Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Dúró ninú odò tó dé orókún, sunkún òùngbẹ”: Ọ̀wọ́n epo ọkọ̀ ní Nigeria – “Standing Knee deep in a River dying of thirst”: Fuel Scarcity in Nigeria

Ki i ṣe àkọ́kọ́ ti ọ̀wọ́n epo ọkọ̀ yio wáyé ni Nigeria, ṣùgbọ́n bi ijiyà ti ọ̀wọ́n epo ọkọ̀ kó bá ará ilú bá ti tán, Ìjọba àti ará ilú á gbàgbé ni wéré, wọn ki kọ́ ọgbọ́n lati ronú ohun ti wọn lè ṣe lati jẹ ki irú rẹ ma wáyé mọ.

Epo ọkọ̀ kò kọ́kọ́ wọ́n nigbati Olóri-ogun Abacha gba Ìjọba ni ọdún mejilélógún sẹhin, ṣùgbọ́n lati bi ogún ọdún, epo ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ si wọn ni ilé-epo nitori wọn kò tún ilé iṣẹ́ tó nṣe epo ọkọ̀ ṣe, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ pọ̀ fún àwọn ti o nkó epo ọkọ̀ wọlé lati Òkè-òkun àti ilé-epo.  Ijiyà yi pọ gidigidi, nitori ọ̀pọ̀ n sun ilé-epo fún ọ̀sẹ̀ kan nitori àti ri epo ọkọ̀ rà ni oye ti Ìjọba ni ki wọn ta a, ṣùgbọ́n ilé epo gbà lati ta epo fùn alarobọ̀ ju ọlọ́kọ̀ lọ.  Nigbati Olóri-ogun Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ di Olóri-Òṣèlú, ti wọn ri ọ̀rọ̀ ọ̀wọ́n epo ọkọ̀ yanjú, ilú gbàgbé iyà yi.  Yàtọ̀ si ki àwọn Ọlọ́kọ̀ epo ọkọ̀ da iṣẹ́ silẹ̀, tàbi ki òṣiṣẹ́ ilé-epo rọ̀bì da iṣẹ́ silẹ̀, ọ̀wọ́n epo ti fẹ́ di ìgbàgbé, nitori irú eleyi ki pẹ́ ju ọjọ́ meji si mẹta lọ.

Ẹ ṣe iránti, ni oṣù kini ọdún kẹta sẹhin, nitori wọn fẹ fi owó kún epo ọkọ̀ lójú ẹ̀rọ, epo ọkọ̀ wọ́n, ṣùgbọ́n bi ilú fẹ́ bi ó kọ̀, Ìjọba Goodluck Ebele Jonathan fi owó kún epo ọkọ̀ lati Naira marunlelọgọta di Naira mẹtadinlọgọrun.  Ni àsìkò yi, gbogbo èrò bọ́ sita lati sọ tinú wọn pé kò si ohun ti ó yẹ ki wọn gbé epo rọ̀bi lati Nigeria lọ si Òkè-Òkun lati lọ sọ di epo ọkọ̀, ki wọn tún fi owó ko padà silé pẹ̀lú owó iyebiye nigbati wọn lè tún ilé-iṣẹ́ to nṣe epo ọkọ̀ ṣe àti lati kọ́ tuntun si.  Ìjọba ṣe ìlérí fún ará ilú pé àwọn yio lo owó ti wọn bá ri fi tún ohun amáyédẹrùn igbàlódé ṣe, wọn o si kọ àti tún ilé-iṣẹ́ ti o nsọ epo rọ̀bì di epo ọkọ̀ ṣe.  Ọdún mẹta ti kọjá, Ìjọba kò mú ìlérí yi ṣẹ nitori àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́.  Continue reading

Share Button

“Ṣàdúrà, ki nṣe Àmin, ijà ò si ni Ṣọ́ọ̀ṣì (ilé isin Onigbàgbọ́): Idibò ni Ìlú-Ọba” – “No fight over prayer and response in the Church: Election in the United Kingdom”

