Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

Bi Irọ́ bá lọ fún Ogún Ọdún, Òtítọ á ba Lọ́jọ́ Kan – Ìbò Ọjọ́ Kejilá Oṣù Kẹfà Ọdún fún MKO Abiọ́lá Kò Gbé – Truth will always catch up lies – June 12 Election of Late Chief MKO Abiola is not in Vain

Lẹhin ọdún mẹẹdọgbọn ti Ijoba Ologun Ibrahim Babangida fagilé ìbò ti gbogbo ilú dì lai si ìjà tàbi asọ̀ tó gbé Olóògbé Olóyè Moshood Káṣìmáawòó Ọláwálé Abíọ́lá wọlé, Ìjọba Muhammadu Buhari sọ ọjọ́ kejilá oṣù kẹfà di “Ọjọ́ Ìsimi Ìjọba Alágbádá” fún gbogbo orílẹ̀-èdè Nigeria.

Ìjọba Ológun àti Ìjọba Alágbádá ti o ti ṣèlú́ lati ọdún mẹẹdọgbọn sẹhin rò wi pé ó ti pari, nitori wọn fẹ́ ki ọjọ́ yi di ohun ìgbàgbé, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Bi irọ́ bá lọ fún ogún ọdún, òtítọ́ á ba lọ́jọ́ kan”.  Òtítọ́ ti bá irọ́ ọdún mẹẹdọgbọn ni ọjọ́ òní ọjọ́ kejila oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún.  Olórí Òṣèlú Muhammadu Buhari dójú ti àwọn onírọ́ ti ó gbá gbogbo ẹni ti ó dìbò lójú.

Ki Ọlọrun kó dẹlẹ̀ fún Olóògbé Olóyè MKO Abíọ́lá, gbogbo àwọn ti ó kú lai ri àjọyọ̀ ọjọ́ òní.

ENGLISH TRANSLATION

Twenty-five years after a peaceful and fair election of late Chief MKO Abiola was annulled by the military Junta Ibrahim Babangida, the government of President Muhammadu Buhari declared “June 12 Democracy Day and National Public Holiday”. Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-06-13 02:32:27. Republished by Blog Post Promoter

“Njẹ́ ó yẹ ki Adájọ́ ti ó bá hu iwà ibàjẹ́ kọjá Òfin?” – “Should Judges be above the Law?”

Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú àwọn Adájọ́ ti wọn fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kàn - DSS arrest of alleged corrupt Judges. Courtesy: @theyorubablog

Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú àwọn Adájọ́ ti wọn fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kàn – DSS arrest of alleged corrupt Judges. Courtesy: @theyorubablog

Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ keje, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbàálémẹ̀rindinlógún, ìròyìn pé àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ já lu ilé àwọn Adájọ́ ti wọn fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kàn jade lẹhin ti wọn ti dúró titi ki “Ẹgbẹ́ Adájọ́” gbé àwọn iwé ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ yẹ̀wò .  Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ròyìn pé wọn bá owó rẹpẹtẹ, pàtàki oriṣiriṣi owó òkè òkun, ni ilé awon Adájọ́ wọnyi.   Lati igbà ti iroyin ti jade, àwọn ‘Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò’ lérí pé àwọn yio da iṣẹ́ silẹ̀ ti Olóri Òṣèlú Muhammadu Buhari kò bá pàṣẹ ki wọn tú àwọn Adájọ́ naa silẹ̀ ni wéréwéré.

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Adájọ́ àti Agbẹjọ́rò ki i ṣe iṣẹ́ nitori àgbà ni ó ndá ẹjọ́ bi ijà bá bẹ́ silẹ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá.  Fun àpẹrẹ, bi àwọn ọmọdé bá njá, àgbàlagbà ti ó bá wà ni ilé ni yio là wọ́n, bi àwọn iyàwó-ilé bá njà, olóri ẹbi tàbi Àrẹ̀mọ ni yio la ijà.  Bi ó bá jẹ́ ijà nitori ilẹ̀ oko, Baálẹ̀ Abúlé naa ni wọn yio kó ẹjọ́ lọ bá fún idájọ́, ti ó bá jẹ àdúgbò kan si ekeji ló njà, wọn á kó ẹjọ́ lọ bá Ọba ilú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.   Lati wa idi òtitọ́, wọn lè kó àwọn ti ó njà lọ si ojúbọ Òriṣà lati búra.  Lẹhin ti àwọn Ìlú-Ọba pin àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilú àwọn Aláwọ̀dúdú, iṣẹ́ Agbẹjọ́rò di ki kọ́ ni ilé-iwé giga.

