Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Ẹni àjò ò pé, kó múra ilé” – “Ìjà Boko Haram” – The person for whom a journey has not been profitable, should prepare to return home – “Boko Haram mayhem”

Yorùbá jẹ́ ẹ̀yà ti ó wà ni Ìwọ̀-õrùn orilẹ̀ èdè Nigeria.  Bi Yorùbá ti fẹ́ràn igbádùn tó, bẹ ni wọn fẹ́ràn òwò ṣiṣe àti ẹ̀kọ́ kikọ́.  Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti aláìní ilẹ̀ Yorùbá ló fẹ́ràn àti rán ọmọ wọn lọ si ilé-iwé bi àwọn fúnra wọn kò ti ẹ lọ si ilé-iwé. Eleyi jẹ ki Yorùbá pọ kà kiri àgbáyé pàtàki ni Àríwá/Òkè-ọya Nigeria.

Nibi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá ti fẹ́ràn “iwé-kikà” ni ẹ̀yà miràn ti fi ẹsin bojú lati ṣe àtakò iwé kikà, pàtàki àwọn ti o ni “A ò fẹ́ iwé – Boko Haram”.   Àwọn ti ó ni àwọn kò fẹ́ lọ si ilé-iwé bẹ̀rẹ̀ si pa ọmọ àwọn ti ó fẹ́ lọ.  Wọn kò dúró lóri ọmọ ilé-iwé nikan, wọn ńpa enia bi ẹni pa ẹran ni ọjà, oko, ilú, ọ̀nà àti gbogbo ibi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilú ni òkè-Ọya pàtàki ni ilú “Borno”.

Girls kidnapped from Nigeria school

Islamic militants suspected in Nigeria abduction of 100 female students

Yorùbá ni “Bi onilé bá ti ńfi àpárí iṣu lọ àlejò, ilé tó lọ”.  Ki ṣe àpárí iṣu nikan ni wọn fi ńlọ àjòjì ni òkè-ọya/Àriwá “ikú òjiji” ni.  Àini ifọkàn balẹ̀ kò lè jẹ́ ki àjò ò pé.  Lati igbà ti “ẹni ti ó so iná ajónirun mọ́ra” ti bẹ̀rẹ̀ si pa enia bi ẹni pẹran ni ilé ijọsin – pàtàki ti onígbàgbọ́; ọjà; ãrin ilú; abúlé àti ilé-iwé ni àjò kò ti pé mọ́. Ìròyìn kàn ni ọjọ́ kẹdogun oṣù kẹrin ọdún ẹgbã-lé-mẹrinla, pe wọn ti tún bẹ̀rẹ̀ si ji ọmọ ilé-iwé gbé – ó lé ni ọgọrun  ọmọ obinrin ti wọn fi ipá ji wọn gbé, mẹrinla ni ó ri àyè sá mọ́ ajínigbé lọ́wọ́, òbi àwọn ti ó kù wà ninú ìrora.

A lè fi òwe Yorùbá ti ó ni “Ẹni àjò ò pé, kó múra ilé” gba àwọn Yorùbá ti ó wà ni òkè-ọya ni ìyànjú pé ki wọn bẹ̀rẹ̀ si múra ilé, ki wọn ma ba pàdánù ẹmi, ó sàn ki enia pàdánù owó ju ẹ̀mi lọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Dídùn ni iranti Olododo – Àgbáyé péjọ fún iranti “Madiba” Nelson Mandela: “Sweet is the memory of the Righteous” – The World gathered in memory of “Madiba” Nelson Mandela

Nelson Mandela memorial: Obama lauds ‘giant of history’

US President Obama

US President Obama pays tribute at the Memorial Service at FNB Stadium, Johannesburg