Idibò lati yan Olóri àti àwọn Òṣèlú wáyé ni ọjọ́ keje, oṣù karun, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún lẹhin ọdún

Idibò ni Ìlú-Ọba - Election in the United Kingdom. Courtesy: @theyorubablog

Idibò ni Ìlú-Ọba – Polling Station.  Election in the United Kingdom. Courtesy: @theyorubablog

marun ti wọn ṣe ikan kọja.  Àsikò idibò kò dá iṣẹ́ dúró, kò si ijà tàbi ji àpóti ibò àti iwà burúkú miran ti ó nṣẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú

Gbogbo Olóri ẹgbẹ́ Òṣèlú meje ti ó jade, polongo pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ fún ibò ará ilú.  Wọn kan ilẹ̀kùn, wọn pin iwé lati ṣe àlàyé ohun ti wọn yio ṣe fún ilú.  Ẹni ti ó wà lori oyè, David Cameron ti ó ndu ipò rẹ padà, lọ lati ibẹ̀rẹ̀ dé òpin Ìlú-Ọba lati ṣe àlàyé ohun ti ẹgbẹ́ rẹ ṣe fún ilú àti eyi ti ó kù ti àwọn yio ṣe.  Àwọn Òṣèlú Ìlú-Ọba kò pin ìrẹsì àti owó lati ra ibò bi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdu pàtàki ni orilẹ̀ èdè Nigeria.

Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá igbàlódé, “Ṣàdúrà, ki nṣe Àmin, ijà ò si ni Ṣọ́ọ̀ṣì”, àwọn Òṣèlú Ilu-Oba kò sọ idibò di ijà, ẹgbẹ́ kan kò rán jàndùkú si ọmọ ẹgbẹ́ keji, wọn ò ji àpóti ibò, wọn ò sọ ipò Òṣèlú di oyè idilè bi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdu ti ó nlo ipò wọn lati mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú.  Bi ó bá di àsikò idibò, wọn a lo ẹ̀sin àti ẹ̀yà lati pin ará ilú dipò ki wọn sọ ohun ti wọn ṣe tàbi ohun ti wọn yio ṣe lati tú ilú ṣe pàtàki lati gba ilú lọwọ òkùnkùn àti àwọn olè ti ó nṣe Ìjọba.  Ó yẹ ki àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdu fi eyi kọ́gbọ́n.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Ogún ọdún nbọ̀ wá ku òla – Ọjọ́ idibò tuntun ni Nigeria wọlé wẹ́rẹ́: Twenty years to come will soon remain a day – Nigerian New Election Day is here

Ijọba Nigeria sún idibò kúrò ni oṣù keji, ọjọ́ kerinla si oṣù kẹta, ọjọ́ kejidinlogbon ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún nitori àwọn Ológun ni àwọn kò lè daabo bo ará ilú ni àsikò idibò.  Wọn ni àwọn fẹ dojú ijà kọ ẹgbẹ́ burúkú ti a mọ̀ si “Boko Haram”.

Àwọn ará ilú fi ibinú han nipa ki kọ isún siwájú ọjọ́ idibò, ṣùgbọ́n nigbati Olóri Ilé-iṣẹ́ Idibò Attahiru Jega ṣe àlàyé wi pe,́ ẹmi àwọn òṣìṣé idibò ṣe pàtàki, ohun kò lè fi ẹ̀mi wọn wewu nitori eyi, ó rọ ará ilú lati gba ọjọ́ tuntun ti wọn sún idibò si.

Àwọn ti ó ndu ipò Òṣèlú fi si sún idibò siwájú polongo lati rọ àwọn ará ilú fún ibò wọn.  Eleyi fa inira fún àwọn awakọ̀ pàtàki ni ilú Èkó, ó si tún ba ọrọ̀ ajé jẹ́.  Ọjọ́ Idibò naa ló wọlé dé wẹ́rẹ́ yi nitori ó di ọ̀la.  Bi ará ilú bá fẹ́ ki àyipadà rere dé si ìyà a kò si iná, kò si omi àti ohun amáyédẹrùn igbàlódé, a rọ àwọn ọmọ Nigeria rere ki wọn tu jade lati ṣe ojuṣe wọn lati lọ dibò yan ẹni ti wọn ba lero wi pé ó lè ṣe àtúnṣe si ipò Òṣèlú tuntun.