Kò si ọmọ Nigeria rere ti kò mọ̀ wi pé,  ‘’Ẹ̀ṣẹ̀ nlá ijiyà kékeré tàbi ki ó má si ijiyà rara fún Olówó, ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ijiyà nla ni fún tálákà tàbi aláìní’’, nitori iwà burúkú àwọn Adájọ́ ti ó ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Agbejoro.  A ri gbọ́ wi pé bi “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò” bá ni ẹjọ́ ni iwájú Adájọ́ lẹhin ti ẹjọ́  agbejoro ti dé iwájú Adájọ́, wọn yio kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ ti “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò” gbé wá.  Eleyi jẹ́ ikan ninú idi pàtàki ti ọ̀pọ̀lọpọ̀  Agbejoro ti fẹ́ fi ọ̀nàkọnà dé ipò “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò”.  Ó yẹ ki wọn gbé eyi yẹ̀wò nitori ni ilú ti òfin bá wà, kò yẹ ki ẹnikẹni kọjá òfin.  Ni Òkè-Òkun, Gó́́mìnà, àgbà Òṣèlú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ kò kọjá òfin.

“Ẹni ma a bèrè ẹ̀tó lábẹ́ òfin yio lọ pẹ̀lú ọwọ́ mímọ́”,  ẹ gb́e ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò bóyá bi wọ́n bá fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kan Adájọ́, kò yẹ ki Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wa idi.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-10-11 18:38:27. Republished by Blog Post Promoter

Ìkíni ni Èdè Yorùbá – Greetings in Yoruba Language

Yorùbá ni kíkí fún gbogbo àsìkò ọjọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti èto.̀  Fún àpẹrẹ: a lérò wípé àwọn ti a kọ si abala ojú     ìwé yi,  àti bi a ti le pe ìkíni kankan a wúlò  fún yin.

ENGLISH TRANSLATION

As a sign of respect, the Yoruba have greetings for any time of the day, special events and ceremonies. We hope you will enjoy some of the greetings below in the slides and voice recordings.

Share Button

Originally posted 2013-07-04 23:41:35. Republished by Blog Post Promoter

Owó orí ìyàwó – “Bíbí ire kò ṣe fi owó ra”: Bride Price – “Good pedigree cannot be bought with money”

OWO  NAIRA

OWO NAIRA

Bi ọkọ ìyàwó bà ti lówó tó ni ó ti lè fi owó si inú àpò ìwé fún owó orí àti àwọn owó ẹbi yókù.  Ni ayé òde òní, owó fún àpò ìwé méjìlá wọnyi lè bẹ̀rẹ̀ lati Aadọta Naira, ẹbí dẹ̀ lè din àpò ìwé kù lai ṣi àpò ìwé tàbi ka owó inú rẹ̀.

Òwe Yorùbá ni “Bíbí ire kò ṣe fi owó rà”.  Ìyàwó ìbílẹ̀ ki ṣe iṣẹ́ ọkọ-ìyàwó nikan, bi ẹbí ìyàwó bá wo àwọn ènìà pàtàkì lẹhin ọkọ, inú wọn a dùn ju owó lọ, nitori wọn a mọ̀ wípé ilé tó dára ni ọmọ wọn nlọ.  Ọpọlọpọ ẹbí ki gba owó orí mọ, wọn a fún ẹbí ọkọ padà ni àpò ìwé owó orí pẹ̀lú ìkìlọ̀ wípé “ọmọ wọn ki ṣe tita, ṣùgbọ́n ki ọkọ àti ẹbi rẹ tọju ọmọ wọn”.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun ti àpò ìwé owó wọnyi wà fún ni ojú ìwé yi.