Yorùbá ni “Òṣìkà kú, inú ilú dùn, ẹni rere kú inú ilú bàjẹ́”.  Bi o ti le jẹ́ pé Nelson Mandela ti pé marun din-lọgọrun ọdun láyé (1918 – 2013), gbogbo àgbáyé ṣe dárò rẹ nitori ohun ti ó gbé ilé ayé ṣe.  Ó fi ara da iyà lati gba àwọn enia rẹ sílẹ̀ ni oko ẹrú ni ilẹ̀ wọn.  Ó fi ẹmi ìdáríjì han nigbati ó dé ipò Olórí Òṣèlú.  Kò lo ipò rẹ lati kó ọrọ̀ jọ, ó gbé ipò sílẹ lẹhin ti ó ṣe ọdún marun àkọ́kọ́.  Eleyi jẹ́ ki ọmọdé, àgbà, Òṣèlú, Ọlọ́rọ̀, Òtòṣì, funfun àti dúdú papọ̀ nibi ètò ìrántí rẹ ni Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹwa, Oṣù Kejila, ọdún Ẹgba-̃le-mẹtala.

Ìgbà àti àsìkò Nelson Mandela jẹ àríkọ́gbọ́n fún gbogbo àgbáyé pataki àwọn ti ó wà ni ipò Òṣèlú.  Ìjọba ilú South Africa ṣe àlàyé ètò ìsìnkú rẹ bayi:

Àìkú, Ọjọ́ kẹjọ, Oṣù Kejila, ọdún Ẹgbã-le-mẹtala:            Ọjọ́ àdúrà àpa pọ̀

Ìṣégun, Ọjọ́ kẹwa, Oṣù Kejila, ọdún Ẹgbã-le-mẹtala:        Ètò ìrántí

Ọjọ́rú, Ọjọ́bọ̀ àti Ẹti, Ọjọ́ kọkọnla si ikẹtala, Oṣù Kejila, ọdún Ẹgbã-le-mẹtala:    Ìtẹ́ òkú

Abameta, Ọjọ́ kẹrinla, Osu kejila, odun Egbalemetala:   Gbigbé òkú lọ si Qunu

Aiku, Ọjọ́ karun-din-lógún, Osu Kejila, odun Egbalemetala:    Ìsìnkú

ENGLISH TRANSLATION

http://www.mandela.gov.za/funeral/

Continue reading

Share Button

“Ká tó ri erin ó digbó; ká tó ri Ẹfọ̀n ó dọ̀dàn; ká tó ri ẹyẹ bi Ọ̀kin ó di gbére” – Ó dìgbóṣe Nelson Mandela: “Before one can see the elephant, one must go to the forest; before one can see the buffalo, one must go to the wilderness; before one can see another bird like the peacock, one must await the end of time” – Farewell Nelson Mandela”.

Nelson Mandela

Mandela milestones

Òkìkí ikú Nelson Mandela kan ni alẹ́ Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ karun, oṣù kejila ọdun Ẹgbã-le-mẹtala.

Òwe Yorùbá ti o ni “Ká tó ri erin ó digbó; ká tó ri Ẹfọ̀n ó dọ̀dàn; ká tó ri ẹyẹ bi Ọ̀kin ó di gbére” fihan pé ki ṣe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú nikan ni irú Nelson Mandela ti ṣe ọ̀wọ́n, ṣugbọn gbogbo àgbáyé.  Melo ninu Olori Òṣèlú àti àwọn Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ló lè ṣe bi Nelson Mandela?  Bi wọn dé ipò giga wọn ki fẹ kúrò, wọn a paniyan, wọn a jalè, wọn a ta enia wọn àti oriṣiriṣi iwa burúkú miran lati di ipò na mu.

Nelson Mandela ṣe ẹ̀wọ̀n fún ọdún mẹta-din-lọgbọn nitori ó̀ gbìyànjú lati tú àwọn enia rẹ sílẹ̀ ni oko ẹrú. O di enia dúdú àkọ́kọ́ lati dé ipò Olori Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú (South Africa).   Kò lo ipò yi lati gbẹ̀san iṣẹ́ ibi ti àwọn aláwọ̀ funfun ṣe si tàbi ijiya rẹ ni ẹ̀wọ̀n.  Ó fi apẹrẹ onígbàgbọ́ rere han nitori ó dariji àwọn ti ó fi ìyà jẹ́ ohun àti àwọn enia rẹ tori ki ilú rẹ lè tòrò.   Ẹyẹ bi ọ̀kín ṣọ̀wọ́n, kò du lati kú si ori ipò, lẹhin ọdún marun ó gbé ipò sílẹ̀ ki ẹlòmíràn lè bọ́ si.

