Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

ÒKÚ NSUKUN Ò̀KÚ, AKÁṢỌLÉRÍ NSUKUN ARA WỌN: The Dead Weeps for the Dead — Yoruba Obituary for Margret Thatcher

ÌSÌNKÚ IYÃFIN MARGARET THATCHER

Wọn ṣe ẹ̀sìn ìsìnkú fún Olõgbe Iyãfin Margaret Hilda Thatcher – Obìnrin àkọ́kọ́ Olórí Òṣèlú Ìlúọba ni Ọjọ́rú, oṣù kẹrin ọjọ́ kẹtàdìnlógún ọdún ẹgbẹrunmejiIemẹtala.  Ọmọ ọdún mẹtadinladọrun ni nigbati ó dágbére fún ayé ni oṣù kẹrin ọjọ kẹjọ, ọdún ẹgbẹrunmejilemẹtala.

The coffin is carried on a gun carriage drawn by the King"s Troop Royal Artillery

The coffin is carried on a gun carriage drawn by the King”s Troop Royal Artillery.

Yorùbá ni “Òkú nsukun òkú, akáṣolérí nsukun ara wọn” ìtumọ̀ èyí ni wípé kò sẹ́ni tí kò ní kú, olówó, aláìní, ọmọdé, arúgbó, Òṣèlú, Ọba àti Ìjòyè á kú tí àsìkò bá tó, nitorina, ẹni to sunkun, sunkun fún ara rẹ, ẹni tó mbinu, mbinu ara rẹ nitori, ẹni tó kú ti lọ.

Ojúọjọ́ dára, ètò ìsìnkú nã lọ dédé láìsí ìdíwọ́.

Sunre o, Olõgbe Iyãfin Margaret Hilda Thatcher, ó dìgbà.

ENGLISH TRANSLATION

The funeral service for Late Baroness Margaret Hilda Thatcher – the first female Prime Minister in the United Kingdom, was held on Wednesday, April 17, 2013, she bade the world farewell on April 8, 2013.  She passed on at the age of 87.

A Yoruba adage says: “The dead is weeping for the dead, while the mourners are weeping for themselves”, this means that there is no one who will not die: rich, poor, young, old, Politicians, King/Queen and Chiefs will die when it is time, as a result, those weeping are weeping for themselves, those angry are angry at themselves because the dead is gone.

The weather was good, the funeral service went well without any hitch.

Sleep on, Late Baroness Margaret Hilda Thatcher, farewell.

Read the article referred to by this post at at http://www.bbc.co.uk/news/uk-22151589

Share Button

ÓDÌGBÀ, ÓDÌGBÓṢE, ÌYÁÀFIN MARGARET THATCHER: Farewell Prime Minister Thatcher

Former UK Prime Minister Margaret Thatcher, love her or hate her, she broke new ground for women everywhere. Image is from the BBC, click the image to read the BBC article.

Òkìkí ikú Ìyáàfin Margaret Thatcher, obìnrin àkọ́kọ́ lati dé ipò Olórí Òṣel̀ú Ìlúọba kàn ní oṣù kẹrin, ọjọ́ kẹjọ, ọdún ẹgbẹ̀rúnméjìlémẹ́tàlá.

Ebenezer Obey, ọ̀gá pàtàkì nínú olórin Jùjú ní ilẹ̀ aláwọ̀dúdú àti àgbáyé kọ̃ lórin wípé “kò sọ́gbọ́n tolèdá, kò síwà tolèhù, kò sọ́nà tolèmọ̀, tolèfi táyé lọ́rùn, ilé ayé fún gbà díẹ̀ ni, ọmọ aráyé ẹ ṣe rere”.  Orin yi ba ìgbà ayé Olõgbe Ìyáàfin Margaret Thatcher mu.  Gẹ́gẹ́bí Obìnrin àkọ́kọ́ tó di Olórí Òṣèlú Ìlúọba, ó ṣe ìwọ̀n tó lèṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ìlù rẹ̀.  Bi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti nṣe ìrántí rẹ fún iṣẹ́ ribiribi to ṣe lóríoyè, bẹ̃ni àwọn kan bu ẹnu àtẹ́ lu͂.

Ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀ ni “Lẹ́hìn ọkùnrin tó ṣorire, obìnrin wa nbe”, ṣùgbọ́n wíwo ìgbésí ayé àwọn og̀bójú obìnrin bi Olõgbe Fúrnmiláyọ̀ Ransome Kútì àti Olõgbe Margaret Thatcher fihàn wípé “lẹ́hìn obìnrin tó bá́ ṣe orire, ọkùnrin wa nbẹ”, ọkọ wọn dúró tìwọn gbọingbọin, èyí fi ọkàn àwọn aṣájú nínú àwọn obìnrin àgbáyé yi balẹ̀ lati tọ́jú àwọn ọmọ pẹ̀lú iṣẹ́ Òṣèlú tí obìnrin kò wọ́pọ̀ lásìkò tiwọn.  A tún ri ẹ̀kọ́ kọ wípé “kòsí ohun ti ọkùnrin ṣe ti obìnrin kò lè ṣe dãda” nítorí Olõgbe Ìyáàfin Fúnmiláyọ̀ Ransome Kútì ṣe iṣẹ́ ribiri lati kọ ìwọ̀sí àti jà fún obìnrin ni ilẹ̀ Yorùbá àti ni ilẹ̀ aláwọ̀dúdú, bẹ͂ni Ìyáàfin Margaret Thatcher ṣe iṣẹ́ tómú ìlọsíwájú bá ara iìúọba lai wo ariwo ọjà.

Sùn re o, Ìyáàfin Thatcher.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

NÍNÍ OWÓ BABA ÀFOJÚDI, ÀÌNÍ OWÓ BABA ÌJAYÀ: Abundance of Money is the Father of Insolence and Lack of Money the Father of Panic

Welfare System Reforms -- BBC

BBC article on benefit cuts, aini owo baba ijaya.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ba ìjọba Ìlúọba àti àwọn ará ìlú wi. Ìjọba njaya nítorí owó ti o nwọle kò kárí owó lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tọ́ ti àwọn ará ìlú nri gbà.  Àwọn ti o si ngba ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ ìjọba njaya nítorí, ẹ̀tọ́ ti Ìjọba ndiku yio mu ìnira bá wọn nítorí ẹ̀dín owó yi bọ́sí àsìkò ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti ohun ìtura míràn.

Gẹ́gẹ́bí ilé iṣẹ́ amóhùn máwòran Ìlúọba ti ròyìn, lati Oṣù kẹrin, ọjọ́ kini, ọdún ẹgbẹ̀rúnmẽjilemẹtala, Ìjọba Ìlúọba bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe lati dín gbèsè ti ìlú jẹ ku; gbígba àwọn òṣìṣẹ́ ni ìyànjú ki wọn tẹra mọ́ṣẹ àti ki àwọn ti ko ṣiṣẹ́ le padà si ẹnu iṣẹ́.  Díẹ̀ nínú àwọn àtúnṣe yi ni: ìdérí owó ìrànlọ́wọ́ si poun mẹrindinlọgbọn lọ́dún fún ìdílé; yíyọ owó fún yàrá tó ṣófo; àtúnṣe fún Ilé Ìwòsàn lapapọ àti bẹ̃bẹ lọ.

Yorùbá ni “Kòsọ́gbọ́n tí o lèda, kòsíwà tí o lèhù  tí o lè  fi tẹ ayé lórùn”,  bí ọ̀pọ̀ ti nyin ìjọba bẹ̃ni ọ̀pọ̀ mbu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àtúnṣe wọnyi wípé Ìjọba ngba lọ́wọ́ aláìní fún àwọn tóní.