ENGLISH LANGUAGE

The amount in the envelopes for bride price and other family envelopes are often depend on the purse of the groom.  In this modern time, the amount in each of the twelve (12) envelopes can start from Fifty (50) Naira. The bride’s family can also use discretion to reduce the number of envelopes or not count the amount in the envelopes to assist the Groom.

According to Yoruba proverb, “Good pedigree cannot be bought with money”.  Traditional marriage ceremony is not the responsibility of the groom alone, if the bride’s family observe that the groom has good family support, he will be more honoured than preference for money. Many families are no longer collecting “Bride Price”, hence the symbolic envelopes containing the “Bride Price” is returned with a caution that “their daughter is not for sale, but the groom and his family should take good care”.  Look through the list of envelopes and the purpose for which the envelope is used.

 ÀPÒ OWÓ ÌYÀWÓ – BRIDAL MONEY   ENVELOPES  
Yorùbá English Iye Owó Amount Naira Iye ti agbára ká Flexible Amount
Owó Ìkanlẹ̀kùn Knocking on the door money Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Irinna Transportation money Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Iwọlé Entry money Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Ìyá gbọ́ Money for mother-in-law’s information Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Bàbá gbọ́ Money for father-in-law’s information Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Ìyàwó Ilé Money for the Bridal family wives Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Ọmọkunrin Ilé Money for Bridal family male youths Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Ọmọbririn Ilé Money for Bridal family female youths Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Ijoko Àgbà Money for the Bridal family elders’ sitting Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Ìṣígbá Money for opening the Bridal Bride Price Dish Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Ìṣíjú Ìyàwó Money for opening the Bridal Bridal veil cover Ẹgbẹ̀rún   Naira N1,000.00 lati Aadọta Naira From N50.00
Owó Orí Bride Price Ẹgbẹ̀rún Naira N1,000.00 Ẹbí ìyàwó a ma dapadà It is often returned
Share Button

Originally posted 2015-03-13 10:15:11. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ káàbọ̀ si ọdún Ẹgbàálémẹ́tàdínlógún – Welcome to 2017

Share Button

Originally posted 2016-12-31 23:30:32. Republished by Blog Post Promoter

“Ìwà bi Ọlọrun pẹ̀lú Ìtẹ́lọ́rùn, Èrè nla ni” – “Godliness with Contentment, is great Gain”

 Ìtẹ́lọ́rùn - Contentment. Courtesy: @theyorubablog

Ìtẹ́lọ́rùn – Contentment. Courtesy: @theyorubablog

Bi kò bá si ìtẹ́lọ́rùn, kò si ohun ti èniyàn ni ti ó tó.  À i ni ìtẹ́lọ́rùn ló nfa iwà burúkú bi, olè̀ jijà, àgbèrè, ojúkòkòrò, irà-kurà, ijẹ-kújẹ, ìpànìyàn, gbi gbé oògùn olóró àti àwọn àlébù yoku.  Kò si owó ti ẹni ti kò ni ìtẹ́lọ́rùn lè ni, ki ó tó.

Yorùbá ni “Isà òkú ki i yó”, bẹ́ ẹ̀ ló ri fún a lai ni ìtẹ́lọ́rùn, nitori ojoojúmọ́ ni ohun tuntun njade, pàtàki ni ayé oriṣiriṣi ẹ̀rọ igbàlódé àti ẹ̀rọ ayélujára yi.  Fún àpẹrẹ, oriṣiriṣi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ló wà, ti wọn nṣe jade ni ọdọdún, àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ igbàlódé owó iyebiye.  Pẹ̀lú ìṣẹ́ ti ó pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú, ọkọ̀ ilẹ́ kò tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú àti Olóri-Ìjọ mọ, ọkọ̀-òfúrufú bi ó ti wọ́n tó, ni wọn nkó jọ.  Nitori eyi, kò si owó ti ó lè tó fún ẹni ti ó bá fẹ́ràn ohun ayé.

