Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Awọ kò ká Ojú ìlù, Ọmọ Onílù ni òhun fẹ́ má a sun Awọ jẹ – Ojúkòkòrò àwọn Òṣèlú Nigeria”: “Not enough Leather for drum making, the drummer boy is craving for leather meat delicacy: Greedy Nigerian Politicians”

Nigbati àwọn Òṣèlú gba Ìjọba ni igbà keji lọ́wọ́ Ìjọba Ológun, inú ará ilú dùn nitori wọn rò wi pé Ológun kò kọ iṣẹ́ Òṣèlú.  Ilú rò wi pé Ìjọba Alágbádá yio ni àánú ilú ju Ìjọba Ológun lọ.  Ó ṣe ni laanu pé fún ọdún mẹ́rìndínlógún ti Òṣèlú ti gba Ìjọba, wọn kò fi hàn pé wọn ni àánú ará ilú rárá.  Dipò ki wọn ronú bi nkan yio ti rọrùn fún ilú nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn bi iná mọ̀nàmọ́ná, ilé-iwé, ilé-ìwòsàn, ojú ọ̀nà ti ó dára, òfin lati jẹ ki ilú tòrò, ṣe ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ji owó ilú.  Bi ori bá fọ́ Òṣèlú, wọn á lọ si Òkè-Òkun nibiti wọn kó owó ti ó yẹ ki wọn fi tú ilé-ìwòsàn ṣe si.  Àwọn Òṣèlú Òkè-Òkun nfi owó Nigeria tọ́jú ará ilú wọn nitori eyi, gbogbo ọ̀dọ́ Nigeria ti kò ni iṣẹ́ fẹ́ lọ si Òkè-Òkun ni ọ̀nà kọnà.

Ọmọ Onilù - The Drummer. Courtesy: theyorubablog

Ọmọ Onilù – The Drummer. Courtesy: theyorubablog

Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Awọ kò ká Ojú ìlù, Ọmọ Onilù ni òhún fẹ́ má a sun Awọ jẹ” bá ìròyìn ti ó jáde ni lọ́wọ́-lọ́wọ́, bi àwọn Òṣèlú ti bá owó ọrọ̀ ajé Nigeria jẹ nipa bi wọn ti ṣe pin owó ohun ijà fún Ológun lati ra ibò.  ‘Epo Rọ̀bì’ ni ‘Awọ’ nitori ó lé ni idá ọgọrin ti owó epo rọ̀bì kó ni owó ọrọ̀ ajé ti ilú tà si Òkè-Òkun.  Fún bi ọdún mẹ̃dógún ninú ọdún merindinlogun ti Èrò Ẹgbẹ́ Òṣèlú (ti Alágboòrùn) fi ṣe Ìjọba ki ó tó bọ lọ́wọ́ wọn ni ọdún tó kọjá, owó epo rọ̀bì lọ si òkè rẹpẹtẹ, ọrọ̀ ajé yoku pa owó wọlé.  Dipò ki wọn lo owó ti ó wọlé lati tú ilú ṣe, wọn bẹ̀rẹ̀ si pin owó lati fi ra owó Òkè-Òkun lati kó jade lọ ra ilé nlá si àwọn ilú wọnyi lati sá fún ilú ti wọn bàjẹ́ ni gbogbo ọ̀nà.

Owó epo rọ̀bì fọ́, awọ kò wá ká ojú ilú mọ́.  Oníṣẹ́ Ìjoba kò ri owó-oṣ̀ù gbà déédé, àwọn ti ó fi ẹhin ti ni iṣẹ́ Ìjọba kò ri owó ifẹhinti wọn gba, owó ilú bàjẹ́, bẹni àwọn Òṣèlú bú owó oṣ́u rẹpẹtẹ fún ara wọn.  Eyi ti ó burú jù ni owó rẹpẹtẹ miran ti wọn bù lati ra ọkọ ti ìbọn ò lè wọ, olówó nla lati Òkè-Òkun fún Ọgọrun-le-mẹsan Aṣòfin-Àgbà.   Olóri Aṣòfin-Àgbà fẹ ra ọkọ̀ mẹsan fún ara rẹ nikan.