Ẹgbẹ́ gbigbé àṣà àti èdè Yorùba lárugẹ gbadura pé ki ó má si ogun tàbi ijà ni àsikò àti ki ilú tura lẹhin idibò.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

“Etí tó gbọ́ àlọ, yẹ ki ó gbọ́ àbọ̀”: Ìjọba Nigeria sún Ọjọ́ Idibò siwájú – The ear that heard the announcement of a journey ought to be informed of the return: Postponement of Election

Dasuki Sambo

Ológun fẹ́ fi ọ̀sẹ̀ mẹfa dojú ijà kọ “Boko Haram – We’ ll crush Boko Haram in 6 weeks—Dasuki

Ọ̀rọ̀ àgbọ́sọ, pé wọn fẹ́ sún ọjọ́ idibò siwájú lu jade ni kété ti ọjọ́ idibò kù bi ọ̀sẹ̀ mẹta.  Iroyin yi kọ́kọ́ lu jade lẹ́nu Ọ̀gágun Dasuki, Onimọ̀ràn Aabo fún Olóri-Òṣèlú Nigeria Jonathan Goodluck.  Ó ni àwọn Ológun fẹ́ fi ọ̀sẹ̀ mẹfa dojú ijà kọ “Boko Haram”, ẹgbẹ́ burúkú ti ó ti gba àwọn ilú ni Òkè-Ọya, Nigeria lati bi ọdún marun. Nitori eyi, kò lè si àyè fún àwọn Ológun lati sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọpa lati pèsè àbò ni àsikò idibò ti wọn ti fi si oṣù keji ọdún, ọjọ́ kẹrinla.

Nigbati Olóri-Òṣèlú pe ipàdé àwọn àgbàgbà, ọ̀pọ̀ àwọn ará ilú tu jade lati tako si sún ọjọ́ idibò  siwájú.  Ọ̀gá ilé-iṣẹ́ Alabojuto ètò idibò, Ọ̀jọ̀gbọ́n Attahiru Jega, ṣe àlàyé fún àwọn Akọ̀wé-iroyin pé, Ìjọba sọ pé wọn kò lè dá aabo bo àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ti àwọn yio gbà si iṣẹ́ àti ará ilú ti ó fẹ dibò ni àsikò idibò.   Ó ni Ìjọba ni àwọn fẹ fi ọ̀sẹ̀ mẹfa fi taratara dojú ijà kọ “Boko Haram”, nitori eyi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Attahiru Jega, sọ wipé àwọn kò lè fi ẹ̀min àwọn òṣìṣé àti ará ilú wewu, nitorina wọn gbà lati sún ọjọ́ idibò siwájú.

Ọjọ́ idibò tuntun lati yan Olóri-Òṣèlú yio wáyé ni ọjọ́ keji-din-lọgbọn, oṣù kẹta, idibò lati yan Gómìnà yio wáyé ni ọjọ́ kọ-kànlá oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdogun.  Kiló ṣe ti Ìjọba kò fi taratara jà lati da aabo bo ilú lati bi ọdún marun?  Owe Yoruba so wipe “Onígbèsè tó dá ogún ọdún, kò mọ̀ pé ogún ọdún nbọ̀ wá ku ọ̀la”, nitorina, ki àwọn ará ilú fi ọwọ́ wọ́nú, nitori ọjọ́ tuntun wọnyi súnmọ́ etíle. Continue reading

Share Button

“Ẹrú kú, iyá ò gbọ́, ọmọ́ kú ariwo ta: Oniṣẹ́-ẹ̀rù pa èniyàn mejila ni France, nigbati Boko-Haram pa Ẹgbẹ-gbẹrun ni Nigeria” – “The Slave died, the mother was not informed, a freeborn died, wailing erupted: Terrorists killed twelve in France while killing thousands in Nigeria”

 

