Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Èkó – Aginjù laarin àwọn Olú Ilú Àgbáyé”: “Lagos – A Jungle among the World Big Cities”

Èkó ni olú ilú Nigeria fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ki àwọn Ijọba Ológun tó kó Olú Ilú Nigeria lọ si Abuja ni bi ọdún mẹrinlélógún sẹhin.  Ki kó olú ilú kúrò ni Èkó kò din èrò ti o nwọ Èkó kù, ilú Èkó ngbòrò si ni, ṣùgbọn bi èrò ti npọ si, Ijọba àpapọ̀ kò ran Eko lọwọ nipa ipèsè owó tó tó ni àsikò fún ohun amáyédẹrùn.

Sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀ - Heavy Lagos traffic. Courtesy: @theyorubablog

Sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀ – Heavy Lagos traffic. Courtesy: @theyorubablog

Ká fi Èkó wé àwọn olú ilú yoku ni àgbáyé àti àwọn ilú nla ti omi yi ká, inira Èkó pọ̀ ju àwọn ilú wọnyi lọ.  Kò si iná mọ̀nàmọ́ná ti ó ṣe deede, kò si omi mimu fún ará ilú pàtàki fún àwọn agbègbè titun.  Eyi ti ó burú jù ni ki èniyàn jade, kó má mọ igbà ti ó ma padà wọlé nipa li lo bi wákàti mẹ́fà tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ ninú sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀, nitori ọ̀nà kò tó, bẹni kò dára, iwà-kuwà pọ̀ fún awakọ̀, ọkọ̀ àti èrò pọ̀ ju òpópó ọ̀nà lọ.

Bi Ijọba àpapọ̀ Nigeria ti ri owó ori gbà ni Èkó ju gbogbo àwọn ilú yoku lọ tó, kò si irànlọ́wọ́ lati tú ọ̀nà Ijọba àpapọ̀ ṣe.  Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Ijọba Ológun di Èkó lọ́wọ́ lati pèsè ọkọ̀ ojú irin ti ó ngbé èrò púpọ̀ ti Gómìnà Lateef Jakande bẹ̀rẹ̀.  Bi Èkó ti tóbi tó, ibùdókọ òfúrufú kan ló wà lójú kan naa ni Ìkẹjà fún àwọn ti ó nlọ si gbogbo àgbáyé àti àwọn ti ó fẹ́ lọ si ilú Nigeria miran.  Lati igbà ti Ijọba Ológun ti lé àwọn àjòjì ti ó dá ilé ọjà nla silẹ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn Olówó ilú kò ronú lati ṣe irú ilé ọjà bẹ́ ẹ̀ si gbogbo agbègbè Èkó fún irọ̀rùn ará ilú ju bi gbogbo ọjà nla ti kó ori jọ si Erékùṣù Èkó.  Àwọn nkan wọnyi àti iwà ibàjẹ́ àti ojúkòkòrò Ijọba Ológun àti Alágbádá (Òṣèlú) ló sọ Èkó di aginjù laarin àwọn olú ilú àgbáyé.

A lérò wi pé Ijọba Òṣèlú ti àwọn ará ilú yàn fún “àyipadà” kúrò ninú iwà ibàjẹ́ tó gba orilẹ̀ èdè kan fún igbà pi pẹ́, yio wa àtúnṣe fún Èkó.  Gómìnà Akinwunmi Àmbọ̀dé ni lati wá àtúnṣe si iyà ti ojú ará ilú nri nipa gbi gbé ọkàn lé ọkọ̀ ilẹ́ fún ohun irinna nikan, nipa pi pari iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin àti ibùdókọ̀ ojú omi ti Ijọba Gómìnà Babátúndé Raji Fáṣọlá bẹ̀rẹ̀, ki wọn si ṣe kun nipa ipèsè ibùdókọ òfúrufú àti ohun amáyédẹrùn yoku.