Àsìkò tó ki àwọn èrò ji lati bá àwọn olè wọnyi wi, nitori àwọn Òṣèlú Òkè-Òkun nibiti wọn nkó owó ilú lọ, kò fi owó ilú wọn tọ́jú ara wọn, wọn nwọ ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ilú, àyè kò si fún wọn lati ja ilú ni olè bi ti àwọn Òṣèlú Nigeria.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-02-19 10:12:16. Republished by Blog Post Promoter

“Ilú-Oyinbo dára, ọ̀rẹ́ mi òtútù pọ̀” – “Europe is beautiful, but my friend it is too cold.

Thumbnail

Emperor Dele Ojo & His Star Brothers Band – Ilu Oyinbo Dara

Gẹgẹbi, àgbà ninu olórin Yorùbá “Délé Òjó” ti kọ ni ọpọlọpọ ọdún sẹhin pe “Ilú Oyinbo dára, ọrẹ mi òtútù pọ̀, à ti gbọmọ lọwọ èkùrọ́ o ki ma i ṣojú bọ̀rọ̀”.  Àsikò òtútù ni àlejò ma ńṣe iranti ilé.  Òtútù ò dára fún arúgbó, a fi ti onilé nã bá lówó lati san owó iná ti o gun òkè nitori àti tan ẹ̀rọ-amúlé gbónọ́.

 

Yinyin – Snow. Courtesy: @theyorubablog

Ìmọ̀ràn fún àwọn ti ó gbé ìyá wọn wá si ìlú-oyinbo, ni ki wọn gbiyànjú lati ṣe ètò fún àwọn ìyá-àgbà lati lọ si ilé ni asiko òtútù lati fara mọ́ àwọn enia wọn. Òtútù o dára fún eegun àgbà.

ENGLISH TRANSLATION

According to an elder Yoruba musician’s “Dele Ojo” song many years ago, “Europe is very beautiful but my friend it is too cold, cracking palm kernel is no mean task”.  Visitors or migrants often remember home during winter.  Cold is not good for the elderly, except if the home owner can afford the high bill spent in heating the home at this period. Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-01-22 06:43:52. Republished by Blog Post Promoter

Ìṣe Ilé ló mbá ni dode – Trudy Alli-Balogun ja Ilé-Iṣẹ́ rẹ lólè – The character cultivated at home often reflect in the public – Trudy Alli-Balogun a Council Officer jailed for £2.4 million housing fraud

Ìbá ṣe pọ̀ laarin Yorùbá àti Ìlú-Ọba ti lé ni igba ọdún nitori òwò Òkè-òkun, pàtàki òwò ẹrú àti fún ẹ̀kọ́ ni ilé iwé giga.  Nitori eyi, àṣà àti èdè Yorùbá kò ṣe fi ọwọ́ rọ sẹhin.

fraud.jpg

Trudy Alli-Balogun jailed for 5 years over £2.4 million housing fraud

Ni Ilú-Ọba, ẹ̀tọ́ ará ilú ni ki Ìjọba pèsè ohun amáyédẹrùn, pàtàki ibùgbé fún ọmọ ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún ọmọ àti ará ilú.  Àwọn ẹ̀tọ́ wọnyi kò tọ́ si àlejò, ẹni ti ó fi èrú wọ ilú ti kò ni àṣẹ igbelu, tàbi ẹni tó ni iwé lati ṣe iṣẹ ṣùgbọ́n ko ti i di ará ilú.  Ẹni ti ó ni iwé-igbelu lati ṣe iṣẹ́ ti ko ti di ará ilú kò ni ẹ̀tọ́ si ilé Ìjọba, ṣùgbọ́n wọn ni ẹ̀tọ́ si ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́. Iwé ìròyìn irọlẹ, gbe jade bi Trudy Alli-Balogun, ti lo ipò rẹ ni ilé iṣẹ́ ti ó nṣe ipèsè ibùgbé fún ọmọ ilú, lati gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Yorùbá ti kò ni ẹ̀tọ́ si irú ilé bẹ́ ẹ̀.  Wọn ṣe ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún marun fún.

