Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Bi ojú bá mọ́, Agbe á yalé Aláró, Àlùkò á yalé Olósùn, Lékeléke á yalé Ẹlẹ́fun”: “At the dawn of the day, the blue-touraco makes for the home of the indigo dealer; …”

Bi a bá wo òwe yi, a o ri pe Agbe pọn bi aró, Àlùkò pupa bi osùn nigbati Lékeléke funfun bi ẹfun. Nitori eyi, bi wọn kò ti ẹ̀ lọ si ilé Aláró, Olósùn àti Ẹlẹ́fun, àwọ̀ wọn á si wa bẹ̃, síbẹ-síbẹ, àwọn ẹiyẹ wọnyi gbiyànjú lati lọ si ibi ti wọn ti lè ri ohun ti yio tú ara wọn ṣe ki ó ma ba ṣa.

A lè fi òwe Yoruba ti o ni “Bi ojú bá mọ́, Agbe á yalé Aláró, Àlùkò á yalé Olósùn, Lékeléke á yalé Ẹlẹ́fun” bá ilú, agbójúlógún àti ọ̀lẹ enia wi. Kò si bi owo ilú, òbi, tàbi ẹbí ti lè pọ̀ tó, bi enia kò bá ṣiṣẹ́ kun á parun. Irú ilú ti ó bá ńná iná-kuna, agbójúlógún àti ọ̀le wọnyi yio ráhùn ni ikẹhin. Ẹ gbọ́ orin ti àwọn ọmọ ilé iwé ńkọ ni àsikò eré-ìbílẹ̀ ni ojú iwé yi.

Agbe ló laró, ki ráhùn aró,
Àlùkò ló losùn, ki ráhùn osùn
Lékeléke ló lẹfun, ki ráhùn ẹfun,
Ka má rahùn owó,
Ka má rahùn ọmọ
Ohun táó jẹ, táó mu kò mà ni wọn wa o) (lẹmeji)

ENGLISH TRANSLATION
Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-08-18 17:10:07. Republished by Blog Post Promoter

“Ọbẹ̀ tó dùn, Owó ló pá: Àwòrán àti pi pè Èlò Ọbẹ̀” – “Tasty Soup, Cost Money – Pictures and pronunciation of Ingredients”

Òwe Yorùbá ni “Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pá”, ṣùgbọ́n kò ri bẹ̃ fún ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se.  Elomiran lè lo ọ̀kẹ́ àimọye owó lati fi se ọbẹ̀ kó má dùn nitori, bi iyọ̀ ò ja, ata á pọ̀jù tàbi ki omi pọ̀jù.

Ni tõtọ, owó ni enia ma fi lọ ra èlò ọbẹ̀ lọ́jà, ṣùgbọ́n fún ẹni ti ó mọ ọbẹ̀ se, ìwọ̀nba owó ti ó bá mú lọ si ọjà, ó lè fi ra èlò ọbẹ̀ gẹ́gẹ́ bi owó rẹ ti mọ, ki ó si se ọbẹ̀ na kó dùn.  Ẹ wo àwòrán àti pipè èlò ọbẹ ni abala ojú iwé yi.

View more presentations or Upload your own.

 

View more presentations or Upload your own.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-08 16:30:36. Republished by Blog Post Promoter

Ìpanu – “Kẹ́nu ma dilẹ̀ ni ti gúgúrú, gúgúrú ki ṣe oúnjẹ àjẹsùn”: Snacks – “Popcorn is eaten to keep the mouth busy, it is not an ideal night meal”.

Oúnjẹ òkèlè ni Yorùbá mọ̀ si oúnjẹ gidi.  Ni ọ̀pọ̀ igbà oúnjẹ òkèlè ni oúnjẹ àjẹsùn, ṣùgbọ́n ìpanu ni ohun amú inú dúró ni ọ̀sán.  Àwọn ìpanu bi gúgúrú àti ẹ̀pà, bọ̃li àti ẹ̀pà, gaàrí àti ẹ̀pà àti bẹ̃bẹ lọ ni Yorùbá njẹ ni ọ̀sán lati mu inu dúró ki wọn tó jẹ́ oúnjẹ alẹ́.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àwọn ìpanu wọnyi ni ojú iwé yi.

