Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Ìsọ̀rọ̀ ni igbèsi: Ibere ti ó wọ́pọ́ ni èdè Yorùba” – “Questions calls for answer: Common questions in Yoruba language”

Ọpọlọpọ ibere ni èdè Yorùbá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu “ọfọ̀ – K”.  Yàtọ̀ fún li lò ọfọ̀ yi ninú ọ̀rọ̀, orúkọ enia tàbi ẹranko, ọfọ̀ yi wọ́pọ̀ fún li lò fún ibere.  Fún àpẹrẹ, orúkọ enia ti ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọfọ̀ – K ni: Kíkẹ́lọmọ, Kilanko, Kẹlẹkọ, Kẹ́mi, Kòsọ́kọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ; orúkọ ẹranko – Kiniun, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Kòkòrò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn irú ibere àti èsì wọnyi ni ojú ewé yi.

Ìsọ̀rọ̀ ni igbèsi – Slides

View more presentations or Upload your own.

[slideboom id=1069722&w=425&h=370]

Share Button

Originally posted 2015-01-13 09:00:46. Republished by Blog Post Promoter

Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀-huru rẹ kò ní jẹ ki a sùn – If you fail to warn your neighbor of danger, his cries at night might prevent you from sleeping

Ó ti lé ni ọgbọ̀n ọdún ti ìyà iná monomono ti ńfi ìyà jẹ ará ilú orílẹ̀ èdè Nigeria.  Nitori dáku-́dájí iná  mọ̀nàmọ́na ti Ìjọba àpapọ̀ pèsè, ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na kékèké ti a lè fi wé kòkòrò búburú gbòde.

Generators

Power generators: ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na. The image is from http://lowhangingfruits.blogspot.com

Òwe Yorùbá ti ó ni “Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀huru rẹ kò ni jẹ ki a sùn” bá iṣẹlẹ ọ̀rọ̀ àti pèsè ina monamona yi mu.  Pẹlu gbogbo owó ti ó ti wọlẹ̀ lóri àti pèsè ina mona-mona, ará ilé ẹni ti o ńjẹ kòkòrò búburú ti jẹ́run.  Ai sọ̀rọ̀ ará ìlú lati igbà ti aiṣe dẽde iná ti bẹrẹ lo fa hẹ̀rẹ̀huru ariwo ti ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ-iná kékèké ma ńfà.  Ariwo yi pọ to bẹ gẹ, ti àtisùn di ogun.  Àti ọ̀sán àti òru ni ariwo ẹ̀rọ-iná kékèké yi ma ńdá sílẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tó burú jù ni herehuru ti òru.

Ki ṣe omi, epo-rọ̀bi, èédú nikan ni a fi lè ṣe ètò ina mona-mona.  A lè fi õrun,  atẹ́gùn àti pàntí ti ó pọ̀ ni orílẹ̀ èdè wa ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ pèsè iná mona-. Ìlú ti kò ni õrun tó ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ńfi õrun pèsè iná mona-mona.

Ohun ìtìjú ni pé fún bi ọgbọ̀n ọdún ó lé díẹ̀, àwọn Òṣèlú àti ará ìlu, kò ri ará ilé ti ó ńjẹ kòkòrò búburú báwí.

English translation: Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-22 03:51:57. Republished by Blog Post Promoter

OHUN TÍ́ A LÈRÍ NÍNÚ ÀTI ÀYÍKÁ ILÉ – BASIC YORUBA HOUSEHOLD ITEMS

 

YORÙBÁ ENGLISH YORÙBÁ ENGLISH
Àwo pẹrẹsẹ Plates Ṣíbí Spoon
Abọ́ Dish Ọ̀bẹ Knife
Ago Cup Ìgò Omi Water Bottle
Aago Clock Ìkòkò Omi Water Pot
Aṣọ Clothes Omi Water
Oúnjẹ Food Ibi Ìdáná Kitchen
Ilẹ̀kùn Door Igi Ìdáná Firewood
Fèrèsé Window Yàrá Room
Ijoko Seat Gbàngán Living Room
Àga Chair Ilẹ̀ilé Floor
Àga Tábìlì Table Òkèàjà Ceiling
Pẹpẹ Shelf Ọgbà Compound
Òrùlé Roof Iléìwẹ̀ Bathroom
Àpótí Aṣọ Boxes Iléìtọ̀/Iléìgbẹ́ Toilet
Share Button

Originally posted 2013-05-07 23:58:38. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹni bá wá iwa-kuwa, ojú rẹ á ri irikuri” – Ìtàn bi imú Erin ti di gigùn: “Whoever pry unnecessarily, will witness an offensive sight” – The story of how the Elephant’s nose became a trunk.

