ.

ENGLISH TRANSLATION  Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-14 23:23:32. Republished by Blog Post Promoter

ÌPANU – SNACKS

Yorùbá ka ìpanu si ohun ti anjẹ lati mu inu duro pataki ni arin ounje aro ati ale.  A le ka si ounje osan.

Traditionally, Yoruba people regard snacks as stop-gap chewable, particularly between breakfast and dinner.  These are also often regarded as lunch. The most popular traditional Yoruba snacks are below: Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-22 18:41:13. Republished by Blog Post Promoter

Ìtán ti a fẹ́ kà loni dá lóri Bàbá tó kó gbogbo Ẹrù fún Ẹrú – The story of the day is about a father who bequeathed all his inheritance to his Chief Slave

Share Button

Originally posted 2017-12-06 00:23:08. Republished by Blog Post Promoter