“Èkó kò ni bàjẹ́ o – ó bàjẹ́ ti”.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-15 20:33:21. Republished by Blog Post Promoter

“A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ” – Ìdàpọ̀ Àríwá àti Gũsu Nigeria: – 1914 Amalgamation of the Northern and Southern Nigeria

Ó pé ọgọrun ọdún ni ọjọ́ kini, oṣù kini ọdún Ẹgba-̃le-mẹrinla ti Ìjọba Ìlú-Ọba ti fi aṣẹ̀ da Àríwá àti Gũsu orílẹ̀ èdè ti a mọ̀ si Nigeria pọ.  Ìjọba Ìlú-Ọba kò bere lọwọ ará ilú ki wọn tó ṣe ìdàpọ̀ yi, wọn ṣe fún irọ̀rùn ọrọ̀ ajé ilú ti wọn ni.

Yorùbá ni “À jọ jẹ kò dùn bi ẹni kan kò ri”.  Ni tõtọ, Ijọba Ilu-Ọba ti fún orilẹ̀ èdè Nigeria ni ominira, ṣùgbọ́n èrè idàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ kò tán.  Gẹgẹbi Olóyè Ọbafẹmi Awolọwọ ti sọ nigbati wọn ńṣe àdéhùn fún ominira pe: “ominira ki ṣe ni ti orúkọ ilú lásán, ṣùgbọ́n ominira fún ará ilú.  A ṣe akiyesi pe lẹhin ìdàpọ̀ ọgọrun ọdún, orilẹ̀ èdè ko ṣe ikan.

Yorùbá ni “A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ” Gẹgẹbi òwe yi, ki ṣe ki kó ọ̀kẹ́ aimoye owó lati ṣe àjọyọ̀ ìdàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ ló ṣe pàtàki, bi kò ṣé pé ki a tó ọ̀rọ̀ bára sọ.

Yorùbá ni “Ọ̀rọ̀ la fi dá ilé ayé”.  Bi ọkọ àti iyàwó bá wà lai bára sọ̀rọ̀, igbéyàwó á túká, nitori eyi, ó ṣe pàtàki ki gbogbo ara ilú Nigeria lápapọ̀ ṣe àpérò bi wọn ti lè bára gbé ki ilú má bã túká.

ENGLISH TRANSLATION

“One does not qualify to live with a person without also qualifying to talk to the person” – Amalgamation of the Northern and Southern Nigeria Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-07 23:11:15. Republished by Blog Post Promoter

Àjọ jẹ kò dùn bi Ẹni kan kò ri: Ìná dànù àwọn ọmọ Olówó Nigeria ni Ìlú-Ọba – Eating together is not fun when some are deprived: Squandering of Nigeria Wealth in the UK, TV Channel 4 Documentary

Lati ọjọ́ ti aláyé ti dá ayé ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ti wà.  Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kún fún ọrọ̀ oriṣiriṣi, ṣùgbọ́n, iwà àpà, ojúkòkòrò, ki kó ti ilé dà si ita, àti ìfẹ́ àjòjì ju ara ilé ẹni lọ, ló fa iṣẹ́ ti ó pọ̀ ni Ilẹ̀-Aláwọ̀dúdú.  Iwà burúkú wọnyi, pàtàki laarin àwọn Olóri ilú tàbi alágbára ló fa ti ta ara ẹni lẹ́rú si Òkè-Òkun, ogun abẹ́lé àti òwò ẹrú ti ayé òde òni ṣi wà.  Àwọn Òṣèlú àti Olóri ilú kò ti kọ́ ọgbọ́n, nitori wọn nṣe àṣiṣe si nipa li lo iṣẹ ti wọn gbà lai ṣe kó owó ilú jẹ, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ ló fa ibàjẹ́ ohun amáyédẹrùn àti ìṣẹ́ laarin ọrọ̀ ni orilẹ̀ èdè Nigeria.