Ìròyìn ti ó gbòde ni inu iwé ìròyìn  àti lori ayélujára fi han bi àwọn Olóri Òṣèlú, Aṣòfin àgbà nla àti kékeré, òṣiṣẹ́ Ìjọba àgbà àti àwọn ti ó wà ni ipó giga ni Nigeria ti lo ipò wọn lati fi ja ilu lólè.  Àyipadà ni Ìjọba pẹ̀lú pe Olóri Òṣèlú Muhammadu Buhari/Yẹmi Osinbajo ti ó gbógun ti iwà ibàjẹ́, ló jẹ ki àṣiri iṣẹ́ ibi wọnyi jade si ará ilú bi àwọn ti ó  wà ni ipò giga ti nlo ipò lati fi hu iwà ibàjẹ́ nitori àti kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà ẹ̀bùrú.

Yorùbá sọ wi pé “Ìṣe ilé ló mbá ni dode”.  Ni àtijọ́, àṣà Yorùbá ni lati wá idi bi enia ti kó ọrọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ni ayé òde oni, olówó ni wọ́n mbọ, bi ó bá ti ẹ jalè tàbi ti ẹ̀wọ̀n de nitori iṣẹ́ ibi.  Àyipadà burúkú yi ni obìnirin Trudy Alli-Balogun gbé dé ẹnu iṣẹ́ lati ja ilé iṣẹ́ rẹ ni olè ọ̀kẹ́ aimoye, ti ó si na owó bẹ́ ẹ̀ ni ìná àpà lai ronú orúkọ burúkú ti ó rà fún Yorùbá àti gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria ni Ilú-Ọba àti pé irú iwà ibàjẹ́ yi ló ba ohun amáyédẹrùn jẹ ni Nigeria.  Iwà ibàjẹ́ kò ni orúkọ meji, ẹni ba jalè ba ọmọ jẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-05-06 23:39:56. Republished by Blog Post Promoter

“Ìṣòro ti Agbalésanwó n ri ni Ilú Nlá lati ri Ibùgbé”– “Prospective Tenants’ troubles of finding Accommodation in the Big Cities”

Abúlé – A Village.  Courtesy: @theyorubablog

Abúlé – A Village. Courtesy: @theyorubablog

Ni ayé àtijọ́, kò si ohun ti ó njẹ́ Agbalésanwó nitori kò si ẹni ti kò ni ẹbi ti wọn lè bá gbé ni ọ̀fẹ́.  Kò wọ́pọ̀ ki èniyàn kúrò ni ilé lati lọ gbé ilú miran.  Iṣẹ́ meji ti ó wọ́pò ni ayé àtijọ́ ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò nipa ti ta irè oko ni ọjọ́ Ọjà Oko lati Abúlé kan si ekeji.  Kò si ohun irinna bi ayé òde òni, nitorina ẹsẹ̀ ni wọn fi nlọ lati ilú kan si ekeji.  Yorùbá fẹ́ràn àlejò, nitori eyi, bi Oniṣòwò bá lọ si Ọjà Oko ni ilú miran, ti kò lè délé ni ọjọ́ ti ó gbéra, yio ri ilé sùn ni abúlé ti ó bá dé ti ilẹ̀ fi ṣú lai sanwó.  Olóko ni o ma npèsè ibùgbé fún Alágbàṣe ti wọn bá gbà fún iṣẹ́ oko, nitori eyi, kò si pé àlejò gba ilé lati sanwó.

Ìsọ̀ Ọjà oko – Village Market Stall

Ìsọ̀ Ọjà oko – Village Market Stall. Courtesy: @theyorubablog

Ni igbà ti ó yá, èrò bẹ̀rẹ̀ si kúrò lati ilú kan si ekeji, pàtàki nitori ọ̀gbẹlẹ̀, iyàn, ogun tàbi ẹni ti wọn lé kúrò ni ilú nitori iwà burúkú.  Eleyi fã ki ilú kan fẹ̀ ju òmíràn lọ, pàtàki ni ilú ti ó bá sún mọ́ odò nla bi ti ilù Èkó nitori iṣẹ́ ma npọ̀.

Ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ má a nkúrò ni ilé lati wá iṣẹ́ lọ si ilú miran.  Ó rọrùn fún ẹni ti ó kàwé àti oníṣẹ́ ọwọ́ lati ri iṣẹ́ nitori oriṣiriṣi iṣẹ́ pọ ni ilú nlá, ju ilú kékeré lọ.  Eleyi jẹ́ ki ilú nlá bẹ̀rẹ̀ si fẹ si. Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá “Ọ̀kọ́lé kò lè mu ràjò”, bẹni kò si bi ẹni ti ó kúrò ni ilé ti lè gbé ilé dáni lọ si ilú nlá. Àlejò bẹ̀rẹ̀ si pọ̀ si ni ilú nlá ṣùgbọ́n ilé gbigbé kò kári.

Àṣà ti ó wọ́pọ̀ ni ki Onilé gba owó ọdún kan tàbi meji.  Elòmìràn ngba ọdún mẹta fún owó à san silẹ̀.  Ilé wá di ohun à mu ṣowó.  Oriṣiriṣi àwọn oniṣẹ́ “Abániwálé” wá pọ̀ si.  ọ̀pọ̀ Onilé àti Abániwále bẹ̀rẹ̀ si lu jìbìtì nipa gbi gba owó lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Agbalésanwó lóri ilé kan ṣoṣo, òmíràn ngba owó lóri ilé ti ki ṣe ti wọn. Yorùbá ni “Alágbàtà tó nsọ ọjà di ọ̀wọn”, bi ilé bá ti wọn tó ni owó ti Abániwále má a ri gbà ti pọ̀ tó.  Eyi jẹ́ ki wọn sọ ilé di ọ̀wọ́n, nitori owó ti wọn má a ri gbà lọ́wọ́ Onilé àti Agbalésanwó lai ro inira Agbalésanwó.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-09-04 07:30:37. Republished by Blog Post Promoter

Bẹni, Bẹ́ẹ̀kọ́ Ìbò Ọ̀rọ̀ Ìlú ni Ìlú-Ọba: Ẹ̀kọ́ fún Orilẹ̀-èdè Nigeria – ‘Yes or No’ The United Kingdom Referendum: Lessons for the Nigerian Nation

Ì̀bò Ọ̀rọ̀ Ìlu ni Ìlú-Ọba' UK Referendum

Ì̀bò Ọ̀rọ̀ Ìlu ni Ìlú-Ọba’ UK Referendum

Ni Ìlú-Ọba, lẹhin ọdún mẹtalelogoji, èrò jade lati di ìbò bẹni-bẹ́ẹ̀kọ́ lori àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Ìlú-Oyinbo méjidinlọ́gbọ̀n ni Ọjọ́bọ̀, oṣu Kẹfa, ọdún Egbàálémẹẹdógún.   Idibò na a lọ wẹ́rẹ́ lai si ìjà, kò gbà ju ìṣéjú kan si meji lọ lati wọlé dibò ti ó  bẹ̀rẹ̀ ni agogo meje àárọ̀ titi di aago mẹwa alẹ́.  Lẹhin idibò, ni òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ keji idibò, ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kẹrinlélógún, oṣù kẹfa, èsi ibò jade pé ibò bẹ́ẹ̀kọ́ ju ibò bẹni lọ, eyi ti ó túmọ̀ si wi pé, ará ilú ti ó fẹ́ ki wọn ‘kúrò’ ni ẹgbẹ́ Ilú-Oyinbo pọ̀ ju àwọn ti wọn ó fẹ́ ki wọn ‘dúró‘ ninú ẹgbẹ́.

Bi èsì ibò ti jade, Olóri Òṣèlú Ilú-Ọba, David Cameron, jade lati bá ará ilú sọ̀rọ̀.  Ninú ọ̀rọ̀ rẹ, ó ni nitori ohun polongo ki wọn dúró ninú ẹgbẹ́ Ilú-Oyinbo ṣùgbọ́n àwọn aráilú ti sọ̀rọ̀ wi pé ki wọn kúrò, nitori eyi ohun yio gbé Ijọba silẹ̀.

