Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

Ẹkáàbọ̀ si ọdún Ẹgbàálémọ̀kándínlógún – Welcome to 2019

Àwn ohun ti a kò rò wọ̀nyí kò ni wlé tọ̀ wáAll these unexpected will not come near.

 

Share Button

Ni ìrántí àwọn ti ó gbé àṣà àti èdè Yorùbá lárugẹ ti ó di olóògbé ni Ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún – In memory of Prof. Akinwunmi Isola and Baba Sala who died in 2018

A bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá si ìlú Ìbàdàn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni oṣù kejìlá, ọjọ kẹrìnlélógún, ọdún Ẹdẹgbaalemọ́kàndínlógójì. Ó kú lẹhin ti ó pé ọdún méjìdínlọ́gọ́rin ni oṣù keji, ọjọ́ kẹtàdínlógún, ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún.  Iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe fún èdè àti àṣà Yorùbá kò ṣe é gbàgbé.  Ki Ọlọrun má a fún ẹ̀mí rẹ ni ìsimi.

Ni ìgbà ayé Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, ó fi iṣẹ́-akẹkọ gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ pẹ̀lú onkọwe-eré, eré-ṣíṣe, eré-ìtàgé àti ajàfẹtọ-àṣà.   Bi ó ti ẹ jẹ wí pé, ó kọ́ ẹ̀kọ́ lóri èdè Faransé, ó kọ ọ̀pọ̀lopọ̀ eré àti àwọn ìwé tó gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ bi: Efúnṣetán Aníwúrà, Tinubu-Ìyálóde Ẹ̀gbá, Ṣaworoidẹ àti bẹ́ ẹ̀ b ẹ́ ẹ̀ lọ.

Mósè Ọláìyá Adéjùmọ̀ (ti àdá-pè rẹ njẹ́ Bàba Sàlá) jẹ́ ọmọ Yorùbá lati Iléṣà ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun.  Ni ìgbà ayé rẹ, ó lo ẹ̀bùn orin-kí kọ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọdún kẹrinladọta sẹ́hìn, àwàdà àti eré-ìtàgé gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ.  Ni ayé ìgbàlódé, Bàba Sàlá jẹ aṣájú fún gbogbo Aláwàdà ni orílẹ̀-èdè Nigeria.

A bi Mósè Ọláìyá Adéjùmọ̀ (ti gbogbo èrò mọ̀ si “Bàba Sàlá”) ni oṣù karun jo kejidinlogun, ọdún Ẹ̀dẹ́gbaa-lémẹ́rìndínlógójì, ó gbé ayé titi di oṣù kẹwa, ọjọ́ keje ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún.  Ogún rẹ̀ fún àwọn Òṣèré yio dúró titi. Ki Ọlọrun má a fún ẹ̀mí rẹ ni ìsimi.

ENGLISH TRANSLATION

Professor Akinwunmi Isola was born in Ibadan, Oyo State on December 24, 1939.  He died after his  78 birthday on February 17, 2018.  His immense contribution to Yoruba language and culture lives on.  May God continue to grant his soul peace. Continue reading

Share Button

Olùkọ̀wé Èdè àti Àṣà Yorùbá lóri ayélujára, ki gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nigeria kú àjọ̀dún Òmìnira kejìdínlọ́gọ́ta – The Yoruba Blog wishes all Nigerians happy 58th Independence Celebration

Àsíá orílẹ̀ èdè Nigeria – Nigerian Flag.