Ni igbà kan ri, imú Erin dàbi ti àwọn ẹranko tó kù ni, ṣùgbọ́n Erin fi aigbọ tara ẹni, di o ni imú gigùn.  Gbogbo nkan tó nlọ ni ayé àwọn ẹranko yoku ni Erin fẹ tọpinpin rẹ.

Yorùbá ni “Ẹni bá wá iwa-kuwa, ojú rẹ á ri irikuri”.  Ni ọjọ́ kan, gẹgẹbi iṣe Erin, ó ri ihò dúdú kan, ó ti imú bọ lati tọpinpin lai mọ pe ibẹ̀ ni Òjòlá (Ejò nla ti o ngbe ẹranko tàbi enia mi) fi ṣe ibùgbé.  Bi o ti gbé imú si inú ihò yi ni Òjòlá fa ni imú lati gbe mì.  Erin pariwo lati tú ara rẹ̀ silẹ̀ ṣùgbọ́n Òjòlá kò tu imú rẹ silẹ̀.  Ìyàwó Erin gbọ́ igbe ọkọ rẹ, o fa ni irù lati gbiyànjú ki ó tú ọkọ rẹ silẹ̀.  Bi àwọn mejeeji ti  ṣe ́gbìyànjú tó, ni imú Erin bẹ̀rẹ̀ si gùn si titi o fi já mọ́ Òjòlá lẹ́nu.

Imú Erin di gigùn – Elephant’s nose became a trunk. Courtesy: @theyorubablog.com

Imú gigùn yi dá itiju fún Erin, ó fi ara pamọ́ titi, ṣùgbọ́n nigbati àwọn ẹranko ti ó kù ri imú rẹ gigun wọn bẹ̀rẹ̀ si ṣe ilara irú imú bẹ.  Èébú dọlá, ohun itiju di ohun ilara.

Ọ̀bọ jẹ ẹranko ti ó féràn àti ma ṣe àfarawé gbogbo ẹranko yoku.   Ni ọjọ́ kan, Ọ̀bọ lọ si ibi ihò dúdú ti Erin lọ lati ṣe ohun ti Erin ṣe.  Yorùbá ni “Ohun ojú wa, lojú nri”.  Bi ó ti gbé imú si inú ihò dúdú yi ni Òjòlá gbe mi, ó si kú.  Àwọn ẹranko tó kù fi ti Ọ̀bọ kọ́gbọ́n, nitori eyi ni o fi jẹ imú Erin nikan ló gùn ni gbogbo ẹranko.

Ẹkọ pataki ninu itàn yi ni pe “àfarawé” lè fa àkóbá bi: ikú òjijì, àdánù owó àti ara, ẹ̀wọ̀n àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

ENGLISH TRANSLATION

A long time ago, the Elephant’s nose was just normal like that of other animals, but the Elephant for not minding his business became a long nose/hand animal.  The Elephant is always prying at all other animals’ matters.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-06-12 09:30:01. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn Yorùbá bi Àdán ti di “Ko ṣeku, kò ṣẹyẹ” – Yoruba Folklore on how the Bat became “Neither Rat nor Bird”

Adan - Flying Bat

Àdán fò lọ bá ẹyẹ – Bat flew to join the birds @theyorubablog

Ìtàn sọ wí pé eku ni àdán tẹ́lẹ̀ ki ìjà nla tó bẹ́ sílẹ̀ laarin eku àti ẹyẹ.  Àdán rò wípé àwọn ẹyẹ fẹ́ bori, nitorina o fo lati lọ darapọ̀ mọ́ ẹyẹ lati dojú ìjà kọ àwọn ẹbi rẹ eku.

Eku àti ẹyẹ bínú si àdàn nitori ìwà àgàbàgebè ti ó hu yi, wọ́n pinu lati parapọ̀ lati dojú ìjà kọ àdán.  Nitori ìdí èyí ni àdán ṣe bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ lati fi òkùnkùn bora ni ọ̀sán fún eku àti ẹyẹ títí  di òní.

A lè fi ìtàn yi wé àwọn Òṣèlú tó nsa lati ẹgbẹ́ kan si ekeji nitori ipò̀ ati agbára lati kó owó ìlú jẹ.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, wọ́n ma “lé eku meji pa òfo” ni.  Ọkùnrin ti o ni ìyàwó kan, ni àlè sita ma fara pamọ́ lati lọ sí ọ̀dọ̀ obìnrin keji ti wọ́n rò wípé́ á fún wọn ní ìgbádùn.  Nígbàtí ìyàwó ilé bá gbọ́, wọn a pa òfo lọdọ ìyàwó ilé, wọn a tún tẹ́ lọ́dọ̀ àlè.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yí ni wípé iyè meji kò dara, ọ̀dalẹ̀ ma mba ilẹ̀ lọ ni, nitorina, ojúkòkòrò kò lérè.