ENGLISH TRANSLATION >>> Continue reading

Share Button

WÕLI ỌBÁDÁRE SÙN NÍNÚ OLÚWA: PROPHET OBADARE SLEPT IN THE LORD

Ìròyìn wípé Wõli Timoteu Ọbádáre, Olùdásílẹ̀ Ìjọ “Olùjèrè Ẹ̀mí Oníhìnrere Iṣẹ́ Ìránsé” sùn nínú Olúwa jáde ni ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹta ọdún ẹgbẹ̀rúnméjì lémẹ́tàlá.

Wõli Ọbádáre jẹ ìkan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọrun àgbáyé nítorí ẹ̀ka Ìjọ ti wọn pè ni WOSEM wa kãkiri ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti ní Òkè-òkun/Ìlú-òyìnbó.  Ẹ̀ka Ìjọ Wõli Ọbádáre wà ni London, New York àti bẹ̃bẹ lọ. Nígbà ayé õlogbe yi, ó fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìhìnrere.

Sùnre lẹ́sẹ̀ Jésù, Wõli Timoteu Ọbádáre.

ENGLISH TRANSALATION

The news that Prophet Timothy Obadare, Church Founder “Soul Winning Evangelical Ministry” popularly known as “WOSEM” slept in the Lord on Friday, 22nd March, 2013.

Prophet Obadare was one of the Evangelists in the world because Soul Winning Evangelical Ministry (WOSEM) is spread in various countries of Africa and with branches Abroad/Europe such as in London, New York etc.  During his lifetime, he worked devotedly to spread the gospel.

Sleep well at the feet of Jesus Prophet Timothy Obadare.

Share Button

YEPARIPA!!! ERÍNWÓ, ẸJA NLA LỌ LÓMI: CHINUA ACHEBE, THE TITAN HAS FALLEN

Ìròyìn ikú Olõgbe Chinua Achebe, ògúnná gbongbo ninu Olukọwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti àgbáyé kàn ni ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejì lélógún, oṣ̀u kẹta ọdún ẹgbẹ̀rún meji le mẹ́tàlá.  Ọmọ ọdún meji le lọgọrin ni Olõgbe Chinua Achebe nígbà ti o pa ipòdà.

Ìkan nínú ìwé ti Olõgbe Chinua Achebe kọ “Nkan túká” di kíkà fún àwọn ọmọ ilé-ìwé lati ilẹ̀ ènìà dúdú títí dé Òkè-òkun/ìlú-òyìnbó.  Títí di àsìkò yi, ìwé na ngbayi si ni, nítorí wọn ti túmọ̀ ìwé yi sí èdè oriṣiriṣi.

Àdánù nla ni ikú Olõgbe Chinua Achebe jẹ́ fún Naijeria, ìlú aláwọ dúdú àti gbogbo Olùkọ̀wé lagbaye.

Sunre o, Ologbe Chinua Achebe.

The news of the death of Late Chinua Achebe, a Prominent Writer in Africa and Literature giant in the World was announced on Friday, 22nd March, 2013.  He was 82 years old at the time of transition.

One of the Literature Books written by Chinua Achebe “Things Fall Apart” is being read by students in many African Countries and Abroad/Europe as it has been translated to several languages and it continues to be in demand.

Chinua Achebe’s death is a big loss not only for Nigeria but Africa and all Writers in the World.

Sleep on Late Chinua Achebe.

Share Button

OHUN T’Ó KỌJÚ SÍ ẸNÌKAN LÓ KẸ̀HÌN SI ẸLÒMÍRÀN: That which faces one person has turned its back to another

“OHUN TÍ Ó KỌJÚ SÍ ẸNÌKAN LÓ KẸ̀HÌN SI ẸLÒMÍRÀN”: That which faces one person has turned its back to another

Olórí Òṣèlú Venezuela Hugo Chavez, pa ipò dà ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ karun oṣù kẹta ọdún ẹgbẹ̀rún méjì lémẹ́tàlá.  Nígbà ayé ologbe yi, ó fa àríyànjiyàn, bí ó ti fẹ́ràn àwọn ìlú kan bẹ lo korira àwọn ìlú míràn.  Lati ìgbà tí ìròyìn ikú rẹ̀ ti kan, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni gbogbo àgbáyé ti nsọfọ bẹni àwọn kan nfi àibìkítà han.  Eleyi fihan wípé ohun tí ó kọju sí ẹnìkan ló kẹ̀hìn sí ẹlòmíran.  Ódìgbóṣe Olõgbé Olórí Òṣèlú Hugo Chavez, orílẹ-èdè Venezuela ṣe ilédè lẹ́hìn rẹ.

