Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Ẹrù fún Ìgbéyàwó Ìbílẹ̀” – “Traditional Bridal List”

Apá Kini – Part One

Traditional Wedding Picture

Gifts at a modern Yoruba Traditional wedding — courtesy of @theYorubablog

 Ìnáwó nla ni ìgbéyàwó ìbílẹ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá “Bi owó ti mọ ni oògùn nmọ”, bi agbára ọkọ ìyàwó àti ìdílé bá ti tó ni ìnáwó ti tó.

Ẹrù ìgbéyàwó ayé òde òní ti yàtọ si ẹru ayé àtijọ́ nitori àwọn Yorùbá ti o wa ni àjò nibiti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù yi kò ti wúlò, nitori èyi ni a ṣe kọ àwọn ẹrù ti a lè fi dipò pàtàki fún àwọn ti ó wà lájò.

ENGLISH TRANSLATION

Traditional Marriage is an expensive event, but according to Yoruba proverb “The amount of your money will determine the worth of your medicine”, meaning that the amount expended can be determined groom and bridegroom and their family’s wealth or purse.

The Bridal list of the modern time are slightly different because of the Yoruba abroad where most of the traditional items are not useful hence the suggestion of substitute.

RÙ TI ÌYÀWÓ – BRIDAL PERSONAL LIST  
YORÙBÁ ENGLISH ÌYÈ QTY DÍPÒ SUBSTITUTE
Bíbélì/Koran Bible/ Quoran Ẹyọ Kan 1 pcs Kò kan dandan Not compulsory
Òrùka Ring Ẹyọ Kan 1 pcs Ẹ̀gbà ọwọ́
Agboòrùn Umbrella Ẹyọ Kan 1 pcs
Bẹ̀mbẹ́ Tin Box Ẹyọ Kan 1 pcs Àpóti Ìrìn-nà Travelling Box
Ohun Ẹ̀ṣọ́ Jewellery Odidi Kan 1 Complete Set Wúrà, Fàdákà tàbi Ìlẹ̀kẹ̀ Gold/Silver or Bead Jewelry
Aago ọwọ Wrist Watch Ẹyọ Kan 1 pcs
Aṣọ Ànkàrá Cotton Print Ìgàn mẹrin 4 bundle Aṣọ òkèrè Lace or Guinea Brocade
Àdìrẹ Tie & Dye Cotton Ìgàn mẹrin 4 bundle
Aṣọ Òfi/Òkè Traditional  woven fabric Odidi kan 1 Complete Set Kẹ̀kẹ́ ìgbọ́mọ sọ́kọ̀ tàbi ti ọmọ kiri Car Sit or Buggy
Gèlè̀ Head Ties Ẹyọ Mẹrin 4 pcs A lè yọ gèlè lára aṣọ Separate 1.6yds from fabric for Headtie
Bàtà àti Àpò Shoe & Bag Odidi Meji 2 sets Mú àpò tó bá bàtà mu Mix & Match bag & shoe
Sálúbàtà Slippers/Sandal Meji 2 pairs
Ọja Aṣọ òfì Baby Wrap ẸyọMẹrin 4 pcs Àpò ìgbọ́mọ 1 Baby Start Carrier
Odó àti ọmọ ọdọ Mortar and pestle Odidi Kan 1 set Ẹ̀rọ ìgúnyán Pounding Machine
Ọlọ àti ọmọ ọlọ grinding stones Odidi Kan 1 set Ẹ̀rọ Ilta Blender
Ìkòkò ìdána Cooking Pots & Pans Mẹrin 4 pcs Kò kan dandan No longer necessary
Share Button

Originally posted 2015-03-10 10:30:47. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀YÀ ARA – ÈJÌKÁ DÉ ẸSẸ̀: PARTS OF THE BODY – SHOULDERS TO TOES

You can also download the mp3 by right clicking here: Parts of the body in Yoruba – shoulders to toes (mp3)
Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-23 21:34:14. Republished by Blog Post Promoter

Yí Yára bi Ojú-ọjọ́ ti nyí padà nitori Èérí Àyíká – Effect of Environmental Pollution on Rapid Climate Change

Ẹ wo àròkọ “Yí Yára bi Ojú-ọjọ́ ti nyí padà nitori Èérí Àyíká” lóri ayélujára ni ojú ewé yi: Check out the essay on “Effect of environmental pollution on rapid climate change” on our YouTube channel on the internet.