Oniṣẹ́-ẹ̀rù pa èniyàn mejila ni France – As it happened: Charlie Hebdo attack

Ariwo ta, gbogbo àgbáye mi tìtì nigbati iroyin àwọn ti ó fi ẹ̀sìn bojú pa èniyàn mejila ni Paris jade.  Ni ọjọ́ keje, oṣù kini ọdún Ẹgbã-le-mẹdogun, àwọn ti ó fi ẹ̀sìn bojú pa àwọn Olùtẹ̀ iwé Aworẹrin “Charlie Hebdo” nibiti wọn ti nṣe ipàdé nipa ohun ti wọn yio gbe jade ninu iwé Aworẹrin ti ọ̀sẹ̀ naa.  Gbogbo àwọn Olóri Òṣèlú àgbáyé fi ọwọ́ so ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú Olóri Òṣèlú France.

 

Idibò ṣe pàtàki fún Òṣèlú ju àti wá ọ̀nà àti dojú ijà kọ Boko Haram – What made the Paris attack more newsworthy than Boko Haram’s assault on Baga?

Idà keji, ẹgbẹ́ “A ò fẹ́ iwé – Boko Haram” jó odidi ilú Baga ni Ariwa Nigeria, wọn si pa Ẹgbã èniyàn lai mi àgbáyé.  Iyàtọ̀ ti ó wà ni bi àgbáyé ti ké lóri ikú èniyàn méjilá ni Paris ni pé, Olóri Òṣèlú àti gbogbo ará ilú parapọ̀ lati fi ẹ̀dùn han.  Gbogbo àgbáyé ké rara nigbati wọn ji ọmọ obinrin igba ó lé diẹ̀ gbé lọ ni Chibok ni Òkè-Ọya Nigeria, ṣùgbọ́n titi di òni, wọn kò ri àwọn obinrin wọnyi gbà padà.  Òbi míràn ti kú nitori iṣẹ̀lẹ̀ ibi yi.

Yorùbá ni “Ẹlẹ́rù ni nké ọfẹ”.  Iṣe àti iwà Olóri Òṣèlú àti Ìjọba-Alágbádá, kò fún àgbáyé ni ìwúrí lati ma a kẹ́dùn nigbati àwọn ti ó kàn kò fihàn pé wọn tara fún ẹ̀mí.  Lati igbà ti Boko Haram ti npa tàbi ji èniyàn gbé ni Òkè-Ọya, Olóri ilú kò lọ lati kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ti èniyàn wọn sọ ẹmi nu.  Wọn kò si fún àwọn Jagun-jagun ni ohun ijà ti wọn lè fi dojù kọ Boko Haram.  Lati ọdún ti ó kọjá, ipalẹ̀mọ́ idibò ọdún yi ṣe pàtàki fún àwọn Òṣèlú ju àti wá ọ̀nà àti dojú ijà kọ Boko Haram.  Irú iwà bayi kò lè ṣẹlẹ ni Òkè-Òkun àti pé ará ilú Òkè-Òkun kò ni gbà fún Òṣèlú, nitori ẹ̀mí èniyàn ṣe pàtàki ju idibò lọ.

ENGLISH TRANSLATION
Continue reading

Share Button

Ẹni sanwó Onífèrè ló ndá orin: Ọ̀rọ̀ Ike-ìyáwó – “He who pays the Piper, dictates the tune: Credit Card Matter”

Money Lenders

Ikilọ̀ fún Ayáni-lówó tipátipá – Warning for rogue payday loan firms

À ńlo ọ̀rọ̀ yi fún àwọn Ayáni-lówó: ki ba jẹ Ilé-owó tàbi àwọn Ayáni-lówó yókù.  Ọ̀pọ̀ ìgbà, Ayáni-lówó ló ndá orin nipa oye èlé ti wọn lè fi lé owó ti Onígbèsè ya.