Melo ninú ọmọ ayé òde òni ló ránti àwọn Ọlọ́rọ̀ ilẹ̀ Yorùbá ni aadọta ọdún sẹhin?  Òmíràn kò mọ itumọ̀ ọ̀rọ̀ Èkó/Yorùbá pé “Bi ó ti ẹ lówó bi Da Rocha” lai bèrè pé tani Da Rocha?  Àwọn Ọlọ́rọ̀ àná bi Candido Joao Da Rocha, Ọlọ́rọ̀ owó ọ̀kẹ́ aimoye àkọ́kọ́ ni orilẹ̀ èdè Nigeria ti ilú Èkó, Olóyè Adéọlá Odùtọ́lá ọ̀gá Oníṣòwò ti Ìjẹ̀bú-Òde ti ìpínlẹ̀ Ògùn, Oloye Àjàó, S. Bọlaji Bakare, I.O. Àjànàkú Iléṣà, Olóyè T.A. Oni & ati àwọn ọmọ-kunrin rẹ ni Ìbàdàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Oṣinọwọ oníṣòwò ọkọ̀ irinna ni Èkó, Mobọ́láji Bank-Anthony, Asábọ́rọ̀, ọmọ Ìkárọ̀ ni ẹ̀gbẹ́ Ọ̀wọ̀ ni ìpínlẹ̀ Ondo àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ ti wọn ti gbàgbé wọn pẹ̀lú ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀.  Àwọn ti wọn ránti, ki ṣe nitori ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀ láyé ni èrò ránti ṣùgbọ́n àwọn ọmọ tó gba ẹ̀kọ́ ni ó lè jẹ ki wọn ṣe iránti wọn àti bi wọn ti lo ọrọ̀ na a fún lati ṣe oore fún àwọn aláìní.

Àwọn Ọlọ́rọ̀ Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kò kọ́ ọgbọ́n ninú itàn igbẹhin Ọba àti Ìjòyè ti kò lo ipò wọn dáradára, àwọn ti ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ, tàbi ti ó lo ipò wọn lati fi tẹ ará ilú mọ́lẹ̀ ni àtijọ́.  Irú ọrọ̀ bẹ́ ẹ̀  kò bá wọn kalẹ́ bẹni ìrántí wọn kò dára.

Ni ọjọ́ keji ọ̀sẹ̀, ọjọ́ keje oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbàá-lémẹ́rìndínlógún, ilé-iṣẹ́ Amóhùn-máwòrán Kẹrin ni Ilú-Ọba fi àpẹrẹ hàn bi àwọn ọmọ Ọlọ́rọ̀ lati Nigeria ti mba owó ninú jẹ́ ni Ilú-Ọba.  Yorùbá ni “Ohun ti a kò bá jiyà fún, ki i lè tọ́jọ́”.  Wọn nná owó ti ọgọrun enia lè ná ni ọdún kan ni alẹ́ ọjọ́ kan lai ronú ọ̀pọ̀ aláìní ni orílẹ̀ èdè wọn, ti Bàbá wọn ti fa ijiyà fún lati kó ọrọ̀ ti wọn nná dànù jọ.  Kò si ìyàlẹ́nu ni irú iwà ti àwọn ọmọ ọlọ́rọ̀ Nigeria wọnyi hù nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bàjẹ́, wọn kò ni ẹ̀kọ́, wọn kò mọ iyi owó nitori wọn kò ṣiṣẹ́ fun.

ENGLISH TRANSLATION  Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-06-21 23:57:06. Republished by Blog Post Promoter

A bèrè fún àròkọ ni Èdè àti Àṣa Yorùbá fún Idije Àkọ́kọ́ – The Yoruba Blog is inviting articles on Yoruba Language and Culture for the 2015 Annual Yoruba Blog Competition

A rọ ẹnikẹni ti ó ni ìfẹ́ èdè àti àṣà Yorùbá (pàtàki ọmọ ilé-iwé giga ti ó nkọ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá) ki ó kọ àròkọ fún “theyorubablog” lóri ayélujára.  Àròkọ ti èrò bá kà jù tàbi ti wọn ni ìfẹ́ rẹ jù yio gba ẹ̀bùn ti a o ṣe ni ọdọọdún.  Àròkọ na a gbọ́dọ̀ ni àwọn ohun wọnyi: Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-03 09:30:41. Republished by Blog Post Promoter