Ẹ̀kọ nla ni lati kọ́ ọmọ ni ìtẹ́lọ́rùn lati kékeré.  Ẹni ti ó bá ni ìtẹ́lọ́rùn, ló ni ohun gbogbo, nitori ko ni wo aago aláago ṣiṣẹ́, á lè lo ohun ti ó bá ni pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn.

Pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, “Ohun ti kò tó loni mbọ̀ wá ṣẹ́kù ni ọ̀la” bi èniyàn bá lè farabalẹ̀.

ENGLISH TRANSLATION

If there is no contentment, nothing can ever be enough.  Lack of contentment is the root cause of many character disorders, such as stealing, adultery, greed, compulsive shopping, gluttony, killings, drug peddling and other vices.  No amount of money is ever enough for someone who lacks contentment. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-22 16:00:00. Republished by Blog Post Promoter

Àwòrán ati pi pe Orúkọ Ẹranko ni Èdè Yorùbá Apá Kini àti Apá Keji – Pictures and pronunciation of Names of Animals in Yoruba Language Part 1 and Part 2

Bi ó ti ẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ nipa orúkọ àti àwòrán ẹranko ni àwọn ìwé ti a ti kọ sẹhin, ṣùgbọ́n Yorùbá ni “Ọgbọ́n ki i tán”, nitori eyi, a ṣe àtúnṣe gẹ́gẹ́ bi “Ọ̀jọ̀gbọ́n Èdè Yorùbá” ti tọka.  Fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ti kò gbọ́ èdè Yorùbá, a fi pipè orúkọ ẹranko pẹ̀lú àwòrán si ojú ìwé yi Apá Kini àti Apá Keji.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-24 12:40:40. Republished by Blog Post Promoter

Kòró/Kòrọ́nà – Ogun ti a kò rí: Coronavirus – the invisible war

Kòró/Kòrọ́nà – Ogun ti a kò rí: Coronavirus – the invisible war

Àjàkálẹ̀ àrùn ma ńṣẹlẹ̀ láti ìgbà-dé-ìgbà. Ni igba kan ri, àjàkálẹ̀ àrùn bi Ṣọ̀pọ̀ná/Olóde, Ikọ́-ife, Onígbáméjì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ló kári ayé. Ni ọdún kẹtàlélógòji sẹhin, Ìkójọ Ètò-Ìlera Àgbáyé (WHO) ṣe ikéde òpin àrùn Ṣọ̀pọ̀ná/Olóde. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé yi, kò jà ju ọdún kan lọ, nigbati àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé miràn ṣi wa titi di àsikò yi. Àrùn Ikọ́-ife kò ti tán pátápátá ni àgbáyé nigbati àrùn Onígbá-meji ti kásẹ̀ ni Òkè-Òkun ṣùgbọ́n kò ti kásè kúrò ni àwọn orilẹ̀-èdè miràn.

Ni igbà ogun àgbáyé, wọn kò ṣe òfin onílé-gbélé. Ẹni ti àjàkálẹ̀ àrùn bi Ṣọ̀pọ̀ná/Olóde tabi Ikọ́-ife, ba nse ni wọn ńsé mọ́lé, ki ṣe gbogbo ilú. Ninu itan, ko ti si àjàkálẹ̀ àrùn ti o se gbogbo agbaye mọle bi ti eyi ti ó njà lọ́wọ́lọ́wọ́, ti Yorùbá sọ ni “Kòró” yi, nitori olóko kò lè re oko, ọlọ́jà kò lè re ọjà, oníṣẹ́-ọwọ́ tàbi oníṣẹ́ ìjọba, omo ilé-ìwé àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ wà ni àhámọ́. Àwọn Onímọ̀-ijinlẹ ṣe àkíyèsí pé inú afẹ́fẹ́ ni àrùn yi ńgbé, o si ńtàn ni wéré-wéré ni ibi ti ọ̀pọ̀ ènìyàn bá péjọ si. Ìjọba ṣe òfin “onílé-gbélé” ti kò gba àpèjọ ti ó bá ju èniyàn mẹwa lọ, èniyàn mẹwa yi ni lati fi ẹsẹ̀ bàtà mẹfa si àárin ẹni kan si èkeji, èyi ni kò jẹ́ ki ẹlẹ́sin Jesu àti Mùsùlùmi péjọ fún ìjọsin ni ọjọ́ ìsimi tàbi ọjọ́ Ẹti. Ọmọ lẹhin Jesu ko le péjọ lati ṣe ikan ninu ọdún ti ó ṣe pàtàki jù fún Ọmọ lẹhin Jesu, ọdún Ajinde ti ọdún Ẹgbàálélógún, Àrùn yi ti mú ẹgbẹgbẹ̀rún ẹmi lọ, o si ti ba ọrọ̀-ajé jẹ́ fún gbogbo orilè-èdè àgbáyé.