Fún ọdún mọ́kàndín-lọgọrun lati ìgbà ti Òyìnbó Ìlú-Ọba ti fi ipá gba Èkó titi di ọjọ́ kini oṣù kẹwa, odun Ẹgbẹ̀sánlé-ọkanlelọgọta ti orílẹ̀ èdè Nigeria gba Òmìnira, Òyìnbó Ìlú-Ọba kan èdè Gẹ̀ẹ́sì wọn nípá, wọ́n tún gàba lóri ọrọ adánidá ni orílẹ̀ èdè Nigeria.  Ṣi ṣe ìrántí Òmìnira yẹ kó rán gbobgo ọmọ Nigeria lápapọ̀ létí iṣé takun-takun ti àwọn olóri òṣèlú parapọ̀ ṣe lati tú orílẹ̀ èdè sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì, pàtàki bi àwọn olóri òṣèlú Ìlà-oòrùn àti Ìwọ̀-oòrùn ti kó ra pọ̀.  Èyi fi hàn wi pé bi àwọn  òṣèlú ayé òde òní bá fi ìfẹ orílẹ̀ èdè ṣáájú, wọn kò ni fi ẹ̀sìn àti ẹ̀yà bojú lati tú orílẹ̀ èdè ka, èyi ti ó njẹ ki wọn ri àyè jí ìṣúra orílẹ̀ èdè si àpò ara wọn nitori eyi, ó yẹ ki gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nigeria ti ó ni ìfẹ́ orílẹ̀ èdè, pẹnupọ̀ lati bá àwọn òṣèlú ti ó nja ilú ló olè wi.

Bi a ṣe nṣe àjọ̀dún Òmìnira kejìdínlọ́gọ́ta yi, ó yẹ ki gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nigeria gbé ìfẹ́ lékè ìríra.  Ìfẹ́ ló lè borí li lo ẹ̀yà àti ẹ̀sìn lati pín orílẹ̀ èdè, ti ó tún lè dín ojúkòkòrò àwọn òṣèlú kù.

Lati ọ̀dọ̀ àwọn Olùkọ̀wé Èdè àti Àṣà Yorùbá lóri ayélujára, a ki gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nigeria kú àjọ̀dún Òmìnira.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yan ẹni ti yio du ipò fún ẹgbẹ́ kò yẹ kó fa ìjà laarin Gómìnà Àmbọ̀dé àti Bàbá Òṣèlú rẹ, Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu – Adoption of Direct Primary should not cause a rift between Gov. Ambode and his political Godfather former Gov. Bola Tinubu

Nínú gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú orílẹ̀ èdè Nigeria, àwọn alágbára díẹ̀ nínú ẹgbẹ́ ni ó ńyan ẹni ti wọ́n fẹ́ ki o fi iga gbága fún ipò pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yoku.  Ó ti di àṣà ki Gómìnà Èkó lo ọdún mẹrin nigbà méji tàbi ọdún mẹjọ lóri ipò Gómìnà.  Lati ìgbà òṣèlú alágbádá kẹrin ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọdún kọkàndínlógún sẹhin ni orílẹ èdè Nigeria, ni ìpínlẹ̀ Èkó ti yan Bọ́lá Ahmed Tinubu si ipò Gómìnà.  Ìpínlẹ̀ Èkó fẹ́ràn Bọ́lá Tinubu, èyi jẹ́ ki ó di ẹni àmúyangàn fún gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú ti ó wà, nitori èyi ẹni ti ó bá fi ọwọ́ si, fún ipò òṣèlú ni àwọn èrò ìpínlẹ̀ Èkó mba fi ọwọ́ si.

Lẹhin ọdún mẹjọ ti Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu pari àsìkò tirẹ̀, fún àìdúró iṣẹ ribiribi ti ó ṣe ni ìpínlẹ̀ Èkó, ó pẹ̀lú àwọn ògúná gbòngbò òṣèlú ti ó yan Gómìnà Babátúndé Rájí Fáṣọlá ti òhun naa lo ọdún mẹjọ. Gẹ́gẹ́ bi bàbá àgbà òṣèlú, Bọ́lá Tinubu da òróró si orí Gómìnà Àmbọ̀dé, èyi jẹ́ ki ó mókè ju gbogbo àwọn ti ó du ipò àti di Gómìnà ni ọdún kẹta sẹ́hìn, ti ó si fa ọ̀tá laarin ẹgbẹ́ àti àwọn ti ó du ipò Gómìnà fún Bọ́lá Tinubu.