Olóri Òṣèlú Nigeria Muhammadu Buhari àti Àtẹ̀lé rẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Oṣinbajo pé Ọgọrun Ọj̀ọ́ lori oye – 100 Days of Buhari/Osinbajo in Office

 

Ọmọ tó rù njẹun diẹ diẹ - A Malnourished baby being fed little by little.  Courtesy: @theyorubablog

Ọmọ tó rù njẹun diẹ diẹ – A Malnourished baby being fed little by little. Courtesy: @theyorubablog

Share Button

Originally posted 2015-09-08 23:59:31. Republished by Blog Post Promoter

“A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù”: Ìmọ̀ràn fún Òṣèlú tuntun àti àwọn ará ilú Nigeria – It takes more than One Day to Nourish a Malnourished child”: Advice for the Newly Elected Politicians and the Nigerian People

Ọmọ ki dédé rù lai ni idi.  Lára àwọn idi ti ọmọ lè fi rù ni: àìsàn, ebi, òùngbẹ, ìṣẹ́, ai ni alabojuto, òbí olójú kòkòrò, ai ni òbí àti bẹ ẹ bẹ lọ.

Orilẹ̀ èdè Nigeria ti jẹ gbogbo ìyà àwọn ohun ti ó lè mú ki ọmọ rù yi, lọ́wọ́ Ìjọba Ológun àti Òsèlú fún ọ̀pọ̀ ọdún.  Nigbati àwọn òbí ti ó fẹ́ràn ọmọ bi Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti àwọn àgbà ti ó bèrè fún Ominira lọwọ Ilú-Ọba, ṣe Òsèlú, ilú kò rù, pàtàki ọmọ Yorùbá.  Wọn fi ọrọ̀ ajé àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ipinlẹ̀, pèsè ohun amáyédẹrùn fún ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, àwọn tó jade ni ilé-iwé giga ri iṣẹ́ gidi àti pé àwọn ará ilú tẹ̀ lé òfin.  Eyi mú ìlọsíwájú bá ilẹ̀ Yorùbá ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.

Ilú bẹ̀rẹ̀ si rù lati igbà ti Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ti fi ipá kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ni  ọdún mọ́kàndinlãdọta sẹhin .  Lati igbà ti wọn ti kó ọrọ̀ ajé gbogbo ipinlẹ̀ si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti a lè pè ni “Òbí” ti jinà si ará ilú ti a lè pè ni “Ọmọ” ti rù.  Ojúkòkòrò àti olè ji jà Ìjọba Ológun àti Òṣèlú lábẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti fa ebi, òùngbẹ àti àìsàn fún ará ilú.

Ni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sẹhin, Olóri Òsèlu tuntun Muhammadu Buhari àti àtẹ̀lé rẹ Túndé Ìdíàgbọn ṣe Ìjọba fún ogún oṣù gẹgẹ bi Ìjọba Ológun.  Nigbati wọn gba Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Òṣèlú ti ó ba ilú jẹ́ pẹ̀lú iwà ìbàjẹ́ ti wọn fi kó ilú si igbèsè lábẹ́ Olóri Òṣèlú Shehu Shagari, wọn fi ìkánjú ṣe idájọ́ fún àwọn tó hu iwà ibàjẹ́, eleyi jẹ ki ilú ké pé Ìjọba wọn ti le jù.  Ká ni ilú farabalẹ̀ ni àsikò na a, ilú ki bá ti dára si.  Nigbati Olóri-ogun Badamasi Babangida gba Ìjọba, inú ilú dùn nitori àyè gba ará ilú lati ṣe bi wọn ti fẹ lati ri owó.  Eleyi jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ olówó ojiji pọ̀ si lati igbà na a titi di oni.  Àyè àti ni owó ojiji nipa ifi owó epo-rọ̀bì ṣòfò, ki kó owó ìpèsè ohun amáyédẹrùn jẹ, gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti iwà ìbàjẹ́, ló pa ilé-iwé giga, ilé-ìwòsàn, pàtàki ìpèsè iná-mọ̀nàmọ́ná, ìdájọ́ àti bẹ ẹ bẹ lọ.