Bọli – Roasted Plantain.  Courtesy: @theyorubablog

Bọli – Roasted Plantain. Courtesy: @theyorubablog

ENGLISH TRANSLATIONS Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-10-31 17:33:49. Republished by Blog Post Promoter

ỌRỌ ÌYÀNJÙ (WORD OF ADVICE): Ẹni tólèdè lóni ayé ibi ti wọn ti nsọ

R ÌYÀNJÙ (WORD OF ADVICE)

Ẹyin ọmọ Odùduwà ẹjẹ ki a ran rawa létí wípé “Ẹni tólèdè lóni ayé ibi ti wọn ti nsọ”.  Mo bẹ yin  ẹ maṣe jẹki  a tara wa  lọpọ nitorina ẹ maṣe jẹki èdè Yorùbà parẹ. Èdè ti a kọ silẹ, ti a ko sọ, ti a ko fi kọ ọmọ wa, piparẹ ni yio parẹ.  Ẹjẹ ki a gbiyanju lati ṣe atunṣe nipa sísọ èdè Yorùbà botiyẹ kasọ lai si idaru idapọ pẹlu  èdè miran.

Yorùbá lọkunrin ati lobirin ẹ ranti wipe “Odò to ba gbagbe orisun rẹ, gbigbe lo ma ngbe”   Lágbára Ọlọrun, aoni tajo sọnu sajo o, ao kere oko délé o (Àṣẹ).

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-01-31 20:18:56. Republished by Blog Post Promoter

Àwòrán àti pi pè orúkọ ẹ̀yà ara lati ori dé ọrùn – Pictures and pronunciation of parts of the body from head to neck

You can also download the Parts of the body in Yoruba by right clicking this link: Parts of the body in Yoruba – head to neck (mp3)

ORÍ DÉ RÙN HEAD TO NECK
Orí Head
Irun Hair
Iwájú orí Forehead
Ìpàkọ́ back of the  head
Ojú Eye
Imú Nose
Etí Ear
Ẹnu Mouth
Ahán Tongue
Eyín Teeth
Ẹ̀kẹ́ Cheek
Àgbọ̀n Chin
Ọrùn Neck
Share Button

Originally posted 2015-11-13 10:53:10. Republished by Blog Post Promoter

Àwòrán ati Orúkọ àwọn Ẹiyẹ ni èdè Yorùbá – Pictures and names of Birds in Youruba

 

 

 

Share Button

Originally posted 2014-10-17 13:00:55. Republished by Blog Post Promoter

ÀWÒRÁN ÀTI PÍPÈ ORÚKỌ ẸRANKO, APA KEJI – Names of Wild/Domestic Animals in Yoruba

Share Button

Originally posted 2018-03-22 01:59:26. Republished by Blog Post Promoter

Ọdún tuntun káàbọ̀ – Ẹgbà-lé-mẹ́rìnlà – Welcoming the New Year – 2014

Ẹ kú ọdún o – Season Greetings. Courtesy: @theyorubablog

kú dún

Festive Greetings

 kú ìyè dún

Greetings on the return of the year

dún á ya abo

Prosperous New Year  

À èyí ṣe àmọ́dún o.                                                  Better years ahead

View more presentations or Upload your own.
Share Button

Originally posted 2013-12-31 23:11:39. Republished by Blog Post Promoter

“A ki i jẹ Igún, a ki i fi Ìyẹ́ Igún rinti: Ẹnu Ayé Lẹbọ” – “It is forbidden to eat the Vulture or use its feather as cotton bud: One should be careful of what others say”

Ohun ti o jẹ èèwọ̀ tàbi òfin ni ilú kan le ma jẹ èèwọ̀/òfin ni ilú miran ṣùgbọ́n bi èniyàn bá dé ilú, ó yẹ ki ó bọ̀wọ̀ fún àṣà àti òfin ilú.  Bi èniyàn bá ṣe nkan èèwọ̀, ó lè ṣé gbé ti kò bá si ẹlẹri lati ṣe àkóbá tàbi ki ó fi ẹnu ṣe àkóbá fún ara rẹ̀.