Ipò Gómìnà tàbi ipò òṣèlú ki i ṣe oyè ìdílé ti kò ṣe é dù bi ìlú bá ti yan olóyè tán.  Ni ìjọba òṣèlú, ọdún mẹrin-mẹrin ni wọn ńdìbò yan àwọn òṣèlú si ipò.  Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ni àwọn fẹ́ kọ àṣà ki àwọn Bàbá-ìsàlẹ̀ má a da òróró si orí ẹni ti wọn fẹ́ fún ẹgbẹ́ mọ́, ṣùgbọ́n ki wọn gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ láyè lati yan ẹni ti yio fi iga gbága fún ipò òṣèlú pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú yoku.  Èyi ló dára jù fún ìjọba tiwa ni tiwa.

Gómìnà Àmbọ̀dé ṣí ọ̀nà mọ́kànlélógún – Gov. Ambode commissions 21 Lagos Roads

Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ńpalẹ̀mọ́ lati ṣe àpèjọ òṣèlú ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yio fi dìbò àkọ́kọ lati yan ẹni ti wọn fẹ lára àwọn ti ó ba jade fún ipò oselu. Lati ìgbà ti Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá ti fi ọwọ́ si ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yan ẹni ti wọn fẹ́ yi, ni ìròyìn ti gbòde pé, ó ti bá ọmọ òṣèlú rẹ̀ Gómìnà Àmbọ̀dé  jà, ó sì ti da òróró lé orí Jídé Sanwóolú lati gba ipò lọ́wọ́ Gómìnà Àmbọ̀dé lẹhin ọdún mẹrin péré.  Eleyi kò yẹ kó fa ìbẹ̀rù tàbi àìsùn fún Gómìnà Àmbọ̀dé nitori àwọn iṣẹ́ ribiribi ti èrò ìpínlẹ̀ Èkó ri pé ó ti ṣe.  Àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ti ó jade lati du ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú Gómìnà Àmbọ̀dé ni Ọ̀gbéni Jídé Sanwóolú àti Ọbáfẹ́mi Hamzat.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀, Bọ́lá Tinubu – ògúná gbòngbò Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwáju,́ fi ọwọ́ si ètò ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ dìbò yan ẹni ti wọn fẹ́ ni ipó – Former Lagos Gov. Bola Tinubu, an influential member of the All progressive Party backs the election of nominees by party members

Ki ìjọba alágbádá ìgbàlódé tó dé, Yorùbá ni bi wọ́n ṣe nṣe ètò ìlú.  Ètò ìlú ayé ìgbà àtijọ́ kò bẹ̀rẹ̀ tàbi pin si ọ̀dọ̀ Ọba àti Ìjòyè ìlú nìkan.  Ètò ìlú bẹ̀rẹ̀ lati ìdílé, nitori kò si ẹni ti kò ni olórí ẹbí tàbi àgbà ìdílé, lẹhin eyi, àdúgbò ni àgbà àdúgbò, bẹni abúlé-oko ni Baálẹ, ọjà ni olórí.

Ètò òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá bàjẹ́ lati igbà ti àwọn ológun ti bẹ̀rẹ̀ si fi ibọn gba ipò òṣèlú, nitori wọn kò náání Ọba tàbi Ìjòyè bẹni wọn kò kọ́ ológun ni iṣẹ́-òṣèlú bi kò ṣe ki wọn gbèjà ìlú tàbi orílẹ̀-èdè.  Ẹ̀yà mẹta ni Nigeria pin si tele – Yorùbá, Haúsá, Ìgbò, nṣe ètò agbègbè wọn, wọn ńsan owó-ori fún ìjọba àpapọ̀.  Ni ọ̀kànlélàádọ́ta ọdún sẹhin, ìjọba ológun da gbogbo ẹ̀yà mẹtẹta yi papọ̀ ki wọ́n tó pin si ẹ̀yà méjìlá si abẹ́ ìjọba àpapọ̀.  Lati igbà yi ni nkan kò ti rọgbọ.