A lè lo òwe “A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù” ṣe àlàyé pé iwà ìbàjẹ́ àti ohun tò bàjẹ́ fún ọdún pi pẹ́ kò ṣe tún ṣe ni ọjọ́ kan, nitori eyi, ki ará ilú ṣe sùúrù fún Ìjọba tuntun lati ṣe àtúnṣe lati ìbẹ̀rẹ̀.  Ki Ìjọba tuntun na a mọ̀ pé “Ori bi bẹ́, kọ́ ni oògùn ori fi fọ́”, nitori eyi ki wọn tẹ̀ lé òfin lati ṣe ìdájọ́ fún àwọn ti ó ba ilú jẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-01-12 10:09:45. Republished by Blog Post Promoter

Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún, Ọbabinrin Elizabeth Keji – Celebration of 90th Birthday of Queen Elizabeth II

Ọbabinrin Elizabeth Keji ni ibi Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún – Queen Elizabeth II at her 90th Birthday celebration.

Ọbabinrin Elizabeth Keji ni ibi Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún – Queen Elizabeth II at her 90th Birthday celebration.

Ọbabinrin Elizabeth Keji, pé aadọrun ọdún láyé ni ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálémẹrindinlólgún.  Gbogbo ará ilú àti àwọn Ìjọ Onigbàgbọ́ pé jọ lati ṣe ayẹyẹ à ṣe pọ̀ fún Ọbabinrin ni ọjọ́ Ìsimi, ọjọ́ kejila, oṣù kẹfà ọdún.  Eleyi bọ si àsikò ti ọkọ rẹ Philips pé ọgọrundinmarun ọdún.

Lẹhin ti Ọbabinrin Elizabeth keji gun ori oyè ni ọdún mẹtalelọgọta sẹhin, ó bẹ ilú Èkó wò ni ọgọta ọdún sẹhin, nigbati Ilú Èkó jẹ́ Olú-Ilú orilẹ̀ èdè Nigeria ki a tó gba Òminira lábẹ́ Ilú-Ọba ni odun Ẹdẹgbaalelọgọta.  A ṣe yi ṣe àmọ́dún o.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán wọnyi.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-06-14 22:22:27. Republished by Blog Post Promoter

Ìkà ò jẹ́ ṣe ọmọ ẹ bẹ́ẹ̀ – Gbi gba wèrè mọ ẹ̀sìn Aláwọ̀-dúdú: The wicked always protect their own – Religious madness in Africa

Libya migrants: Muslim refugees arrested in Italy for throwing Christians into sea after fight

Libya migrants: Muslim refugees arrested in Italy for throwing Christians into sea after fight

Ni ọjọ́ kẹrin-din-lógún, oṣ̀u kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdógún, ọwọ́ Ọlọpa Italy tẹ ọkunrin mẹ̃dogun ti ó ju àwọn Ìgbàgbọ́ mejila si odò nitori ẹ̀sìn lati inú ọkọ̀ ojú agbami ti o nko Aláwọ̀-dúdú ti ó nsa fún ogun àti iṣẹ lo si Òkè-òkun/Ilú-Òyinbò.

Ni gbogbo ọ̀nà ni Aláwọ̀-dúdú fi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Lára gbi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn ni Àlùfã fi ni ki àwọn ọmọ ijọ bẹ̀rẹ̀ si jẹ koríko ti ọmọ rẹ kò lè jẹ, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ijọ ti ó jẹ koríko ló gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Ọmọ ijọ ti kò le bọ ara rẹ tàbi bọ ọmọ, ti ó nda ida-mẹwa nigbati Olóri Ijọ nfi owó yi gun ọkọ̀ òfúrufú fi han pé ọ̀pọ̀ ti gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Aládurà ti ó nri iran ti kò ri tara rẹ gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.