Ẹ̀kọ́ fún Ìjọba tiwa ntiwa ni orilẹ̀ èdè Nigeria ni wi pé iwá ibàjẹ́ ti àwọn Òṣèlú nhu ni Àbùjá lai fi eti si ará ilú pé àwọn ẹ̀yà mẹ́yà orilẹ̀ èdè Nigeria fẹ́ dá Ìjọba wọn ṣe ju ki Òṣèlú joko si Àbùjá lati maa na owó gbogbo ará ilú.  Ó yẹ ki wọn ronú bi wọn yio ti ṣe Ìjọba ti yio mu irọ̀rùn ba gbogbo ipinlẹ Nigeria.  Ki wọn fi eti si ohun ti ará ilú lati Guusu dé Àriwá sọ, pé ki wọn joko sọ̀rọ̀ bi wọn yio ti ma bára gbé.  Igbe àwọn Igbo ti pọ si lẹhin ti wọn jagun abẹ́lé, àwọn ẹya miran bi Yorùbá nkun ni abẹ́lẹ̀ pé àwọn ma fẹ dá dúró ki wọn san iṣákọ́lẹ̀ fún Ìjọba àpapọ̀.

Ó yẹ ki Òṣèlú Nigeria ṣe àyẹ̀wò òfin ti aṣojú Ilú Ọba – Lugard fi da Guusu àti Àríwá pọ fún irọ̀rùn ìṣàkóso orilẹ̀ èdè Nigeria ni ọgọrunlemeji ọdún sẹhin.  Nigeria gba Òmìnira ni bi ọdún mẹrindinlọgọta sẹhin.  Lẹhin Òmìnira, àwọn Òṣèlú pàtàki ni Ìwọ̀-oòrùn lábẹ́ Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ fi ipò Òṣèlú ṣe iṣẹ́ ribiribi lati jẹ́ ki àwọn ará ilú jẹ èrè Òmìnira, ṣùgbọ́n lati igbà ti Ìjọba Ológun ti ó fi ibọn gba Ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ si ṣe Òṣèlú ni ilú ti bàjẹ́ si, wọn si rò wi pé àwọn lé fi ipá kó orilẹ̀ èdè pọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-06-24 13:52:05. Republished by Blog Post Promoter

Ewu ifi Ilé-àpèjẹ dipò Ilé-ìkàwé, MTN fẹ́ gbé Ilé-ìkàwé kúrò ni Ilé-iwé Giga ti Àkokà – The danger of replacing the Library with Event Place, as Donor MTN announced intent to relocate Digital Library from UNILAG

 Ilé-ìkàwé MTN - MTN to withdraw multi-million digital library donated to UNILAG

Ilé-ìkàwé MTN – MTN to withdraw multi-million digital library donated to UNILAG

Ilé-ìkàwé gẹ́gẹ́ bi orúkọ yi ti jẹ ni èdè Yorùbá, jẹ ibi ti wọn kó oriṣiriṣi iwé si, fún ọmọ ilé-iwé àti èrò lati wọlé yá iwé fún ki kà.  Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú ni Ilé-ìkàwé ti bẹ̀rẹ̀ ni Alexandria, Egypt.  Ni ayé òde òni, ki ṣe iwé nikan ni wọn nkó si Ilé-ìkàwé, wọn a tún pèsè ẹ̀rọ ayélujára fún ẹni ti ó bá fẹ́ ka iwé lóri ayélujára àti lati wá idi ohun ti ó nlọ ni àgbáyé.

Ilé́-iwé kò pé lai si Ilé-ìkàwé.  Ki ṣe ilé-iwé nikan ló ni Ilé-ìkàwé, nitori àdúgbò, agbègbè àti ilú na a ma nni Ilé-ìkàwé fún ọmọ ilé-iwé àti èrò ti ó ni ìfẹ́ lati ni ìmọ̀.  Lati igbà ti Ìjọba-àpapọ̀ ti gba gbogbo ilé-iwé lọ́wọ́ àwọn Olùdásílẹ̀, ni ilé-iwé ti bàjẹ́ pàtàki àwọn ilé-iwé ti Ìjọba gba.