Bọ́lá Tinubu, supports APC members electing their nominee

Ètò ti ìjọba-òṣèlú lọ́wọ́lọ́wọ́ – Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú, fẹ́ gbé kalẹ̀ lati yan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti yio gbé àpótí ìbò fún ipò òṣèlú nipa ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ lè dìbò yan ẹni ti ó bá wù wọ́n, dára gidigidi.  Tẹ́lẹ̀, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ni o ma ńdìbò fún àwọn ti wọn yio yàn lati gbe àpóti ìbò.  Eleyi ki i jẹ ki àwọn òṣèlú mọ ará ìlú tàbi ki ará ìlú mọ àwọn ti ó wà ni ipò òṣèlú nitori wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ìbò nitori wọn ni “Bàbá Ìsàlẹ̀” lẹhin.

Nigbati wọn lo ètò titun yi ni ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun, lati yan ẹni yio gbe àpótí ìbò fún ipò Gómìnà Ọ̀ṣun, inú gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ dùn wi pé àwọn ni ipin àti yan àwọn òṣèlú.  Eleyi yi o jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ìlú lè mọ àwọn ti ó wà ni ipò òṣèlú olóri àjọ ìgbìmọ̀ kékeré, Gómìnà, aṣojú ni ipinlẹ̀ àti ni ìjọba àpapọ̀.

Gómìnà ipinlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀, Bọ́lá Ahmed Tinubu – ògúná gbòngbò Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwáju,́ ti polongo ètò ki àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bẹ̀rẹ̀ si dìbò yan ẹni ti wọn bá fẹ́ ni ipò.

ENGLISH TRANSLATION

Prior to the modern democratic dispensation, Yoruba ethnic group had their system of governance.  Governance in the olden days did not begin or end with the King and his Chiefs.  Governance begins with the family as everyone has a family head or elder, then each neighbourhood has a leader, farm settlements is led by their leader and markets have their leader too. Continue reading

Share Button

Gó́mìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin fún ìpamọ́ àti ìgbéga èdè Yorùbá – Lagos Governor Akinwunmi Ambode signed into Law Yoruba Language Preservation and Promotion Bill

Ọ̀túnba Gàní Adams ṣe ìwúyè – Chief Gani Adams’ installation as the Aare Ona Kakanfo

Aàrẹ Ọ̀nà Kakanfo, Ọ̀túnba Gàní Adams ti wọn ṣe ìwúyè fún ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, oṣù kini, ọjọ́ kẹtàlá ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún fi ẹ̀dùn ọkàn hàn nipa bi àṣà àti ìṣe Yoruba ti fẹ́ parẹ́.  Nigba ìwúyè, Ọ̀túnba Gàní Adams ṣe àlàyé pé́ ori ire ni wi pé kò si ogun ti ó nja ilẹ̀ Yoruba lọ́wọ́lọ́wọ́, ṣùgbọ́n òhun yio tẹra mọ́ṣẹ́ lati dáàbò àti bójútó àṣà àti ìṣe Yorùbá.

Ìpínlẹ̀ Èkó ti tún ta wọ́n yọ lẹ́ ẹ̀kan si.  Ni Ọjọ́bọ̀, oṣù keji ọjọ́ kẹjọ, ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún, Gómìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin ti yio ṣe ìpamọ́ àti gbé èdè Yorùbá ga.

Gómìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin – Gov Akinwunmi Ambode signed Yoruba Language Preservation and Promotion bill

Akọ̀wé Yorùbá lóri ayélujára yin Gó́mìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé àti àwọn Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó fún iṣẹ́ takuntakun ti wọ́n ṣe lati ṣe òfin fún ìpamọ́ àti ìgbéga èdè Yorùbá.