A screen capture from a Boko Haram video purporting to show the kidnapped girls

‘The Chibok girls are never being freed,’ says Boko Haram leader

Ẹlẹ́sin Mùsùlùmi ti ó npa ẹlòmíràn ni orúkọ ẹ̀sìn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Eyi ti ó ni èèwọ̀ ni iwé kika fún ẹ̀sìn ohun “Boko Haram” ti wọn fi nba ilé iwé jẹ, ji àwọn obinrin kò kúrò ni ilé iwé, fihàn pé wọn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Ọjọ́ kẹrinla oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdógún ló pé ọdún kan ti ẹgbẹ́ burúkú “Boko Haram” ti ko igba-le-mọkandinlógún obinrin kúrò ni ilé-iwè ni Chibok.  Lèmọ́mù rán ọmọ tirẹ̀ lọ si ilé-iwé, irú àwọn ọmọ Lèmọ́mù ti ó ka iwé ni ó nṣe Òṣèlú tàbi jẹ ọ̀gá ni iṣẹ́ Ìjọba.

Kò si Òṣèlú Aláwọ̀-dúdú ti kò sọ pé ohun jẹ Onígbàgbọ́ tàbi Mùsùlùmi ṣùgbọ́n eyi kò ni ki wọn ma ja ilú ni olè.  Ìfẹ́ agbára ki jẹ ki wọn fẹ gbe ipò silẹ̀ nitori eyi wọn á fi ẹ̀sìn da ilú rú.  Eleyi ló fa ogun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-18 00:30:26. Republished by Blog Post Promoter

“A ngba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ni wọn ò jẹ́ ki ohun lọ ààtàn lọ jẹ̀: Ìkìlọ̀ fún àwọn tó fẹ́ lọ Ò̀kè-òkun tipátipá” – “Struggling to save the chicks from untimely death and its complaining of being prevented from foraging at the dump – Caution against desperate illegal Oversea migration”

A lè lo òwe yi lati ṣe ikilọ̀ fún ẹni tó fẹ́ lọ si Òkè-òkun (Ìlu Òyìnbó) lọ́nà kọ́nà lai ni àṣẹ tàbi iwé ìrìnà.  Bi ẹbi, ọ̀rẹ́ tàbi ojúlùmọ̀ tó mọ ewu tó wà ninú igbésẹ̀ bẹ ẹ bá ngba irú ẹni bẹ niyànjú, a ma binú pé wọn kò fẹ́ ki ohun ṣoriire.

Watch this video

More than 3,000 migrants died this year trying to cross by boat into Europe

An Italian navy motorboat approaches a boat of migrants in the Mediterranean Sea

Thirty dead bodies found on migrant boat bound for Italy

Bi oúnjẹ ti pọ̀ tó ni ààtàn fún òròmọ adìẹ bẹni ewu pọ̀ tó, nitori ààtàn ni Àṣá ti ó fẹ́ gbé adìẹ pọ si.  Bi ọ̀nà àti ṣoriire ti pọ̀ tó ni Òkè-òkun bẹni ewu àti ìbànújẹ́ pọ̀ tó fún ẹni ti kò ni àṣẹ/iwé ìrìnà.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkú sọ́nà, ọ̀pọ̀ ndé ọhun lai ri iṣẹ́, lai ri ibi gbé tàbi lai ribi pamọ́ si fún Òfin nitori eyi, ọ̀pọ̀ wa ni ẹwọn. Lati padà si ilé á di ìṣòro, iwájú kò ni ṣe é lọ, ẹhin kò ni ṣe padà si, nitori ọ̀pọ̀ ninú wọn ti ju iṣẹ́ gidi silẹ̀, òmiràn ti ta ilé àti gbogbo ohun ìní lati lọ Òkè-òkun. Bi irú ẹni bẹ́ ẹ̀ ṣe npẹ si ni Òkè-òkun bẹni ìtìjú àti padà sílé ṣe npọ̀ si.

Òwe Yorùbá ti ó sọ pé “A ngba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ni wọn ò jẹ́ ki ohun lọ ààtàn lọ jẹ̀ yi kọ́wa pé ká má kọ etí ikún si ikilọ̀, ká gbé ọ̀rọ̀ iyànjú yẹ̀wò, ki á bà le ṣe nkan lọ́nà tótọ́.