ENGLISH TRANSLATION

According to Yoruba folklore, the bat was once a rat, until a great fight broke out between the rats and the birds.  Sensing that birds might win the fight, some of the rats became bats, flying to join the birds against their rat kindred. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-09-11 09:20:28. Republished by Blog Post Promoter

Òrìṣà òkè jẹ́ ki npé meji obinrin kò dé inú – Àṣà Ìkó-binrin-jọ: “The prayer of a woman to the god of heaven to have a co-wife/rival is not sincere” – The Culture of Polygamy

Ọkùnrin kan pẹ̀lú iyàwó púpọ̀ wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá.  Àwọn obinrin ti ó bá́ fẹ́ ọkọ kan naa ni à ńpè ni “Orogún”.  Ìwà oriṣiriṣi ni ó ma ńhàn ni ilé olórogún, àrù̀n iyàwó ti ó ńjalè, purọ́, ṣe àgbèrè, aláisàn, ti ó ńṣe òfófó, àti bẹ̃bẹ lọ,  lè má hàn bi ó bá jẹ́ obinrin kan pẹ̀lú ọkọ rẹ ni ó ńgbe gẹ́gẹ́ bi ti ayé ode oni.  Bi iyàwó bá ti pé meji, mẹta, bi àrù́n yi bá hàn si iyàwó keji, èébú dé, pataki ni àsikò ijà.

Ni ẹ̀sin ibilẹ̀, oye iyàwó ti ọkùnrin lè fẹ́, ko niye, pàtàki Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti akikanjú ni àwùjọ.  Bi àwọn ti ó ni ipò giga tabi òkìkí ni àwùjọ kò fẹ́ fẹ́ iyàwó púpọ̀, ará ilú á fi obinrin ta wọn lọ́rẹ.  Ẹ̀sin igbàlódé pàtàki, ẹ̀sin igbàgbọ́ ti din àṣà ikó-binrin-jọ kù.  Òfin ẹlẹ́sin igbàgbọ́ ni “ọkọ kan àti aya kan”.  Bi o ti jẹ́ pé ẹ̀sin Musulumi gbà ki  “Ọkùnrin lè fẹ́ iyàwó titi dé mẹrin”, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin Musulumi igbàlódé ńsá fún kikó iyàwó jọ.

Fẹlá Kúti fẹ́ iyàwó mẹta-din-lọgbọn ni ọjọ kan – Fela Kuti married 27 wives in one day

Fẹlá Kúti fẹ́ iyàwó mẹta-din-lọgbọn ni ọjọ kan – Fela Kuti married 27 wives in one day

Yorùbá ni “Òriṣà òkè jẹ́ ki npé meji obinrin kò dé nú”.  Inú obinrin ti wọn fẹ́ iyàwó tẹ̀lé kò lè dùn dé inú, nitori eyi, kò lè fi gbogbo ọkàn rẹ tán ọkọ rẹ mọ, owú jijẹ á bẹ̀rẹ̀.  Iyàwó kékeré lè dé ilé ri àbùkù ọkọ ti iyálé mú mọ́ra.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oló-rogún kiki ijà àti ariwo laarin àwọn iyàwó àti àwọn ọmọ naa.  Diẹ̀ ninú ọkùnrin ti ó fẹ́ iyàwó púpọ̀ ló ni igbádùn.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ti ó kó obinrin jọ ni ó ńsọ ẹ̀mi wọn nù ni ọjọ́ ai pẹ́ nitori ai ni ifọ̀kànbalẹ̀ àti àisàn ti bi bá obinrin púpọ̀ lò pọ̀ lè fà.   Nitori eyi, ọkùnrin ti ó bá fẹ́ kó iyàwó jọ nilati múra gidigidi fun ohun ti ó ma gbẹ̀hìn àṣà yi.

ENGLISH LANGUAGE Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-06-10 18:00:13. Republished by Blog Post Promoter

“Àbíkú sọ Olóògùn di èké” – “Child mortality mis-portray the genuineness of the Herbalist”

Ìgbàgbọ́ Yorùbá yàtọ̀ si ohun ti àwọn Ẹlẹko-Ijinlẹ fi hàn ni ayé òde òni.  Ni igbà àtijọ́, bi obinrin/iyàwó bá bi ọmọ, ti ó kú ni ikókó tàbi ki ó tó gba àbúrò, ọmọ ti wọn bá bi lẹhin rẹ ni wọn ma fún ni orúkọ “Àbíkú” pàtàki ti ó bá tó bi meji, mẹta ki ọmọ tó dúró.  Yorùbá gbàgbọ́ ninú àpadà-wáyé, ni igbà miran, wọn á fi ibinú fi àmin, bi ki wọn kọ ilà si ara ọmọ ti ó kú tàbi gé lára ẹ̀yà ara ọmọ yi lati mọ bóyá yio padà wá.  Bi ìyá ti ó bi Àbíkú bá bímọ lẹhin ikú ọmọ ti wọn fi àpá si lára, àpá yi ni wọn ma kọ́kọ́ wò lára ọmọ titun.  Bi wọn bá ri àpá yi, wọn o sọ ọmọ naa ni orúkọ Àbíkú.  Orúkọ àbùkù ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Àbíkú – ó lè jẹ́ orúkọ ẹranko, orúkọ ti ó fi ìbẹ̀rù hàn, tàbi orúkọ fún ìmọràn.

