Ohun ti wọ́n bá fi ogún ọdún tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ kọ́, ṣe é bàjẹ́ ni iṣéjú akàn, ṣùgbọ́n lati ṣe àtúnṣe lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún bakan na a. Ó ṣe pataki ki gbogbo ọmọ ilú pinu ni ikan kan lati ṣe àtúnṣe lati bọ́ lọ́wọ́ ìnira ti ó wà ni ilú lọ́wọ́lọ́wọ́.
Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi – Change Begins with Me. Courtesy: @theyorubablog
Àyípadà tàbi Àtúnṣe yẹ ki ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òṣiṣẹ́ Ìjọba, àwọn ti ó nta ọjà, ọ̀gá ilé-iwé àti àwọn ọmọ ilé-iwé, àwọn òṣiṣẹ́ ilé-ìwòsàn, ọmọdé àti àgbà ilú. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà àti àwọn iwà ibàjẹ́ ti ó ti gbilẹ̀ fún ọdún pi pẹ́ ti ba nkan jẹ ni orilẹ̀ èdè Nigeria. Di ẹ ninú àwọn iwà burúkú wọnyi ni ki òṣiṣẹ́ ìjọba ji ẹrù àti owó Ìjọba fún ara wọn tàbi sọ ara wọn di alágbàtà ti o nsọ ọjà di ọ̀wọ́n nipa gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ. Eleyi lo njẹ ki àwọn iṣẹ́ ti ìjọba bá gbé sita lati tú ọ̀nà ṣe, lati pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, omi àti ohun amáyédẹrùn miran wọn ju ti gbogbo àgbáyé lọ. Nitori òṣiṣẹ́ Ìjọba ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ti ó gba iṣẹ́ lè ma ṣe iṣẹ́ tàbi ki wọn ṣe iṣẹ́ ti kò dára. Ẹni ti ó nta ọjà á sọ̀rọ̀ si onibárà pẹ̀lú ẹ̀gàn, ojúkòkòrò, ìfẹ́ owó ki kó jọ ni ọ̀nà ẹ̀rú àti à ṣe hàn ló nfa iwà ibàjẹ́ àti olè jijà laarin àwọn Òṣèlú, olóri ẹ̀sìn, òṣiṣẹ́ Ìjọba, ọlọ́jà ti ó nkó ọjà pamọ́ lati fa ọ̀wọ́n, Olùkọ́ ilé iwé, ọmọ ilé-iwé kò ni itẹriba fún Olùko mọ́, àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.
Ki àyipadà rere lè dé bá ilú, ó yẹ ki onikálukú yẹ ara rẹ̀ wò fún àtúnṣe kúrò ninú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà, iwà ibàjẹ́, ai ṣojú ṣe ẹni ninú ẹbi, ai bẹ̀rù àgbà, ji ja ilú lólè, ki kó owó ilú lọ si òkèèrè, ki kọ oúnjẹ ilú ẹni silẹ̀ fún oúnjẹ òkèèrè, ayẹyẹ àṣejù, ni ná owó ti èniyàn kò gbà àti ai ni ìtẹ́lọ́rùn.
Ìpolongo tó nlọ lọ́wọ́ ni orilẹ́ èdè Nigeria ni pé “Àyípadà tàbi Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi”. Yorúbà sọ wi pé “Igi kan ki da a ṣe igbó”, eyi túmọ̀ si wi pé ki i ṣe Olóri Ìjọba Òṣèlú àti àwọn Òṣèlú yoku nikan ni ó yẹ ki ó ṣe àtúnṣe ohun ti ó ti bàjẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣùgbọ́n gbogbo ọwọ́ ló yẹ ki ó ṣe àtúnṣe lati gbógun ti iwà ibàjẹ́.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading →
Originally posted 2016-09-23 14:32:38. Republished by Blog Post Promoter