Yorùbá fẹ́ràn ẹni ti ó bá kàwé, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ìfẹ́ owó àti ìgbádùn ti dipò ìfẹ́ ẹ̀kọ́, nitori eyi Ilé-àpèjẹ pọ ni ilú ju Ilé-ìkàwé lọ.  Eyi ti ó burú jù ni pé, kò si Ilé-ìkàwé tuntun, eyi ti ó wà kò ri àtúnṣe.  Ìròyìn gbe jade pé, Ilé-iṣẹ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ti ṣe tán lati gbé Ilé-ìkàwé ti wọn kọ́ ni ọdún mẹwa sẹhin fún lilò ni ilé-iwé giga ti ó wà ni Àkokà, ilú Èkó, kúrò nitori wọn ti i pa lati ọdún marun lai lò.  Eleyi yẹ kó ti ará ilú àti Òṣèlú lójú nitori, Ilé-ìkàwé ti wọn ti kọ́ ni ọgọrun ọdún sẹhin tàbi jù bẹ ẹ lọ ṣi wà ni Òkè-Òkun.

Ilú kò lè ni ìlọsíwájú lai si ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ nitori “Ìgbádùn tàbi Eré ṣi ṣe lai ṣi iṣẹ́, ló nfa Ìṣẹ́”.

ENGLISH TRANSLATION

Library as the name literarily suggested in Yoruba, is place where various kinds of books are kept, for Students and the public, where they can borrow books to read.  The oldest Library started in Alexandria, Egypt in 300 BC.  Nowadays, not only books are kept in the Library, Computers with internet are provided for those who want to read or carry out research on happenings around the world. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-06-05 10:00:23. Republished by Blog Post Promoter

Kí iṣu tó di iyán a gún iṣu lódó: “Before Yam becomes Pounded Yam it is pounded in a mortar”

Gẹ́gẹ́bí Ọba nínú Olórin ti ógbé àṣà àti orin Yorùbá lárugẹ lagbaaye (Ọba orin Sunny Ade) ti kọ wípé: “Kí iṣu tó di iyán a gún iṣu lódó”, òdodo ọ̀rọ̀ ni wípé a ni lati gún iṣu lódó kí ó tó di Iyán, ṣùgbọ́n fún ìrọ̀rùn àwọn tí ó ní ìfẹ́ oúnje abínibí tí ó wà ni Ìlúọba/Òkèòkun, a ò gún iṣu lódó mọ, a ro lórí iná bí ìgbà ti a ro Èlùbọ́ to di Àmàlà ni.

Ìyàtọ̀ tó wà laarin Èlùbọ́ tó di Àmàlà àti iṣu tó di Iyán tí a rò nínú ìkòkò ni wípé, Àmàlà dúdú, Iyán funfun, ṣùgbọ́n Àmàlà fẹ́lẹ́ ju Iyán lọ.  A ní lati ṣe àlàyé fún àjòjì wípeí ara iṣu ni Èlùbọ́ tó di Àmàlà ti jáde gẹ́gẹ́bi Iyán ti jáde lára Iṣu. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-17 09:20:09. Republished by Blog Post Promoter

ÈLÒ ỌBẸ̀ YORÙBÁ: YORUBA SAUCE/STEW/SOUP INGREDIENT

Yorùbá English Yorùbá English
Èlò bẹ̀ Soup/Stew/Stew Ingredients Elo Obe Soup/Stew/Stew Ingredients
Ẹja Fish Ẹyẹlé Pigeon
Ẹja Gbígbẹ Dry Fish Epo pupa Palm Oil
Akàn Crab Òróró Vegetable Oil
Edé pupa Prawns Òróró ẹ̀̀gúsí Melon oil
Edé funfun Crayfish Òróró ẹ̀pà Groundnut Oil
Ẹran Meat Àlùbọ́sà Onion
Ògúfe Ram Meat Iyọ̀ Salt
Ẹran Ẹlẹ́dẹ̀ Pork Meat Irú Locost Beans
Ẹran Mal̃ũ Cow Meat/Beef Àjó Tumeric
Ẹran ìgbẹ́ Bush Meat Ata ilẹ̀ Ginger
Ẹran Ewúrẹ́ Goat Meat Ilá Okra
Ẹran gbígbẹ Dry Meat Efirin Mint leaf
Ṣàkì Tripe Ẹ̀fọ́ Vegetable
Ẹ̀dọ̀ Liver Ẹ̀fọ́ Ewúro Bitterleaf
Pọ̀nmọ́ Cow Skin Ẹ̀fọ́ Tẹ̀tẹ̀ Green
Panla Stockfish Gbúre Spinach
Bọ̀kọ́tọ̀/Ẹsẹ̀ Ẹran Cow leg Ẹ̀gúsí Melon
Ìgbín Snail Atarodo Habanero pepper
Adìyẹ Chicken Tàtàṣé Paprika
Ẹyin Egg Tìmátì Tomatoes
Pẹ́pẹ́yẹ Duck Ewédú Corchorus/Crain Crain
Tòlótòló Turkey Àpọ̀n Dried wild mango seed powder
Awó Guinea-Fowl Osun Mushroom
Share Button