Ọmọ ọdún marun-din-lọgọrun ni ki ó tó pa ipò dà, bi o ti ẹ̀ jẹ́ pé Nelson Mandele ti di arúgbó, gbogbo àgbáyé ò fẹ́ ki ó kú, nitori ẹyẹ bi ọ̀kín rẹ ṣọ̀wọ́n.  Bi àwọn Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú yoku ba le kọ́gbọ́n lára “ìgbà àti ikú Nelson Mandela”, ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú á dára.

Gbogbo àgbáyé ṣè dárò Madiba Nelson Mandela.  Gbogbo ọmọ Yorùbá ni ó dìgbà, ó dìgbóṣe, ó dàrìnàkò, ó dojú àlá ká tó tún ríra.

ENGLISH TRANSLATION

http://www.bbc.co.uk/news/

Reverend Malusi Mpumlwana holds a short prayer for hundreds of mourners who gathered outside former President Nelson Mandela"s house in Johannesburg

South Africa and world mourns Mandela

The news of the death of Nelson Mandela broke out at night Thursday, day five, December, 2013.

The Yoruba proverb that said, “Before one can see the elephant, one must go to the forest; before one can see the buffalo, one must go to the wilderness; before one can see another bird like the peacock, one must await the end of time” showed that Nelson Mandela was not only a rare breed in African but in the world.  How many Political Leaders or Politicians in Africa can behave like Nelson Mandela?  When they get to position of authority, they never want to leave, they will kill, steal, sell their people and commit other wicked acts to retain their position.

Continue reading

Share Button

Ẹrú kú ìyá ò gbọ́, ọmọ́ kú ariwo ta – ọ̀fọ̀ ṣe ni ìlú Àkúrẹ́: “The slave died the mother was not informed, a freeborn died, lamentation erupted” – Akure people mourns”

Òkìkí ìròyìn pé Ọba Àkúrẹ́ wàjà (Ọba Adebiyi Adeṣida) kàn ni òwúrọ̀ ọjọ́ Aiku, ọjọ́ kini, oṣu kejila ọdún ẹgbẹwa-le-mẹtala.  Ọmọ ọdún mẹta-le-lọgọta ni Ọba Adeṣida, ó jọba ni ọdún mẹta le diẹ sẹhin, eleyi lo jẹ ki iroyin yi jẹ ọfọ gidigidi.

Gẹgẹ bi òwe Yorùbá yi “Eru ku…., bi o ti le jẹ pe ko yẹ ki irú iroyin bẹ jade titi di ọjọ keje lẹhin ti Ọba bá wàjà, òkìkí ti kan lori ẹ̀rọ ayélujára.

ENGLISH TRANSLATION

http://odili.net/news/source/2013/dec/1/830.html

Deji of Akure dies at 63  by Eniola Akinkuotu

Deji of Akure dies at 63
by Eniola Akinkuotu

The report of the demise of the King of Akure (King Adebiyi Adesida) erupted in the news early morning on Sunday, 1st of December, 2013.  He was aged 63, he reigned barely over three years hence the great mourning of the people.

According to the Yoruba proverb “The slave died the mother was not informed, a freeborn died, lamentation erupted”, even though the news of the king’s demise ought not to have been announced till seven days after his demise, because of his position in the Society, the news was already on the internet.

Share Button

“Ohun to yẹni lo yẹni, òkùnkùn ò yẹ ọmọ eniyan” – Ilé-iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná: “What befits is what befit, darkness does not befit human being” – NEPA/PHCN

Ọ̀gá ninu Olórin Fela Anikulapo-Kuti kọrin pé “Ọjọ́ wo la ma bọ o, lóko ẹrú”, orin yi fa ìbèrè wípé “ọjọ́ wo la ma bọ ninu òkùnkùn ni orílẹ̀ èdè Nigeria?”