 

 

 

ENGLISH TRANSLATION

The 15th Aare Ona Kakanfo, Chief Gani Adams who was installed on Saturday, January, 13, 2018 expressed the concern that Yoruba culture and values are going into extinction.  During his installation, he opined that though he was lucky that there is no war ravaging Yoruba nation right now, he will continue to work tirelessly to protect and preserve Yoruba culture and values. Continue reading

Share Button

A ò lè tori a mà jẹran dọ̀bálẹ̀ fún Mãlu – Àgbẹ́kọ̀yà kọ Àṣejù Fúlàní Darandaran – Agbekoya (meaning Farmers reject oppression) condemn the excesses of Fulani Herdsmen

Ìròyìn tó gbòde, ni ọ̀rọ̀ Ìjọba-àpapọ̀ ti ó fẹ ki gbogbo ìpínlẹ̀ ni Nigeria pèsè àyè ni ọ̀fẹ́ fún àwọn darandaran lati tẹ̀dó dípò ki wọn ma kó Mãlu kiri.

Ni ipinlẹ si ìpínlẹ̀, oníkálùkù lò ni iṣẹ́ tàbi òwò tirẹ̀.  Iṣẹ́ àgbẹ̀ ló wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá ni ayé àtijọ.  Bi iṣẹ́ àgbẹ̀ ti ṣe pàtàki fún Yoruba, bẹ ni ise darandaran jẹ́ fún Fúlàní ni òkè-ọya.  Ìyàtọ̀ ti ó wà ni àwọn iṣẹ́ mejeeji ni wi pé, àgbẹ̀ ńṣe oko ni agbègbè rẹ, nigbati darandaran ńda ẹran wọn kakiri lati ìlú kan si ekeji.

Ilẹ̀ pọ̀ ju èrò lọ ni oke- ọya ju odò-ọya lọ. Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “A o ri ibi sùn, ajá ńhanrun”.  Ìjà Sèríà àti Boko Haram ti ṣi ọpọlọpọ ni idi kúrò ni òkè-ọya bọ́ si odò-ọya.    Àyè kò tó fún ogúnlọ́gọ̀ ènìyàn ti ó ngbé ni odò-ọya pàtàki fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ó dari wále nitori ija Bókó Haram àti ogun abẹ́lé yoku ni òkè-ọya.

Fúlàní Darandaran – Fulani Herdsman

Yorùbá fẹran àlejò púpọ̀, darandaran ti nda ẹran wá si ilẹ̀ Yorùbá lai si ìjà, ọ̀na ti jin. Ọba, Ìjòyè àti ọlọ́rọ̀ àyè àtijọ́ ma nni agbo ẹran tàbi Mãlu ti àwọn Fúlàní mba wọn tọ́jú.  Ibùjẹ-ẹran tún wà ni ilẹ̀- Yorùbá ni Àkùnnù-Àkókó. Ni ayé òde òni, kò bójú mu lati da ẹran kiri ni igboro àti ilú nlá.    Di da ẹran kiri ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàmbá ọkọ̀ tó ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ.  Ki ẹran má a jẹ ohun ọ̀gbìn àgbẹ̀ àti ba oko jẹ kò bójú mu.  Èyí ti ó́ burú ju ni darandaran ti ó ngbé ìbọn dání dípò ọ̀pá-ìdaran, ti wọn ti pa olóko tori ki malu lè jẹun.  Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “A ò lè tori a ma jẹ́ran, dọ̀bálẹ̀ fún Mãlu”, eleyi ló jẹ́ ki ẹgbẹ́ Àgbẹ́kọ̀yà kọ ètò ìjọba àpapọ̀ lati pèsè ilẹ̀-ọ̀fẹ́ fún àwọn Fulani ti ó nda ẹran ni ipinle Yorùbá àti lati kọ ìyà lọ́wọ́ daran-daran ti o ngbé ìbọn lati da ẹran.