Share Button

Originally posted 2019-01-21 17:55:15. Republished by Blog Post Promoter

“Fi ọ̀ràn sínú pète ẹ̀rín; fi ebi sínú sunkún ayo” – “Keep your troubles inside and laugh heartily; keep your hunger hidden and pretend to weep from satiation”

Bi a bá wo iṣe àti àṣà Yorùbá, a o ri pe àwọn “Àlejò lati Òkè-Òkun” ti o ni “Inú Yorùbá ló dùn jù ni àgbáyé” kò jẹ̀bi.

Kò si ibi ti enia lè dé ni olú-ilú àti ìgbèríko/agbègbè Yorùbá ti kò ni ri ibi ti wọn ti ńṣe àpèjẹ/ayẹyẹ. Yoruba ni “Ọjọ́ gbogbo bi ọdún”, pataki ni ilú Èkó, lati Ọjọ́-bọ̀ titi dé Ọjọ́-Àìkú ni wọn ti ńṣe àpèjẹ, ilú miran ńṣe àpèjẹ ni Ọjọ́-Ajé fún àpẹrẹ – Ikẹrẹ-Ekiti. Ọpọlọpọ àpèjẹ/ayẹyẹ àti Ìjọ́sìn ló mú ìlù, orin, ijó àti àsè dáni. Ni gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, àti Ọlọ́rọ̀ àti Òtòṣì ló ńṣe àpèjẹ/ayẹyẹ kan tàbi keji.  Bi wọn ò kómọ-jade; wọn a ṣe ìsìnkú tàbi yi ẹ̀hìn òkú padà; ìṣílé; ọjọ́-ibi; igbéyàwó; Ìwúyè; àjọ̀dún àti bẹ̃bẹ lọ.

Òwò tò gbòde ni “Ilé-apejọ” àti gbogbo ohun èlò rẹ. Ọpọlọpọ àwọn ti o jade ni ilé-iwé giga ti kò ri iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ si kọ́ṣẹ́ bi wọn ti ńwé gèlè, rán aṣọ, àsè sisè àti iṣẹ́ Olù-palèmọ́ àpèjẹ/ayẹyẹ nigbati ẹlẹgbẹ́ wọn ni Òkè-òkun ńṣe àṣe yọri ninú ẹ̀kọ-ijinlẹ.  Fún akiyesi, ilé-àpèjọ pọ̀ ju ilé-ìkàwé lọ.  Ọpọlọpọ àwọn ti ó ńṣe àpèjẹ/ayẹyẹ yi ló ńjẹ igbèsè lati ṣé.  Omiran kò ni ri owó ilé-iwé ọmọ san lẹhin ìsìnkú, tàbi ki wọn ma ri owó lati pèsè oúnjẹ tàbi aṣọ fún ọmọ-tuntun ti wọn ná owó rẹpẹtẹ lati kó jade.

Bi ọjọ gbogbo bá jẹ bi ọdún, àyè àti ronú dà?  Ewu ti ó wà ninú òwe Yorùbá ti ó ni “Fi ọ̀ràn sínú pète ẹ̀rín; fi ebi sínú sunkún ayo”, ni pé, ki jẹ́ ki irú ilú bẹ̃ ri ãnu gbà tàbi ni ìlọsíwájú.  Bawo ni a ti lè ṣe àlàyé pé kò si owó lati rán ọmọ lọ si ilé-iwé tàbi bèrè pé ki Ìjọba Òkè-òkun wá pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, omi, ilé-ìwòsàn àti bẹ̃bẹ lọ fún àwọn ti “Inú rẹ dùn jù ni àgbáyé?”  Fún idi eyi, Yorùbá ẹ jẹ́ ki á ronú lati ṣe àyipadà.  Ọ̀pọ̀ owó ti Ọlọ́rọ̀ fi ńṣe ìsìnkú wúlò fún alàyè lọ; nipa pi pèsè ilé-iwé, omi-ẹ̀rọ, ọ̀nà, ilé-ìkàwé ni orúkọ olóògbé ju ki gbogbo owó bẹ̃ lọ fún àpèjẹ/ayẹyẹ.