Bi eré bi àwàdà, dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná bẹrẹ ni àsikò Ìjọba Sagari, ni bi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n sẹhin.  Ni àsikò yi, ki ṣe pe iná ti ilú pèsè kò tó, ṣùgbọ́n a ṣe akiyesi pé awọn òṣìṣẹ́ ni àsikò na lọ ńyọ nkan lára àpóti iná, nitori eyi, ki ṣe gbogbo àdúgbò ni ki ni iná. Fún akiyesi, iná ilé-iwé giga àti agbègbè rẹ, awọn ilé iṣẹ́ bi ìlèṣẹ ọkọ̀ òfúrufú, ilé ìwòsàn àti bẹbẹ lọ ki lọ.  “Bi eniyan ba yọ́ ilẹ̀ dà, ohun burúkú a ma yọ́ni ṣe”, nigbati awọn òṣìṣẹ́ oníṣẹ́ ibi kò ri ẹni ba wọn wi, ọ̀rọ̀ iná lilọ bẹrẹ si gbòrò si.  Pẹlu gbogbo owó ti wọn ti na lati tú ọ̀rọ̀ iná mọ̀nà-mọ́ná ṣe, ó burú si lai ya ilé-iṣẹ́ àti ibi kankan sílẹ̀ ninu òkùnkùn.

Yorùbá ni “ohun tó yẹ ni, lo yẹ ni, òkùnkùn o yẹ ọmọ eniyan”, nitori òkùnkùn ti ilé-iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná fa fún ará ilú, ọpọlọpọ ilé-iṣẹ́ ti kò kúrò ni Nigeria eleyi din ìpèsè iṣẹ́ kù, kò si iná lati tọ́jú ounjẹ eleyi jẹ ki ounjẹ wọn si, ìnáwó lori ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná pẹ̀lú ariwo ki jẹ ki eniyan sùn bẹni kò jẹ́ ki eniyan tabi ilé-iṣẹ́ fi owó pamọ́.

Á lérò wípé awọn ilé-iṣẹ́ ti wọn pin iná pi pèsè fún a yọ ilú kúrò ninu òkùnkùn nitori òkùnkùn kò yẹ ọmọ eniyan.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

“A ni ki á pẹnupọ̀ bá olè wi, wọn ni ibi ti oní-ǹkan gbé nkàn rẹ̀ si ò da” – “We said we should collectively condemn the thief/rogue, the owner is being condemned for not keeping his/her stuff well”.

Ìròyìn ti ó nlọ lọ́wọ́ ni orílẹ̀ èdè Nigeria ni pé Aṣojú-ọba nkó ọrọ̀ ilú dànù gẹgẹ bi iṣe awọn yoku lati ra ọkọ̀̀ ojú-ogun.  Asoju-oba ile iṣẹ ọkọ-òfurufu – Ms Stella Odua lo ọ̀kẹ́ àìmoye owó lati pèsè àbò fún ara rẹ nipa ni náwó lórí ọkọ̀-ologun nibiti ọ̀pọ̀ ará ilú ti ńjìyà àti òṣìṣẹ́ ti o ngba owó kékeré.

http://saharareporters.com/news-page/nigerias-minister-aviation-armored-bmw-car-scandal-car-sells-only-170k-europe-and-america

Nigeria's Minister of Aviation Armored BMW Car Scandal: Car Sells For Only $170K In Europe And America

Nigeria’s Minister of Aviation Armored BMW Car Scandal: Car Sells For Only $170K In Europe And America

 

Abájọ ti Yorùbá fi pà òwe pé “A ni ki a pẹnu pọ̀ ba olè wi, wọn ni ibi ti oní-nkàn gbé nkàn rẹ̀ si ò da”.  Eleyi ba Ìjbọba-àpapọ ti ó nwá ẹni ti ó tú àṣiri ìná-kuna yi dipò ki wọn bá Onina-kuna wi.

Ni ọjọ́, awọn ará ìlú ni àpapọ̀ wọn a ni ìgboyà lati pẹnupọ̀ bá awọn olé Òṣèlú/Aṣojú-ọba ti wọn nkó ọrọ̀ ìlú dànù wi.

 

ENGLISH TRANSLATION

The news raging on in Nigeria is a Minister squandering public money as usual to acquire armoured car.  The Minister of Aviation – Ms. Stella Odua spent a staggering sum of 255 million Naira to secure her own security by investing public fund on armoured vehicles while most Nigerians are in the midst of poverty and workers earning paltry sum.