Ki Ọlọrun sọ “kòró” di kòrọ́nà gbe gbà lai pẹ́. Àwọn Onímọ̀-ìjìnlẹ̀, Oníṣègùn àti àwọn alabojuto-aláìsàn ńṣe iṣẹ́ ribiribi lati dojú ìjà kọ arun “kòró”. Ninu ìtàn àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé nigbati ko ti si abẹ́rẹ́ àjẹsára, a ṣe àkíyèsí pé àwọn iṣọ́ra ti wọn ṣe wọnyi wúlò lati gbógun ti àrùn Kòró.

Ànìkàngbé/Àdádó – Isolation
Àhámọ́ – Quarantine
Ìmọ́tótó – Good personal hygiene such regular washing of hands
Li lo egbogi-apakòkòrò – Using disinfectants
Onílégbélé/Dín àpéjọ kù – Stay Home/Avoid large gathering
Bi bo imú àti ẹnu – Wearing mask

 

ENGLISH TRANSLATION

Pandemic is not new in the world, as it occurs from time-to-time. Smallpox, Tuberculosis, cholera Etc. were once upon a time a pandemic ravaging the world. The World Health Organization declared the eradication of Smallpox on December 9, 1979. Tuberculosis has not been completely eradicated while Cholera has been drastically contained in the developed world with some cases still occurring in the developing world. Continue reading

Share Button

Originally posted 2020-04-16 01:09:11. Republished by Blog Post Promoter

“BÍ ỌMỌDÉ BÁ ṢUBÚ Á WO IWÁJÚ…”: “IF A CHILD FALLS HE/SHE LOOKS FORWARD…”

BÍ ỌMỌDÉ BÁ ṢUBÚ Á WO IWÁJÚ, BÍ ÀGBÀ BÁ ṢUBÚ Á WO Ẹ̀HÌN

Òwe Yorùbá yi wúlò lati juwe òye àgbàlagbà lati wo ẹ̀hìn fún ẹ̀kọ́ nínú ìrírí tó ti kọjá lati yanjú ọ̀ràn tó ṣòro nígbàtí ọmọdé tí kò rí irú ìṣòro bẹ̃ lati kọ́ ọgbọ́n, má nwo iwájú.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá miran ni “Ẹni tó jìn sí kòtò, kọ ará yókù lọ́gbọ́n”.  Nitotọ ọ̀rọ̀ miran sọ wípé “Ìṣòro ni Olùkọ́ tó dára jù”, ṣùgbọ́n dí dúró kí ìṣòro jẹ Olukọ fún ni lè fa ewu iyebíye, nitorina ó dára ká kọ́ ọgbọ́n lati ọ̀dọ̀ àgbà.  Ọlọ́gbọ́n ma nlo ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n lati yẹra fún ìṣubú.

Ní àsìkò ẹ̀rọ ayélujára yi, òwe “Bí ọmọdé bá ṣubú á wo iwájú, bí àgbà bá ṣubú á wo ẹ̀hìn” ṣi wúlò fún àwọn ọmọdé tí ó lè ṣe àṣàyàn lati fi etí si àgbà, kọ́ ẹ̀kọ́, tàbí ka àkọsílẹ̀ ìrírí àgbà nínú ìwé tàbí lórí ayélujára lati yẹra fún àṣìṣe, kọ́ ibi tí agbára àti àilera àgbà wà fún lílò lọ́jọ́ iwájú.