ENGLISH LANGUAGE Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-02-14 20:27:33. Republished by Blog Post Promoter

Ọ̀dọ́ Kọ̀yà Ọlọpa orílẹ̀-èdè Nigeria – Nigeria Youths protest Police brutality

Ọlọpa ti fi iyà jẹ ará ilú fún igbà pípẹ́, nitori iwà-ibàjẹ́ àti gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ni iṣẹ́ Ọlọpa àti ni orilẹ̀-èdè Nigeria.  Ọlọpa ti tori àti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fi iyà jẹ ọlọ́jà, àgbẹ, oníṣẹ́ọwọ́ àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀  lọ tàbi pa ọlọ́kọ̀.  Wọn kò mọ àgbà yàtọ̀ si ọ̀dọ́ lati kó enia si àtìmọ́lé lainidii, ṣùgbọn wọn kò jẹ ṣe iwà burúkú yi fún Òṣèlú ti wọn ńjalè orilẹ̀-èdè àti olówó ti ó ngbé Ọlọpa kiri.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ilú ló ti jẹ ìyà lọ́wọ́ Ọlọpa tàbi mọ enia ti ó jẹ iya lainidii.   Bi ẹni pé iwa burúkú Ọlọpa kò tó, Ìjọba dá “Ọlọpa Pàtàki fún Ìgbógun ti Adigun-jalè” silẹ̀ lati ara Ọlọpa.  Orúkọ Ọlọpa kò dára tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn Ọlọpa Pàtàki yi bẹ̀rẹ̀ si gbógun ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ti kò ṣẹ̀, wọn kò bikità fún ẹ̀mi.  Ìwà-ibàjẹ́ ti àwọn Ọlọpa Pàtàki yi burú ju ti àwọn adigun-jalè lọ.

Òwe Yorùbá wi pé “Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun”.  Òṣùwọ̀n Ọlọpa Pàtàki kún ni ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbàá, àwọn ọ̀dọ́ tú jade lati kọ̀yà Ọlọpa Pàtàki fún Ìgbógun ti Adigun-jalè.   Lẹhin idákẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn ọ̀dọ́ ṣe ipinu lati “Sọ̀rọ Sókè” ni pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ṣùgbọ́n jàndùkú àwọn Òṣèlú àti Ọlọpa bẹ̀rẹ̀ si dà wọ́n rú.  Àwọn ọ̀dọ́ ni “Ó tó gẹ́”, wọn tẹnumọ pé wọn kò fẹ Ọlọpa Pàtàki fún Ìgbógun ti Adigun-jalè mọ́. 

Ni alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ogún ọjọ́, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbàá, àwọn tó wọ aṣọ Ológun yinbọn lati tú àwọn ọ̀dọ́ ti ó dúró lati kọ̀yà ni òpópó Lẹkki/Ẹ̀pẹ́ ni ipinlẹ̀ Èkó.  Ni àárọ̀ Ọjọrú, ọjọ́ kọkànlélógún, ìroyin kàn pé ibọn ti àwọn tó wọ aṣọ Ológun yin si àárin èrò, ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ leṣe àti okùnfà ikú omiran, nitori eyi, ìlú Èkó gbaná.  Lára ibi ti àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ni, ọkọ̀ akérò ipinlẹ̀ Èkó, ilé iṣẹ amóhùnmáwòrán, ilé ìyá Gómínà ipinlẹ̀ Èkó Babájídé Sanwó-Olú, ilé-iṣẹ́ Bèbè Odò àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.  Jàndùkú da Àfin Ọba Akinolú ti ilú Èkó rú wọn si gbé ọ̀pá oyé.