ENGLISH TRANSLATION

Hugo Chavez: Venezuela's late President, loved by some and hated by others. CNN article.

Hugo Chavez: Venezuela’s late President, loved by some and hated by others. CNN article.

The late President of Venezuela Hugo Chavez passed on Tuesday, 5 March 2013.  During his lifetime, he was controversial, while he showed love to some, he was also hated by others. Since the news of his death, while many people all over the world are mourning, others could care less.  Reaction to his death reflects the Yoruba saying: “that which faces one person has turned its back to another”. Farewell Late President Yugo Chavez, the people of Venezuela are holding forth.

Share Button

A kì dàgbà jẹ Òjó: Natural birth names not apt at old age — ÌDÁRÚKỌ PADÀ UNILAG – THE UNILAG NAME CHANGE

Univesity of Lagos Senate

UNILAG Senate Building – photo from http://www.unilag.edu.ng/

“A kì dàgbà jẹ Òjó”: “Natural birth names not appropriate at old age”

Òjó, Dàda, Àìná, Táíwò, Kẹhinde ati bebe lo je orúkọ amu tọrun wa.  Pípa orúkọ Ilé-ìwé gíga ni Akoka, ilu Eko da lẹhin aadọta ọdún dàbí ìgbà ti a sọ arúgbó lorukọ àmú tọrun wa.  Apẹrẹ: ẹni ti ki ṣe ibeji ko le pa orúkọ da si orúkọ àmú tọrun wa.

A dupẹ lọwọ Olórí Ìlú Goodluck Jonathan to gbọ igbe awọn ènìyàn lati da orúkọ Ilé-ìwé Gíga ti o wa ni Akoko ti Ilu Eko pada gẹgẹbi Olukọagba Jerry Gana, ti kọ si ìwé ìròyìn ni ọjọ Ẹti, oṣù keji ẹgbaa le mẹtala.

ENGLISH TRANSLATION

Òjó, Dàda, Àìná, Táíwò, Kẹhinde etc, all these names in Yoruba are given at birth as a result of natural circumstances observed at birth.  Continue reading

Share Button

ÌRÒYÌN – NEWS: Ogun àsọ tẹlẹ – A War Aforetold

ÌRÒYÌN ÌJÌ NLA JÀ NI ÌBÀDÀN: NEWS OF RAIN STORM IN THE IBADAN

Òjò ati ìjì bẹrẹ ni arọkutu ọjọ ajé, ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdún ẹgbẹwa le mẹtala.  Ìjì naa ba ílé ati ọna jẹ rẹpẹtẹ ni ìlú Ìbàdàn

Òwe Yorùbá sọ wipe “Ogun àsọ tẹlẹ ki parọ to ba gbọn”.  O ṣeni lanu wipe ko si àsọ tẹl tabi ipalẹmọ fún ará ìlú ati ijọba.  Iyalẹnu ni wipe lati ọpọ ọdun ti ìjì àti àgbàrá lati odò Ògùnpa ti mba ilé ati ọna jẹ lọdọdun, Ìjọba Ọyọ ko ti ri ogbọn kọ lati da ẹkun ati ibanujẹ ti iṣẹlẹ yi nda silẹ.

ENGLISH TRANSLATION

Rain storm began early on Monday morning, 18 February, 2013.  The rain storm destroyed homes and properties in Ogun state, Nigeria. Continue reading

Share Button