Originally posted 2013-05-01 03:06:44. Republished by Blog Post Promoter

“Ibi ti à ńgbé là ńṣe…” – Ìfi ìdí kalẹ̀ ni Ìlú-Ọba – One should live according to the custom and fashion of the place where one find oneself in…” – Settling down in the United Kingdom

 Ẹ̀kọ́ púpọ̀ ni enia lè ri kọ́ ni irin àjò.  A lè rin irin àjò fún ìgbà díẹ̀ tàbi pípẹ́ lati bẹ ilú nã wò tàbi lati lọ tẹ̀dó si àjò.

wọ ọkọ̀ òfũrufu – Boarding Aeroplane. Courtesy: @theyorubablog

Oriṣiriṣi ọ̀nà ni enia lè gbà dé àjò, ṣùgbọ́n eyi ti ó wọ́pò jù láyé òde òni ni lati wọ ọkọ̀ òfũrufú, bóyá lati lọ kọ́ ẹ̀kọ si, lati ṣe ìbẹ̀wò, lati lọ ṣiṣẹ́ tàbi lati lọ bá ẹbi gbé (fún àpẹrẹ: ìyàwó lọ bá ọkọ, ọkọ lọ bá ìyàwó, ìyá/bàbá lọ bá ọmọ tàbi ọmọ lọ bá bàbá). Gbogbo ọ̀nà yi ni Yorùbá ti lọ lati dé Ìlú-Ọba.

Àṣepọ̀ laarin ará Ìlú-Ọba àti Yorùbá ti lè ni ọgọrun ọdún, nitori eyi, kò si ibi ti enia dé ni Ìlú-Ọba ni pataki àwọn Olú-Ìlú, ti kò ri ẹni ti ó ńsọ èdè Yorùbá tàbi gbé irú ilú bẹ.  A ṣe akiyesi pé lati bi ọdún mẹwa sẹhin, àṣepọ̀ laarin ọmọ Yorùbá ni Ìlú-Ọba din kù.  Ni ìgbà kan ri, bi ọmọ Yorùbá bá ri ara, wọn a ki ara wọn.

Òwe Yorùbá ni “Ibi ti a ngbe la nse; bi a bá dé ìlú adẹ́tẹ̀ a di ìkúùkù”, àwọn ọ̀nà ti a lè fi ṣe ibi ti a ngbe: Ki ka ìwé nipa àṣà àti iṣẹ ìlú ti a nlọ ninu ìwé tàbi ṣe iwadi lori ayélujára; wiwa ibùgbé; lọ si Ilé-Ìjọ́sìn; Ọjà; Ọkọ̀ wiwọ̀ àti bẹ̃bẹ lọ.