Gbogbo Akọ̀wé Èdè Yorùbá lóri ayélujára rọ gbogbo àwọn ọ̀dọ́ ti ó ńbínú pé ki wọn fọwọ́ wọ́nú, ki wọn dẹkun àti ba ọrọ̀ ipinlẹ̀ Èkó jẹ́.   Ki Èdùmàrè tu idilé àwọn ti ó kú ninú.

ENGLISH TRANSLATION

Nigerian Police has always been brutal towards Nigerians in their efforts to extort bribe due to the level of corruption in the Police and Nigeria.  Drivers, traders, farmers etc had fallen victim or killed by Police over bribe.  Police was no respecter of the young or old in locking people up for no just cause, except the politicians and the rich ones moving around with escort.  As if the reputation of the Police was not bad enough, Special Anti-Robbery Squad (SARS) was formed using staffing from existing Nigerian Police.  Overtime, SARS began to terrorise mostly the youths on trump up charges without respecting lives.  SARS became worse than the armed-robbers.    

Continue reading
Share Button

Originally posted 2020-10-22 19:34:49. Republished by Blog Post Promoter

“Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì” – “There is no respect for a King that has no Queen”

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Bi ọmọdé bá tó ni ọkọ́, à fún lọ́kọ́”.  Ọkọ́ jẹ irinṣẹ́ pàtàki fún Àgbẹ̀.  Iṣẹ́-àgbẹ̀ ni ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́. Nitori eyi, bi bàbá ti nkọ́ ọmọ rẹ ọkùnrin ni iṣẹ-àgbẹ̀, ni ìyá nkọ́ ọmọ obinrin rẹ ni ìtọ́jú-ile lati kọ fún ilé-ọkọ.  Iṣẹ́ la fi nmọ ọmọ ọkùnrin, nitori eyi, bi ọkùnrin bá dàgbà, bàbá rẹ á fun ni ọkọ́ nitori ki ó lè dá dúró lati lè ṣe iṣẹ́ ti yio fi bọ́ ẹbi rẹ ni ọjọ́ iwájú.

Bi ọkùnrin bá ni iṣẹ́, ó ku kó gbéyàwó ti yio jẹ “Olorì” ni ilé rẹ.  Ìyàwó fi fẹ́ bu iyi kún ọkùnrin, nitori, ó fi hàn pé ó ni igbẹ́kẹ̀lé.  Àṣà Yorùbá gbà fún ọkùnrin lati fẹ́ iye ìyàwó ti agbára rẹ bá gbé lati tọ́jú.  Nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọba, Baálẹ̀, Ìjòyè àti àwọn enia pàtàki láwùjọ ma nfẹ ìyàwó púpọ̀.  Ìṣòro ni ki wọn fi ọkùnrin ti kò ni ìyàwó jẹ Ọba.  Kò wọ́pọ̀ ki Ọba ni ìyàwó kan ṣoṣo.

Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyi Adeṣida - Coronation of the Late Deji of Akure.

Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyi Adeṣida – Coronation of the Late Deji of Akure.

Ohun ti a ṣe akiyesi ni ayé òde òni, ni Ọba ti ó fẹ ìyàwó kan ṣoṣo nitori ẹ̀sìn, pàtàki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ti ó ni àlè rẹpẹtẹ.  Ọba ayé òde òni ndá nikan lọ si òde lai mú Olorì dáni.  Gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Yorùbá, “Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì”, nitori eyi, kò bu iyi kún Ọba, ki ó lọ àwùjó tàbi rin irin àjò pàtàki lai mú Olorì dáni.  Ohun ti ó yẹ Ọba ni ki a ri Ọba àti Olorì rẹ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ.

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-11 19:13:42. Republished by Blog Post Promoter

Orukọ́ Ẹranko àti Àwòrán – Yoruba Names of Animals and pictures

Share Button

Originally posted 2013-06-21 22:30:27. Republished by Blog Post Promoter

ẸGBẸ́́ YORÙBÁ NÍ ÌLÚỌBA: Finding Yoruba Food in the UK (Dalston Kingsland)

Yorùbá ní “Bí ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ, á dọṣẹ”,ọ̀rọ̀ yí bá ẹgbẹ́ Yorùbá ni Ìlúọba mu pàtàkì àwọn ti o ngbe ni Olú Ìlúọba.  Títí di bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, àti rí oúnjẹ Yorùbá rà ṣọ̀wọ́n.  Ní àpẹrẹ, àti ri adìẹ tó gbó rà lásìkò yi, à fi tí irú ẹni bẹ̃ bá lọ si òpópó Liverpool,  ṣùgbọ́n ní ayé òde òni, kòsí agbègbè ti ènìà kò ti lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá ra.