Ni ilẹ̀ Yorùbá ohun ti a lè fi ṣe àpèjúwe Ilé-iṣẹ́ Ayáni-lówó ni bi Ọba bá fún ni nilẹ̀ lati fi dá oko, Ọba lè ni ki irú ẹni bẹ kó idá-mẹrin, tàbi idá-marun irè oko nã wá ni igbà ìkórè.  Àwọn miran tún ma ńyá owó lọwọ Olówó-èlé.  Ẹ̀yà Yorùbá ti a mọ si Ìjẹ̀ṣà ma ńṣe òwò aṣọ àti wúrà tità lati ilú dé ilú  àti agbègbè dé agbègbè.  Bi wọn ba ti ta àwin fún onibara, bi ọjọ́ bá pé, Ìjẹ̀ṣà á ji lọ si ilé Onígbèsè lati gba owó ọjà, á ni “Òṣó mã ló gbowó mi loni” nitori eyi ni wọn fi npe Ìjẹ̀ṣà ni “Òṣó mã ló”.

Ike-ìyáwó kò wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n  àwọn enia ma ńyá owó lọ́wọ́ ẹbi, ọ̀rẹ́, ẹgbẹ́ àti bẹ̃bẹ lọ, lati sin òkú, sán owó ilé iwé ọmọ, ṣòwò àti fún ọ̀pọ̀ idi miran.  Èlé owó irú eyi kò pọ̀ tó ti èlé ori Ike-ìyáwó, nigbà miran kò ki ni èlé.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ ti ó ni:“Ẹni sanwó Onífèrè ló ndá orin”. Ayáni-lówó ló ńdá orin nipa di dari èlé ori owó Ike-ìyáwó.  Ẹni ti o fi owó pamọ́ ki ri èlé gbà tó èlé ti ó wà lori owò Ike-ìyáwó.  Nibiti èlé owó ipamọ́ bá jẹ́ idá-ọgọrun, èlé owó ori ike-iyawo lè tó idá-marun tàbi jù bẹ̃ lọ.  Bi owó bá ti tó san, ọ̀pọ̀ Ayáni-lówó lè fi ipá gba owó irú bẹ̃.  Bi wọn kò ti ẹ̀ fi ipá gba irú owó bẹ̃, èlé ori owó yi á sọ ẹni ti ó yá owó  di Onigbèsè rẹpẹtẹ.

Ike-ìyáwó ni iwúlò fún ẹni ti ó bá lè kó ara rẹ ni ijánu lati dá owó padà nigbati ó bá yẹ.  Ike-ìyáwó dùn lati nọ́ ju owó gidi lọ nitori eyi, fún ẹni ti kò bá mọ owó ṣirò tàbi ṣọ́ra, á sọ irú ẹni bẹ̃ di òtòṣi, nigbati èlé bá gun ori èlé.  Onigbèsè pàdánù òmìnira.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

“Aṣeni ṣe ara rẹ, asánbàntẹ́ so ara rẹ lókùn: iwà/ijà-agbára inú ilé/ẹbi” – He who would hurt others hurts himself: Domestic Violence” – Ray Rice Video

Òwe Yorùbá sọ pé “Ẹni a lè mú, là  nlèdí mọ́”.  Òwe yi fi iwà burúkú nipa ìwà/ìjà-agbára ti ó nṣẹlè ni inú ilé, pàtàki laarin ọkùnrin àti obinrin tàbi ọkọ àti ìyàwó.  Ki ṣe ọkùnrin nikan ló nhu ìwà/ìjà-agbára si obinrin, obinrin oníjà miran ma nhu ìwà/ìjà-agbára si ọkùnrin tàbi si ọkọ, ṣùgbọ́n, eyi ti ó wọ́pọ̀ jù ni ọkùnrin si obinrin.