No wonder Yoruba said “We said we collectively condemn the thief/rogue, the owner is being condemned for not keeping his/her stuff well”.  This is the case of the Federal Government searching for those who leaked the secret rather than condemning this wasteful expenses.

One day, the Nigerian people will be bold to condemn these rogue Politicians/Ministers squandering the wealth of the nation.

 

Share Button

Ẹ̀bẹ̀ là mbẹ̀ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe – Ọkọ̀ tó kó òṣìṣẹ́ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú dà si odò ni Lampedusa, Italy: One can only remonstrate with the wicked to improve his/her town – African Migrant Workers ship wreck on the Mediterranean, Lampedusa, Italy

Yorùbá ni “Omi lènìyàn, bi ó bá ṣàn siwájú á tún ṣàn sẹ́hìn”.  Òwe yi túmọ̀ si wipé lati ọjọ́ ti aláyé ti dáyé ni èniyàn ti nkúrò ni ìlú kan lọ si ikeji fún ọpọlọpọ idi.  Èniyàn ma nkúrò ni ìlú abínibí nitori: ogun, ìyàn, ọ̀gbẹlẹ̀, ọrọ̀ ajé, ìtẹ́síwájú ninu ẹ̀kọ́, àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

Ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú kún fún wàrà àti oyin nitori ọgọrun-din-marun ohun àlùmọ́nì gbogbo àgbáyé wà ni orílẹ̀ èdè naa.  Ó ṣeni lãnu pe, ọgọrun-din-marun ìṣẹ́ wa ni ni orílẹ̀ èdè yi nitori ìṣe àti ìwà awọn “Olórí” nipa gbígba abẹtẹlẹ, ìwà ìbàjẹ́, ọ̀kánjúà, jija ìlú lólè àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  Lára ìwà burúkú yi ló ndá ogun àti ọ̀tẹ̀ si ìlú àti tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun awọn ọ̀dọ́. Èrè awọn ìwà ìbàjẹ́ wọnyi ti ba ìlú jẹ, èyi jẹ ikan ninu ohun ti ó dá kún ohun ti ọ̀dọ́ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú fi nkúrò lọ si òkè-òkun/ìlú-oyinbo ni ọ̀nà kọnà.

Italy boat sinking: Coastguard rescue footage released

Ọkọ̀ tó kó òṣìṣẹ́ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú dà si odò ni Lampedusa, Italy: African Migrant Workers ship wreck on the Mediterranean, Lampedusa, Italy

Iroyin awọn ọdọ òṣìṣẹ́ ti o nṣi kúrò ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ti ọkọ̀ wọn dà si òkun ni ìlú Lampedusa, Italy kàn loni ọjọ́ Ẹti, osu kewa, ọjọ́ kẹrin ọdún Ẹgbãlẹmẹtala.  Iroyin ikú ọ̀rùndínrínwó òṣìṣẹ́ tó ṣègbé si òkun kan.

Yorùbá ni “Ẹ̀bẹ̀ là mbẹ̀ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe”. Òwe yi bá awọn Oṣelu ti a npe ni “Alágbádá” àti awọn Olórí ìjọ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ki wọn jọwọ tún ìlú wọn ṣe.  Ọpọlọpọ ewu ti awọn ọdọ nla kọjá iba din kù bi awọn Olórí ìlú bá lè fi ìwà burúkú sílẹ̀, ki wọn tu ìlú ṣe nipa ṣi ṣe ìdájọ́ fún Olórí ti ó bá ṣe iṣẹ́ ibi bi ki kó owó ìlú jẹ àti awọn ìwà ìbàjẹ́ yoku.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba adage said “People are like river that flows both ways”.  This proverb can be applied to support the fact that people have always migrated from one place to the other for many reasons.  People leave their places of birth as a result of: war, famine, drought, trade, pursuant of further education etc. Continue reading

Share Button

Ọmọ to yi ko gbọn, Ìyá ni ko ma ṣa kú, kilo npa ọmọ bi agọ̀? Nigeria lẹhin ominira ọdún mẹ́tàléladọta: A child is as old and yet lacks wisdom, the mother said, so far the child does not die, what kills a child more than foolishness” – Nigeria after Fifty-three years Independence.

Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ikan ninu ẹ̀yà nlá lára orílẹ̀ èdè Nigeria.  Orílẹ̀ èdè yi gba ominira lati ọ̀dọ̀ ilú-ọba ni ọdún mẹ́tàléladọta sẹhin.  Lati igba ti Nigeria ti gba ominira, “Kàkà ki ewé àgbọn dẹ̀, koko ló tún nle si”.   Bi ọdún ti ńgorí ọdún ni ó nle koko si fún ará ilú.

Olórí ilú ti a npe ni Ìjọba mba ọrọ̀ ilú jẹ pẹ̀lú iwà ibàjẹ́ bi: gbigba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, ojúkòkòrò, rírú òfin ti wọn fúnra wọn fi silẹ̀, fifi èrú gba Ìjọba, kíkó ọrọ̀ ilú lọ si òkè-òkun àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  Kò si iyàtọ̀ laarin Ìjọba Ológun àti Òṣèlú.

Èrè iwà burúkú lati ọ̀dọ̀ Òṣèlú ti ran awọn ará ilu.  Oriṣiriṣi iwà burúkú ti kò ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́ ti bẹ̀rẹ̀ si ṣẹlẹ̀.  Fún àpẹrẹ, gbọmọgbọmọ ti gbòde, olè jíjà, jìbìtì, tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun, ọ̀tẹ̀ àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  Èrè iwà burúkú yi han ni gbogbo ẹ̀yà orilẹ̀ èdè Nigeria lati Àríwá dé Ìwọ Õrun, Ìlà Õrun àti Gũsu.  Kò si iná, omi, ilé-ìwé fún ọmọ aláìní, ojú ọ̀nà ti bàjẹ́, awọn ará ilú njẹ ìyà, ọpọlọpọ ọdọ jade ilé-ìwé wọn ò ri iṣẹ́, èyi to ri iṣẹ́ ngba owó ti kò tó jẹun àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

Bi Nigeria ti nṣe àjọ̀dún kẹtaleladọta ni ọjọ́ kini oṣù kẹwa, ó yẹ ká gbé òwe Yorùbá ti ó ni “Ọmọ to yi ko gbọn, Ìyá ni ko ma ṣa kú, kilo npa ọmọ bi agọ̀”, yẹ̀wò.  Ìlú tó bá gbọ́n ni lati kó ara pọ̀ lati ṣe àpérò fún àtúnṣe nkan ti ó ti bàjẹ́, ki agọ̀ ma bà pa orílẹ̀ èdè.

Bi ó ti wù ki ó ri, ẹni ọdún bá láyé, ó yẹ ki ó dúpẹ́, ki ó ni ireti pé ọ̀la yi o dára, nitori eyi, ẹ̀yin olólùfẹ́ èdè àti àṣà Yorùbá, ẹ kú ọdún ominira o.

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

“Ọmọ ẹni kì í burú títí, ká fi fún ẹkùn pajẹ ” – “One’s child cannot be bad to the extent of throwing him/her to the Leopard to devour”

Ọmẹni kì í burú títí, ká fi fún ẹkùn pajẹ ” – ìdájọ́ fún ìyá àti ọkọ-ìyá Daniel Pelka: “One’s child cannot be bad to the extent of throwing him/her to the Leopard to devour”, judgement for Daniel Pelka’s mother and step-father 

Gẹgẹ bi Òwe Yorùba,́ “Ọmọ ẹni kì í burú títí, ká fi fún ẹkùn pajẹ”.  Òwe yi bá ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú ti ó ṣẹlẹ̀ si Daniel Pelka mu.  Kò tọ́ ki ìyá Daniel Pelka ti o yẹ ki ó dáàbò bo ọmọ fi ìyà jẹ ọmọ ọdún mẹrin yi dé ojú ikú.  Ọmọ kékeré yi jẹ̀ ìyà kú lọ́wọ́ ìyá àti ọkọ rẹ.