Lati bi ogún ọdún sẹ́hin, Yorùbá ti pọ̀si nidi àtẹ oúnjẹ títà ni Olú Ìlúọba.  Nitõtọ, oúnjẹ Yorùbá bi iṣu, epo pupa, èlùbọ́, gãri, ẹ̀wà pupa, sèmó, iyán, ẹran, adìẹ tógbó, ẹja àti bẹ̃bẹ wa ni àrọ́wọ́to lãdugbo.  Ṣùgbọ́n, bí ènìà bá fẹ́ àwọn nkan bí ìgbín, panla, oriṣiriṣi ẹ̀fọ́ ìbílẹ̀, bọkọtọ̃, edé gbígbẹ àti bẹ̃bẹ lọ tí kòsí lãdugbo, á rí àwọn nkan wọnyi ra ni ọjà Dalston àti Kingsland fún àwọn ti o ngbe agbègbè Àríwá àti ọja Pekham fún àwọn ti o ngbe ni agbègbè Gũsu ni Olú Ìlúọba.

Àwòrán àwọn ọjà wọnyi a bẹrẹ pẹ̀lú, Ọja Dalston àti Kingsland.  Ẹ fojú sọ́nà fún àwọn ọja yókù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-05 21:06:49. Republished by Blog Post Promoter

“Ayẹyẹ ṣi ṣe ni Òkèrè – Àṣà ti ó mba Owó Ilú jẹ́”: “Destination Events – The Culture that is destroying the Local Currency”

Yorùbá fẹ́ràn ayẹyẹ ṣi ṣe púpọ̀ pàtàki fún igbéyàwó.  Ni ayé àtijọ́, ìnáwó igbéyàwó kò tó bi ó ti dà ni ayé òde òni.  Titi di bi ogoji ọdún sẹhin, ilé Bàbá Iyàwó tàbi ọgbà ẹbi ni wọn ti nṣe àpèjọ igbéyàwó.  Ẹbi ọ̀tún àti ti òsi yio joko fún ètò igbéyàwó lati gba ẹbi ọkọ ni àlejò fún àdúrà gbi gbà fún àwọn ọmọ ti ó nṣe igbéyàwó àti lati gbà wọn ni ìyànjú bi ó ṣe yẹ ki wọn gbé pọ̀ ni irọ̀rùn.  Ẹbi ọkọ yio kó ẹrù ti ẹbi iyàwó ma ngbà fún wọn, lẹhin eyi, ẹbi iyàwó yio pèsè oúnjẹ fún onilé àti àlejò.  Onilù àdúgbò lè lùlù ki wọn jó, ṣùgbọ́n kò kan dandan ki wọn lu ilu tàbi ki wọn jó.

Nigbati ìnáwó rẹpẹtẹ fún igbeyawo bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹlòmíràn bẹ̀rẹ̀ si jẹ igbèsè lati ṣe igbéyàwó pàtàki igbéyàwó ti Olóyìnbó ti a mọ si igbéyàwó-olórùka.  Nitori àṣejù yi, olè bẹ̀rẹ̀ si jà ni ibi igbéyàwó, eyi jẹ́ ki wọn gbé àpèjẹ igbéyàwó àti àwọn ayẹyẹ yoku kúrò ni ilé.  Wọn bẹ̀rẹ̀ si gbé àpèjẹ lọ si ọgbà ilé-iwé, ilé ìjọ́sìn tàbi ọgbà ilú àti ilé-ayẹyẹ.