Ẹ fi ojú sọ́nà fún àlàyé lori àwọn ọ̀nà ti enia lè lò lati tètè fi idi kalẹ̀ ni àjò.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-03 23:45:42. Republished by Blog Post Promoter

Aṣọ nla, Kọ́ lènìyàn nla – Wèrè ti wọ Àṣà Aṣọ Ẹbí: The hood does not make the Monk – the madness of Family Uniform

Àṣà ilẹ̀ Yorùbá títí di àsìkò yi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ma nni iyawo pupọ́ wọn si ma mbi ọmọ púpọ̀, wíwọ irú aṣọ kan naa fun ṣíṣe ma nfi ẹbi han.  Aṣọ ẹbí bẹ̀rẹ̀ nípa ki ọkọ àti ìyàwó dá irú aṣọ kan nigba ìgbéyàwó àti wíwọ irú aṣọ kan naa lẹhin ìgbéyàwó lati fi han wípé wọn ti di ara kan.   Bàbá ma nra aṣọ  irú kan naa fun àwọn ọmọ nítorí ó dín ìnáwó kù láti ra irú aṣọ kan naa fún ọmọ púpọ̀ nípa ríra ìgàn aṣọ ju ríra ni ọ̀pá.   Aṣọ ẹbí tún wa fún ẹbí àti ọmọ oloku, ìyàwó ṣíṣe, ẹgbẹ́ ìlú àti bẹ̃bẹ lọ.

Nígbàtí wèrè ko ti wọ àṣà aṣọ ẹbí, ẹnití o ṣe ìyàwó, ṣe òkú, sọ ọmọ lórúkọ àti ṣiṣe yoku ma npe aṣọ ni.  Kò kan dandan ki ènìá ra aṣọ tuntun fún gbogbo ṣíṣe, fún àpẹrẹ, aṣọ funfun ni wọn ma sọ wípé ki àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọ̀ fún òkú ṣíṣe, aṣọ ibilẹ̀ bi aṣọ òfi àti àdìrẹ fún ìgbéyàwó. Ẹbí ìyàwó le sọ wípé ki ẹgbẹ́ wọ aṣọ aláwọ ewé lati ba ohun yọ ayọ ìgbéyàwó, ki ẹbí ọkọ ni ki àwọn ẹgbẹ́ wọ àdìrẹ ti wọn  ti ra tẹ́lẹ̀ fún ìgbéyàwó.

Lati bi ogoji ọdun sẹhin, lẹhin ti ìlú ti bẹ̀rẹ̀ si naa owó epo, àṣejù ti wọ àṣà aṣọ ẹbí rírà.  Àṣà aṣọ ẹbí ti káári ìlú kọjá ile Yorùbá si gbogbo Nigeria.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ a ma jẹ gbèsè nítorí àti ra aṣọ ẹbí, pàtàkì ni Ìlúọba ti àwọn miran ti nṣiṣẹ àṣekú lati kó irú owó bẹẹ si aṣọ ẹbí, àwọn miran á kó owó oúnjẹ àti owó ilé ìwé lórí aṣọ ẹbí.

Ìlú nbajẹ si, kò síná, kò sómi, ìṣẹ́ pọ, aṣọ ẹbí ko le mu ìṣẹ́ kúrò tàbi sọ ẹnití o jẹ gbèsè láti ra aṣọ ẹbí di ènìyàn nla nítorí “Aṣọ nla, kọ lènìyàn nla – Yorùbá ni ilé lóko, ẹ dín wèrè aṣọ ẹbí kù.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba culture up till now, many men are engaged in “Polygamy” with children from many women, so to buy the same clothes is cheaper for the many wives and children for various festivities.  Family uniform are also used during Burial, Wedding, Naming and other ceremonial events.

When family uniform madness has not started, those preparing for burial, marriage and other traditional events normally call “colour code” of dressing or for invitees to wear one of the previous Family Uniforms, rather than buy new clothes for every event. Those days, those preparing for burial would ask families and friends to wear white attire, while the bride’s family could ask friends to wear green while the groom’s family would request for other locally produced fabrics.  Things were moderately done.

It is observed that since the oil boom about forty years ago, there has been a lot of excesses in the so called “Family Uniform” and this culture has spread beyond the Yoruba to other parts of Nigeria. The Nigerian’s abroad are also not excluded in spite of working to death with no time for family lives only to spend such income that could have been spent on education, food and other necessities on such frivolities as “Family Uniform”.

In the midst of decaying infrastructure and poverty, spending so much on “Family Uniform” would not make our nation great.  “The hood does not make the Monk, Yoruba at home and abroad should reduce the madness on “Family Uniform”.

Share Button

Originally posted 2013-05-31 22:53:11. Republished by Blog Post Promoter