ENGLISH TRANSLATION

IF A CHILD FALLS HE/SHE LOOKS FORWARD, IF AN ELDER FALLS HE/SHE LOOKS BACK

This Yoruba proverb is relevant to describe the ability of an adult to look back and draw from past experience to solve a problem while a child with no previous experience look forward since he/she has no previous experience to fall back on.

There is another Yoruba proverb that said “The one that fell into a ditch teaches the others wisdom”. Though there is an adage that said “Experience is the best Teacher”, often waiting to learn from personal experience may be too costly, so it is better to avoid the cost by learning a lesson from the Elders.  The wise people would always learn from the experience of others to avoid pitfalls.

In this computer age, the proverb that said “if a child falls he/she looks forward, if an elder falls he/she looks back” is still relevant to encourage the young ones, who have more choices of listening and learning directly from the elder or reading the documented experience of others from books or the internet to avoid past mistakes, learn from the strength and weakness of the Elders for future use.

Share Button

Originally posted 2013-05-03 19:29:24. Republished by Blog Post Promoter

“A kì í fi Oníjà sílẹ̀ ká gbájúmọ́ alápepe – Pí pa Àjòjì ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú” – “One does not leave the person one has a quarrel with and face his/her lackey – Xenophobic attack in South Africa”

Foreign nationals stand with stones and bricks after a skirmish with locals in Durban.

Pí pa Àjòjì ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú – South Africa’s xenophobic attacks

Òwe Yorùbá kan sọ pé “Amúkun, ẹrù ẹ́ wọ́, ó ni ẹ̃ wò ìsàlẹ̀”.  Òwe yi ṣe é lò lati ṣe àyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ pí pa àjòjì ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú yoku, ti ó bẹ́ sílẹ ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú ni oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlémẹ̃dógún.

Èniyàn dúdú ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú, jẹ ìyà lábẹ́ Ìjọba amúnisìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.  Ìfẹ́ Àlejò/Àjòjì ju ara ẹni, jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú jẹ ìyà lábẹ́ Aláwọ̀-funfun lati Òkè-òkun fún ìgbà pi pẹ́.  Ojúkòkòrò Aláwọ̀-funfun si ohun ọrọ̀ ti ó wà ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú pọ̀ si, nigbati ọkàn wọn balẹ̀ tán, wọn ṣe Ìjọba ti ó mú onílé sìn.  Ìjọba amúnisìn yi fi ipá gba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú lati pin fún Aláwọ̀-funfun, wọn ṣe òfin lati ya dúdú sọ́tọ̀, pé dúdú kò lè fẹ́ funfun, wọn bẹ̀rẹ̀ si lo èniyàn dúdú bi ẹrú lóri ilẹ̀ wọn àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.  Àwọn èniyàn dúdú kò dákẹ́, wọn jà lati gba ara wọn sílẹ̀ ninú ìyà àti ìṣẹ́ yi, nitori eyi wọn pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹni wọn gbé àwọn Olóri Aláwọ̀dúdú púpọ̀ si ẹ̀wọ̀n ọdún àimoye.  Lára wọn ni “Nelson Mandela” ti ó lo ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni ẹ̀wọ̀n nitori ijà àti tú àwọn èniyàn rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ Ìjọba amúnisìn.

Ki ṣe ẹ̀yà Zulu tàbi ará ilu Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú nikan ló jà lati gba òmìnira lọ́wọ́ Ìjọba Amúnusìn. Gbogbo àgbáyé àti ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú yoku dide pọ lati pa ẹnu pọ̀ bá olè wi.  Ni àsikò ijiyà yi, Ìjọba àti ará ilú Nigeria ná owó àti ara lati ri pé èniyàn dúdú ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú gba òmìnira lóri ilẹ̀ wọn. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-21 18:18:36. Republished by Blog Post Promoter