Yorùbá fẹ́ràn ayẹyẹ ṣi ṣe púpọ̀, ṣùgbọ́n àṣà tó gbòde ni ayé òde òni, ni igbéyàwó àti ayẹyẹ bi ọjọ́ ìbí ṣi ṣe ni òkèrè.  Gẹgẹ bi àṣà Yorùbá, ibi ti ẹbi iyàwó bá ngbé ni ẹbi ọkọ yio lọ lati ṣe igbéyàwó.  Ẹni ti kò ni ẹbi àti ará tàbi gbé ilú miran pàtàki Òkè-Òkun/Ilú Òyìnbó, yio lọ ṣe igbéyàwó ọmọ ni òkèrè.  Wọn yio pe ẹbi àti ọ̀rẹ́ ti ó bá ni owó lati bá wọn lọ si irú igbéyàwó bẹ́ ẹ̀.  Ẹbi ti kò bá ni owó, kò ni lè lọ nitori kò ni ri iwé irinna gbà.  A ri irú igbéyàwó yi, ti ẹbi ọkọ tàbi ti iyàwó kò lè lọ.  Eleyi wọ́pọ laarin àwọn Òṣèlú, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba àti àwọn ti ó ri owó ilú kó jẹ.

Igbéyàwó àti ayẹyẹ ṣi ṣe ni òkèrè, jẹ́ ikan ninú àṣà ti ó mba owó ilú jẹ́.   Lati kúrò ni ilú ẹni lọ ṣe iyàwó tàbi ayẹyẹ ni ilú miran, wọn ni lati ṣẹ́ Naira si owó ilu ibi ti wọn ti fẹ́ lọ ṣe ayẹyẹ, lẹhin ìnáwó iwé irinna àti ọkọ̀ òfúrufú.  Ilú miran ni ó njẹ èrè ìnáwó bẹ́ ẹ̀, nitori bi wọn bá ṣe e ni ilé, èrò púpọ̀ ni yio jẹ èrè, pàtàki Alásè àti Onilù.  A lérò wi pé ni àsìkò ọ̀wọ́n owó pàtàki owó òkèrè ni ilú lati ṣe nkan gidi, ifẹ́ iná àpà fún ayẹyẹ á din kù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-04-26 18:55:23. Republished by Blog Post Promoter

“Ki Àgbàdo tó di Ẹ̀kọ, a lọ̀ ọ́ pa pọ̀: Ògì Ṣí ṣe” – “For Corn to become Pap it has to be grinded – Pap Making”

Ra Àgbàdo lọ́jà - Buy the Corn

Ra Àgbàdo lọ́jà – Buy the Corn

Àgbàdo ni wọn fi nṣe Ògì.  Ògì ni wọn fi nṣe Ẹ̀kọ́.  Ògì ṣí ṣe fẹ ìmọ́ tótó, nitori eyi, lai si omi, Ògì kò lè ṣe é ṣe.  Ọkà oriṣiriṣi ló wà ṣùgbọ́n, Ọkà Àgbàdo àti Bàbà ni wọn mọ̀ jù lati fi ṣe Ògì funfun tàbi pupa.  A lè lọ àgbàdo funfun àti pupa pọ̀, ẹlòmiràn lè lọ ẹ̀wà Sóyà pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bi àpẹrẹ àwòrán ojú iwé yi

 

 

Ṣí ṣe Ògì

Ra Àgbàdo lọ́jà
Da Àgbàdo rẹ fún ọjọ́ mẹta ninú omi tútù tàbi omi gbi gbóná
Ṣọn Àgbàdo kúrò ninú omi lati yọ ẹ̀gbin bi ò̀kúta kúrò
Gbe lọ si Ẹ̀rọ fún li lọ̀ tàbi gun pẹ̀lú odó lati lọ ọ.
Sẹ́ Ògì pẹ̀lú asẹ́ aláṣọ tàbi asẹ́ igbàlódé
Bẹ̀rẹ̀ si yọ omi ori Ògì si sẹ bi ó bá ti tòrò
Pààrọ̀ omi ori rẹ fún ìtọ́jú rẹ fún ji jẹ tàbi
Da Ògì sinú àpò ki ó lè gbẹ fún ìtọ́jú

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-07-17 23:46:06. Republished by Blog Post Promoter