Bawo ni ènìyaìn ṣe lè sọ pé, ohun ni ìfẹ́ nigbati ó bá hu ìwà-agbára si ẹni ti ó fẹ́ràn?  Ọ̀pọ̀lọpọ̀  ilé yi, ẹni tó nhu ìwà/ìjà-agbára ìwà burúkú ma nṣe si ẹni ti wọn bá rò pé àwọn lè mú tàbi ti wọn ni agbára ni ori rẹ.  Àwọn ti wọn hu iwa-agbara si yi, ki le fi ẹjọ́ sùn, nitori ìbẹ̀rù ẹni ti ó ni agbára jù wọn lọ, pàtàki laarin ọkọ àti aya.  Obinrin ti ó njẹ  iya  ìwà/ìjà-agbára ki lé tètè kúrò tàbi ki wọn fi ẹjọ́ sùn nitori àwọn idi pàtàki bi: ìfẹ́ si ẹni ti ó nhu ìwà/ìjà-agbára; àyípadà; itiju ki èrò ma gbọ́; ai fẹ ki ìgbéyàwó túká; ai lè dá dúró nitori owó tàbi àwọn ọmọ ti wọn bi si irú ilé bẹ-ẹ; ìyà ti mọ́ra; àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

0907-ray-ric-elevator-gif-launch-the-aftermath-01

ìjà-agbára ti “Ray Rice” hu – Ray Rice-elevator-knockout-fiancee-takes-crushing-punch-video/

Ìbínú burúkú ló nfa iwa/ija-agbara.  Igbẹhin ìwà/ìjà-agbára ki já si ire, nitori irú ìwà burúkú yi lè fa  ikú ojiji; àrùn ọpọlọ; ìrẹ̀wẹ̀sì; li lọ si ẹ̀wọ̀n; ìbànújẹ́ fún àwọn ọmọ; àbùkù fún ẹni ti ó hu irú ìwà yi àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.  Irú àbùkù yi ló kan “Ray Rice” nigbati ìjà-agbára ti ó bá Àfẹ́sọ́nà rẹ̀ jà ninú ẹ̀rọ-àkàbà ti ó lu jade si gbogbo àgbáyé ninú ìròyìn àti ori ayélujára.   Gẹgẹbi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Aṣeni ṣe ara rẹ, asánbàǹtẹ́ so ara rẹ lókùn”, lati ìgbà ti àṣiri ìwà/ìjà-agbára ti “Ray Rice” hu ti tú, aṣeni ti ṣe ara rẹ nitori iṣẹ rẹ ti bọ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

“Ìwà lẹ̀sìn, A ki fi òtítọ́ sinú gbàwìn ìkà”: Ìjọba Sudan dá ẹjọ́ ikú fún Mariam Yahia Ibrahim nitori ẹ̀sin – “Good Character is key to worship”

Sudan Death Sentence Woman Gives Birth In Jail

 

Mariam Yahya Ibrahim

Ìjọba Sudan dá ẹjọ́ ikú fún Mariam Yahia Ibrahim nitori ẹ̀sin – Sudan Death Sentence Woman Gives Birth In Jail

Yorùbá ni “Ọmọ ẹni kò lè burú titi, ká fi fún Ẹkùn pa jẹ”, ki ṣe bi ti obinrin Sudan – Mariam Yahia Ibrahim ti wọn gbé si ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú oyún lati dúró de idájọ́ ikú lẹhin ọmọ bibi nitori ẹ̀sìn.  Ohun pẹ̀lú ọmọ ti ó ti bi tẹ́lẹ̀ ni wọn gbé jù si ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn pé kò yẹ ki ó fẹ́ ìgbàgbọ́ lábẹ́ òfin “Sharia”.  Lábẹ́ òfin yi, ọkunrin Ìmàle lè fẹ́ obinrin ni ẹ̀sìn miran, ṣùgbọ́n obinrin wọn kò ni ẹ̀tọ́ lati fẹ́ ẹni ti ó bá ṣe ẹ̀sìn miran.

Kò si bi ẹni ti ó fa ọmọ rẹ̀ silẹ̀ nitori ó fẹ́ ẹlẹ́sìn miran ti lè sọ pé ohun ni òtitọ́ ninú gbàwìn ìkà.  Bawo ni enia ṣe lè pa ẹni-keji nitori ẹ̀sìn? Ìkà ti wà ninú irú àwọn bayi ki wọn to gba ẹ̀sìn, wọn kan fi ẹ̀sìn bojú ṣe ìkà ni.  Àjà ni wọn fi ḿbọ̀ Ògún ki ṣe enia.  Yorùbá ni “A ki fi ọmọ Ọrẹ̀, bọ Ọrẹ̀”, òwe yi túmọ̀ si pe abòriṣà Yorùbá kò jẹ́ fa ọmọ rẹ silẹ fún ikú nitori ó yà kúrò ninú ẹ̀sin ibilẹ̀.