ENGLISH TRANSLATION

This proverb can be applied to someone struggling at all cost to migrate Abroad/Oversea without a Visa or proper documentation.   Even when family, friend or colleague that knows the danger in illegal migration, tries to warn such person of the danger, he/she will be angry of being prevented from prosperity. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-19 09:10:15. Republished by Blog Post Promoter

“Àgbá òfìfo ló ńdún woro-woro” – “Empty barrel makes most noise”

Àgbá ti ó kún fún epo-rọ̀bì – Barrel full of Crude oil

Àgbá ti ó kún fún epo-rọ̀bì – Barrel full of Crude oil

Àgbá ti ó kún fún ohun ti ó wúlò bi epo-rọ̀bì, epo-pupa, epo-òróró, epo-oyinbo, ọ̀dà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ki pariwo.  Àgbá òfìfo, kò ni nkan ninú tàbi o ni nkan díẹ̀, irú àgbá yi bi o ti wù ki ó lẹ́wà tó, ni ariwo rẹ máa ńpọ̀ ti wọn ba yi lóri afárá tàbi ori titi ọlọ́dà.

Oil-Barrels-2619620

Àgbá òfìfo ti ó lẹ́wà – Colourful empty barrels

Àgbá òfìfo ni àwọn ti ó wà ni òkè-òkun/ilú òyìnbó ti ó jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati wá ṣe àṣehàn ti wọn bá ti àjò bọ, ohun ti wọn kò tó wọn a pariwo pé àwọn jù bẹ́ẹ̀ lọ.  Ni tòótọ́, ìyàtọ̀ òkè-òkun/ilú-òyìnbó si ilẹ̀ Yorùbá ni pé, àti ọlọ́rọ̀ àti aláìní ló ni ohun amáyé-dẹrùn bi omi, iná mọ̀nà-mọ́ná, titi ọlọ́dà, ilé-iwé gidi, igboro ti ó mọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.  Àwọn Òṣèlú kò kọjá òfin, bẹni irònú wọn ki ṣe ki á di Òṣèlú lati kó owó ilú jẹ.

Ni ayé àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá, owó kọ́ ni wọn fi ńmọ ẹni gidi, àpọ́nlé/ọ̀wọ̀ wà fún àgbà, ẹni ti ó bá kàwé, olootọ enia, ẹni tó tẹpá mọ́ṣẹ́,  akin-kanjú àti ẹni ti ó ni òye.  Ni ayé òde òni, àgbá òfìfo ti pọ ninú ará ilú, àwọn Òṣèlú àti àwọn òṣiṣẹ́ ijọba.  Bi wọn bá ti ri owó ni ọ̀nà èrú, wọn a lọ si òkè-òkun/ilú-òyìnbó lati ṣe àṣehàn si àwọn ti wọn bá lọhun lati yangàn pẹ̀lú ogún ilé ti wọn kọ́ lai yáwó, ọkọ̀ mẹwa ti wọn ni, ọmọ-ọ̀dọ̀ ti wọn ni àti ayé ijẹkújẹ ti wọn ńjẹ ni ilé.  Wọn á ni àwọn kò lè gbé òkè-òkun/ilú-òyìnbó, ṣùgbọ́n bi àisàn bá dé, wọn á mọ ọ̀nà òkè-òkun/ilú-òyìnbó fún iwòsàn àti lati jẹ ìgbádùn ohun amáyé-derùn miran ti wọn ti fi èrú bàjẹ́ ni ilú tiwọn.

Bi àgbá ti ó ni ohun ti ó wúlò ninú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni gidi tó ṣe àṣe yọri ki pariwo. Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Àgbá òfìfo ló ńdún woro-woro”, bá ẹni-kẹ́ni ti ó bá ńṣe àṣehàn tàbi gbéraga wi pé ki wọn yé pariwo ẹnu.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-08-08 18:20:28. Republished by Blog Post Promoter