Kini ọmọ ọdún mẹrin lè ṣe lati gbèjà ara rẹ lọ́wọ́ òbí burúkú?  Kòsí ohun ti ọmọdé lè ṣe, ṣugbọn Ìjọba fa obìnrin àti ọkùnrin burúkú yi lọ si Ilé-Ẹjo.  Wọ́n gba ìdájọ́ èyí ti wọn ni lati lo ọgbọn ọdún ó kéré jù.  Ẹ wo ìròyìn yi:

ENGLISH LANGUAGE

According to Yoruba proverb that said “One’s child cannot be bad to the extent of throwing him/her to the Leopard to devour”.  This proverb is applicable to the evil incidence that happened to Daniel Pelka.  It is not appropriate for Daniel Pelka’s mother that ought to have protected her son to punish the four year old to death.  This young child suffered to death in the hands of his mother and step-father.

What can a four year old do to protect him/herself in the hands of wicked parent?   There is nothing a young child can do, but the Government dragged this wicked woman and man to Court.  They got the judgement they deserved of at least thirty (30) years imprisonment.  Read the news below:

http://www.bbc.co.uk/

Mariusz Krezolek, Magdelena Luczak and Daniel Pelka

Daniel Pelka Killers jailed for minimum of 30 years

Share Button

Àjọ̀dún Iṣẹ́-Ọnà Yorùbá ni London: Yoruba Art Festival London

Ni ọjọ Àbámẹ́ta àti ọjọ Àìkú oṣù keje, ọjọ́ kẹtadinlọgbọn àti ọjọ kejidinlọgbọn ọdun ẹgbã̃-le-mẹtala, wọn ṣe àjọ̀dún kẹrin Iṣẹ́-ọnà ilẹ Yorùbá, ni pápá Clissod, ni ìlú London.

Gẹgẹbi òwe Yorùbá “Ẹni ti ó ni ki ará ilé ohun má là, ará ìta ni o ya láṣọ”.  Òwe yi là le fi ba awọn èyaǹ wa wi, nitori bi Òyìnbó bá bẹ̀rẹ̀ si ṣe irú àjọ̀dún yi, awọn enia wa a tò pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ lati gba àyè lati fi iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni irú ibi bẹ̃.  Bi èrò ìwòran ti ó fẹ́ mọ nipa iṣẹ́ ọ̀na Yorùbá ti pọ̀ tó, kòsí oníṣẹ́ ọnà bi: onilù, olórin ìbìlẹ́, oníṣòwò ọjà ìbílẹ̀ àti bẹ̃bẹ̃ lọ lati polówó iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni àjọ̀dún yi.

Awọn ẹ̀ka Yorùbá ti ó wà ni Brazil ló kó onílù àti oníjò “Batala” ti ó dá awọn èrò lára ya.́  Awon olonje Yoruba ri oja ta.   Awọn onilù, oníṣòwò ibile, olórin ibile, oniṣẹ ọna ati eléré ìbílẹ̀ Yorùbá ni ìlú-ọba pàdánù àti jẹ ọrọ̀ àti polongo iṣẹ ọwọ́ wọn.

Ó ṣe pàtàkì lati parapọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ lati gbé àṣà, iṣẹ́ ọnà àti èdè Yorùbá lárugẹ.

ENGLISH LANGUAGE

On Saturday and Sunday July 27 and 28, 2013 Yoruba Art Festival was held in Clissold Park in London.

According to Yoruba adage literally translates to “Anyone that says his kinsman should not be rich would rely on outsider to borrow clothes”.  This adage can be applied to the low patronage by the Yoruba budding artists and cultural groups in the United Kingdom.  It is observed that if this event had been organized by foreigners, our people would have queued to beg for a spot to display their culture.  Many of the audience/crowd were disappointed at not seeing Yoruba Artist and other Cultural display at the event.

However, the branch of Yoruba at Brazil “Batala Dance and Drum Group” gave a good performance to entertain the crowd.  The Yoruba food Vendors made brisk business.  The Yoruba indigenous Drummers, Artists, Entertainment Group, Dancers etc. lost the opportunity to show case and advertise their skills.

It is important to join hand with love to promote Yoruba Culture, Art and Language.

Share Button