Ibrahim has a son, 18-month-old Martin, who is living with her in jail, where she gave birth to a second child last week. By law, children must follow their father's religion

Ohun pẹ̀lú ọmọ ti ó ti bi tẹ́lẹ̀ ni wọn gbé jù si ẹ̀wọ̀n – Meriam Ibrahim with her son and the newborn

Ìròyìn jade pé Mariam Yahia Ibrahim ti bi ọmọ si ẹ̀wọ̀n, a ri ninú ẹbi rẹ ti o ke pe ki won fi ikú si-so pá ti ó bá kọ̀ pé ohun kó padá si ẹ̀sìn Ìmàle.  Gbogbo àgbáyé ḿbẹ̀ àwọn Òṣèlú Sudan ki wọn tú obinrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ silẹ̀ nitori irú ẹjọ́ oró yi, kò tọ̀nà ni ayé òde òni.

 

 

 

ENGLISH LANGUAGE Continue reading

Share Button

“Ẹni ti o ni ori rere, ti kò ni iwà, iwà rẹ ni yio ba ori rẹ̀ jẹ́”: “Evil character ruins good fortune – Jimmy Savile”

Jimmy Savile abused at least 500 victims

Ọ̀pọ̀ ti ó ni ipò ni àwùjọ ni ó fi iwà ikà ba ipò wọn jẹ.  Ìròyìn bi Olóògbé Jimmy Savile ti fi iwà burúkú ba iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe nipa pi pa owó fún ọrẹ-àánú ni ó ńlọ lọ́wọ́-lọ́wọ́.  Iṣẹ́ ibi ti ó ṣe ni igbà ayé rẹ fihan pé “O ni ikù ló mọ̀ ikà”.  Gẹ́gẹ́ bi iwadi ti o jáde lẹhin ikú Olóògbé yi, ó lo ipò rẹ ni àwùjọ lati bá ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta obinrin ni àṣepọ̀ ni ọ̀nà ti kò tọ́.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Ẹni ti o ni ori rere, ti kò ni iwà, iwà rẹ ni yio ba ori rẹ̀ jẹ́” fihàn pé Jimmy Savile fi iwà àbùkù ba iṣẹ́ rere ti ó ṣe jẹ.  Ìṣẹ̀lẹ̀ Jimmy Savile kò ṣe àjòjì ni ilẹ̀ Yorùbá.  Ni ayé àtijọ́, àwọn Ọba tàbi Olóyè miran ma ńlo ipò wọn lati ṣe iṣẹ ibi – bi ki wọn gbé ẹsẹ̀ lé iyàwó ará ilú; fi ipá gba oko tàbi ilẹ̀ ará ilú lai si ẹni ti ó lè mú wọn ṣùgbọ́n láyé òde òni, Ọba tàbi Olóyè ti ó bá hu iwà burúkú wọnyi, yio tẹ́.

Ọba/Olóyè yio ti ṣe iwà ibi yi pẹ́, ki ilú tó dide lati rọ̃ loye, ṣùgbọ́n láyé òde òni ki pẹ́, ki ẹni ti ó bá fi ipò bojú iwà burúkú yi tó tẹ́.  Ọba/Olóyè/Ọlọ́rọ̀ Yorùbá ti ó bá fi ipò tàbi ọlá hu iwà ikà ni ayé igbàlódé yi, kò ri ibi pamọ́ si, nitori àṣiri á tú ninú iwé-ìròyìn, ẹ̀rọ-asọ̀rọ̀-mágbèsi, ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti lori ayélujára.