Ni ilú òyìnbó, àgbẹ àti àwọn ti o ńsin ẹran nri ìrànlọwọ gbà ni ọdọ Ìjọba. Ó yẹ ki ijoba apapo pèsè irinṣẹ́ ìgbàlódé fún àwọn àgbẹ̀ àti ki àwọn ipinlẹ̀ pèsè àyè rẹpẹtẹ fún oko lati gbin oúnjẹ fún àwọn ogúnlọ́gọ̀ èrò ti ó pọ̀si odò-ọya ju ìpèsè ilé ọ̀fẹ́ fún darandaran.   Ìmọ̀ràn fún Ìjọba-àpapọ̀ ni ki wọn lo ilẹ̀ ti ó pọ̀ rẹpẹtẹ ni òkè-ọya pàtàki igbó Sambisa ti àwọn Bókó Haram fi ṣe ibùjòkó tẹ́lẹ̀ ki Ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́ tó lé wọn jade fun agbo malu.

ENGLISH TRANSLATION

The current news in Nigeria is the Federal Government’s directives for the States to voluntarily give land for herdsmen’s colony to stem the current practice of herdsmen moving from place to place for grazing.  Continue reading

Share Button

A kú ọdún tuntun – Happy New Year

Share Button

A kú Ìdùnnú Ìdúpẹ́ – Happy Thanksgiving

Bi Ọlọrun ti ńdárí ẹ̀ṣẹ̀ ji èniyàn
Bi Olóri Òṣèlú Àmẹ́rikà ti ńdáríji tòlótòló
Bẹni ki èniyàn dári ji ẹni ti ó bá ṣẹ́, nitori ki a lè fi ìdùnnú dúpẹ́.

Olóri Òṣèlú Àmẹ́rikà dáríji tòlótòló – American President pardons the Turkey during Thanksgiving

 

 

Share Button

Ikú kò mọ àgbà, ó mú ọmọdé bi Jidé Tinubu – Death is no respecter of age, Jide Tinubu was snatched away by death

Òwe Yorùbá sọ wi pé “bi iná bá kú, á fi eérú bojú, bi ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá kú, á fi ọmọ ẹ rọ́pò”.  Òwe yi fi hàn ipò ti Yorùbá fi ọmọ si.  Kò si ẹni ti kò ni kú, ṣùgbọ́n ọ̀fọ̀ nlá ni ikú ọmọ jẹ́ fún òbí àti àwọn ti olóògbé bá fi silẹ̀ pàtàki àbíkú àgbà.  Ìròyìn ikú Jidé Tinubu àrólé Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinubu kàn pé ó jade láyé ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kini oṣù kọkànlá ọdún Ẹgbàálémẹ́tàdínlógún.

Góm̀nà tẹ́lẹ̀ Bọla Tinubu pẹ̀lú ìyàwó Rẹ̀mí àti ọmọ rẹ olóògbé Jidé nigbà ayẹyẹ ìwé-ẹri Agbejọ́rò – former Gov Tinubu with his wife Remi and late son Jide during his Law School graduation

Ọlọrun ki ó dáwọ́ àbíkú àgbà dúró, ki ó si tu bàbá olóògbé,  Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed, ìyàwó, àwọn ọmọ àti gbogbo ẹbí ninú.  Ki Èdùmàrè dá ikú ọ̀dọ́ dúró, kó tu gbogbo àwọn ti irú ọ̀fọ̀ bẹ́ ẹ̀ bá ṣẹ̀ ninú.

ENGLISH TRANSLATION

According to one of the Yoruba proverbs translated thus “fire is succeeded by ashes, plantain/banana is replaced by its fruits”.  This proverb reflects the hope Yoruba placed on their children. Death is unavoidable by everyone, however, the death of one’s child is often a terrible bereavement for the parents of the deceased particularly the death of an adult child.  On Wednesday, November 1, 2017, the news of the death of Jide Tinubu the first son of the former Governor of Lagos State, Bola Ahmed Tinubu was announced. Continue reading

Share Button