Àbíkú jẹ́ ikú ọmọdé àti ìkókó titi dé ọmọ ọdún marun.  Ẹkọ-Ijinlẹ fi hàn pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú ọmọdé ti Yorùbá mọ̀ si Àbíkú yi ti ìpasẹ̀ wọnyi wá: àrùn tó ṣe-dádúró, oúnjẹ-àìtó, omi-ẹlẹgbin,  ilé-iwòsàn ti kò pé tàbi ai si ilé-iwòsàn, àrùn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ọmọ ti ó ni iwọn-kékeré nigbà ìkókó. Owe Yoruba ti o ni “Àbíkú sọ Olóògùn di èké” fi ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn pé, kò si oògùn ti ó lè dá Àbíkú dúró.  Ìmọ̀ Ijinlẹ fi hàn pe ki ṣe gbogbo ọmọ ti ó kú, ni ó yẹ ki ó kú, nitori lati igbà ti àtúnṣe àwọn ohun ti ó nfa ikú ọmọdé yi ti wà, Àbíkú din-kù – nipa ìpèsè omi ti ó mọ́, ilé-ìwòsàn ọmọdé, ilà-lóye àwọn obinrin nipa ìtọ́jú aboyún àti ọmọdé

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-19 21:51:28. Republished by Blog Post Promoter

Gbogbo ọmọ Yorùbá n’ilé l’óko ẹ fi etí si Ìròyìn Asọ̀rọ̀mágbèsí Ìlú-Ọba fún èdè Yorùbá lóri ayélujára – Yoruba at home and abroad log in to BBC Yoruba online Service.

Fi etí si Ìròyìn èdè Yorùbá lóri Asọ̀rọ̀mágbèsí Ìlú-Ọba - Listen to BBC Yoruba Service
Share Button

“Tori wèrè ìta la ṣe n ni wèrè inú ile”: Idibò lati yan Olóri Òṣèlú ni ọdún Egbãlemẹdógún – Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu Fakọyọ – “It takes a mad family member to confront an external aggression/madness”: Election 2015 Senator Bola Ahmed Tinubu was gallant

Ẹ̀rù ba onilé àti àlejò fún Nigeria nitori idibò à ti yan Olóri Òṣèlú à̀ti àwọn Òṣèlú yoku, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun pe ọjọ́ na ti wá, ó ti lọ, ilú ti yan Olóri Òṣèlú tuntun Ọ̀gágun Muhammadu Buhari lati gba ipò lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Goodluck Ebele Jonathan.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú Alágboorun ti ó ti ṣe Ìjọba fún ọdún mẹrindinlógún, ti ṣe iléri wi pé àwọn yio wa lori oyè fún àádọ́ta ọdún nitori ẹgbẹ́ wọn ló pọ̀jù ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú.  Yorùbá pa òwe pé “À ti gba ọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́, ki ṣe ojú bọ̀rọ̀” pàtàki, à ti gba ipò lọ́wọ́ Òṣèlú ki ṣe ojú bọ̀rọ̀.  Gẹ́gẹ́ bi òwe yi, ẹnikẹni mọ̀ pé Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ki fẹ gbé ipò silẹ̀.  Bi ó bá ṣe é ṣe wọn ò kọ lati kú si ipò, nitori wọn kò sin ará ilú.

Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu ṣe àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari  -  APC Rally

Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu ṣe àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari – APC Rally

Yorùbá sọ wi pé “Àgbájọ ọwọ́ la fi nsọ̀yà”, lai si ipa ti Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu kó lati kó ẹgbẹ yoku mọ́ra àti àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari lati  jade ni igbà kẹrin fun ipò Olóri Oselu, “Àyipadà” ti ará ilú fẹ́ kò bá ma ṣe e ṣe.

 

ENGLISH TRANSLATION  
Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-03 21:08:29. Republished by Blog Post Promoter

ÀWÒRÁN ÈLÒ ỌBẸ̀ YORÙBÁ – PHOTO GALLERY OF SOME YORUBA SOUP/STEW/SAUCE INGREDIENTS

Share Button

Originally posted 2013-05-03 23:19:39. Republished by Blog Post Promoter