 Oba Adebukola Alli nysc corper

Ọba Adébùkọ́lá Alli – Alọ́wá ti Ìlọ́wá ti obinrin Agùnbánirọ̀ fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ipá ni àṣepọ̀ – accused by Female Youth Corper of rape

Ki ṣe ará ilú nikan ló lè ṣe ìdájọ́ fún Ọba ti ó bá hu iwà ikà nipa ri-rọ̀ lóyè, gbogbo àgbáyé ni yio ṣe idájọ́ fun, irú Ọba/Olóyè/Ọlọ́rọ̀ bẹ̃ yio tun fi ojú ba ilé-ẹjọ́.   Fún àpẹrẹ: Ọba Adébùkọ́lá Alli – Alọ́wá ti Ìlọ́wá ti obinrin Agùnbánirọ̀ fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ipá ni àṣepọ̀ àti  Déji Àkúrẹ́ ti wọn rọ̀ lóyè nitori iwa àbùkù – Oluwadare Adeṣina.

 

 

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

“Bi a ò bá gbàgbé ọ̀rọ̀ àná, a ò ni ri ẹni bá ṣeré” – Apàniyàn Rodger Elliot: “If one does not forget past misdeed/grudge, one would not get anyone to play with” – Killer Rodger Elliot

Isla Vista shooting

Carnage: The scene of a mass shooting in the college town of Isla Vista, CA

Ìròyìn iṣẹ̀lẹ̀ ọ̀dọ́-kùnrin, ọmọ ọdún meji-le-logun – apàniyàn Rodger Elliot ti ó kàn ni ọjọ́ karun-din-lọ́-gbọ̀n, oṣù karun ọdún Ẹgbẹ̀wá-le-mẹrinla, fi àpẹrẹ ohun ti ó lè ṣẹlẹ̀ bi a ò bá gbàgbé  ọ̀rọ̀ àná.  Gẹ́gẹ́ bi àsọtẹ́lẹ̀ ti apàniyàn yi fi silẹ lori ayélujára ni pé “Ayé òhun dà rú nigbati obinrin àkọ́kọ́ ti òhun fi ìfẹ́ hàn si lọ́mọdé fi òhun ṣe yẹ̀yẹ́, eleyi da ọgbẹ́ fún òhun gidigidi”, nitori èyi ó já si igboro lati pa enia.  Lẹhin ti ó ti pa enia mẹfa, ṣe enia meje miran le-ṣe, Ọlọpa yin ìbọn fún lori lati dá iṣẹ́ ibi yi dúró.

Lai gbe ìbọn, ọ̀bẹ, àdá àti ọ̀kọ̀, ọgbẹ́ ọkàn ti ai gbàgbé ọ̀rọ̀ àná ńdá silẹ̀ lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì fún ẹni ti kò gbàgbé ọ̀rọ̀ àná.  Ninú ewu ti ó wà ni ai gbàgbé ọ̀rọ̀ àná ni pé ọmọ iyá meji lè túká; ọkọ àti aya lè túká; orilẹ̀ èdè kan lè gbé ogun ti ekeji; ọrẹ meji lè di ọ̀tá ara; aládũgbò lè di ọ̀tá ara àti bẹ̃bẹ lọ.

Ó ṣòro lati bá ara gbé, lai ṣẹ ara.Yorùbá́ ni “Igi kan ki dá ṣe igbó”, nitori Ọlọrun kò dá enia lati dá nikan gbé.    Ọ̀pọ̀ ẹni ti ó dá ni kan wà ni Èṣù ńlò, nipa ri ro èrò burúkú ti ó lè fa àìsàn tabi iṣẹ́ ibi bi irú èyi ti apànìyàn Rodger Elliot ṣe.

Ó yẹ ki á fi òwe Yorùbá ti ó ni “Bi a ò bá gbàgbé ọ̀rọ̀ àná, a ò ni ri ẹni bá ṣeré” yi gba ẹni ti a bá ṣe àkíyèsí pé ki gbàgbé ọ̀rọ̀ àná ni iyànjú nipa ewu ti ó wà ni irú ìwà bẹ̃.

ENGLISH TRANSLATION
Continue reading

Share Button