Ni ilú kan ti a mọ̀ si “Ayégbẹgẹ́”, àwọn àlejò ọkùnrin meji kan wa ti orúkọ wọn njẹ́ – Miòṣé àti Moṣétán.  Ọba ilú Ayégbẹgẹ́ kede pé èèwọ̀ ni lati jẹ ẹiyẹ Igún ni ilú wọn.  Akéde ṣe ikilọ̀ pé ẹni ti ó bá jẹ Igún, ikùn rẹ yio wu titi yio fi kú ni.  Àwọn àlejò meji yi ṣe ìlérí pé kò si nkan ti yio ṣẹlẹ̀ ti àwon bá jẹ Igún, nitori eyi wọn fi ojú di èèwọ̀ ilú Ayégbẹgẹ́.

Igún - Vulture

Igún – Vulture

Miòṣé, lọ si oko, ó pa Igun, ó din láta, ó si jẹ́, ṣùgbọ́n ó pa adiẹ, ó da iyẹ́ adiẹ si ààtàn bi ẹni pé adiẹ ló jẹ.  Ọ̀pọ̀ ará ilú ti wọn mọ̀ pé èèwọ̀ ni lati jẹ Igún paapa, jẹ ninú rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mọ pé Igún ni àwọn jẹ, wọn rò wi pé adiẹ ni.  Miòṣé fi ọ̀rọ̀ àṣiri yi sinú lai si nkan ti ó ṣe gbogbo àwọn ti ó jẹ Igún pẹ̀lú rẹ.

Moṣétán lọ si oko ohun na a pa Igun, ó gbe wá si ilé, ṣùgbọ́n kò jẹ́.  Ó pa adiẹ dipò Igún, o din adiẹ ó jẹ ẹ, ṣùgbọ́n, ó da iyẹ́ Igún si ààtàn bi ẹni pé Igún lohun jẹ.  Ni ọjọ́ keji àwọn ará ilú ri iyẹ́ Igún wọn pariwo pé Moṣétán jẹ èèwọ̀, ó ni bẹni, ohun jẹ Igún.  Ni ọjọ́ kẹta inú Moṣétán bẹ̀rẹ̀ si i wú titi ara fi ni.  Nigbati ìnira pọ̀ fún Moṣétán, ó jẹ́wọ́ wi pé adiẹ lohun jẹ, ṣùgbọ́n wọn ko gba a gbọ pé kò jẹ Igun, titi ti ó fi ṣubú ti ó si kú. Yorùbá ni “Ẹnu Ayé Lẹbo”, Moṣétán fi ẹnu kó bá ara rẹ̀.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pé, àfojúdi kò dára, ó yẹ ki enia pa òfin mọ nitori “Bi a ti nṣe ni ilé wa, èèwọ̀ ibò miran”.  Ẹni ti kò bá pa òfin mọ, á wọ ijọ̀ngbọ̀n ti ó lè fa ikú tàbi ẹ̀wọ̀n.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-29 23:20:09. Republished by Blog Post Promoter

“Ìkà gbàgbé Àjọbi, adánilóró̀ gbàgbé ọ̀la, ẹ̀san á ké lóri òṣìkà” – “The wicked forgets same parentage, an evil doer forgets tomorrow, there is consequence for the wicked”.

Yorùbá ni ètò àti òfin ti àwọn Àgbà, Ọba àti Ìjòyè fi nto ilú ki aláwọ̀-funfun tó dé.  Onirúurú ọ̀nà ni wọn ma fi nṣe idájọ́ ìkà laarin àwùjọ.  Wọn lè fi orin tú àṣiri òṣìkà ni igbà ọdún ibilẹ, tàbi ki wọn fa irú ẹni bẹ ẹ si iwájú Àgbà idilé, Baálẹ̀ tàbi Ọba fún ìdájọ́ ti ó bá tọ́ si irú ẹni bẹ ẹ.  Lati agbo ilé dé ilé iwé àti àwùjọ ni  Yorùbá ti ma nlo òwe, ọ̀rọ̀ àti orin ṣe ikilọ fún ọmọdé àti àgbà pé ẹ̀san wà fún oniṣẹ ibi tàbi òṣìkà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Eléré àti Olórin, pàtàki àwọn Ọ̀gá ninú Eléré àti Olórin Yorùbá ni ó fi ẹ̀san òsìkà hàn ninú eré àti orin.  Ọ̀gá Eléré bi: Lere Paimọ, Olóògbe Kọla Ogunmọla, Olóògbe, Oloye Ogunde àti ọpọ ti a kò dárúkọ, àti àwọn ọ̀gá Olórin bi: Olóògbé, Olóyè I.K. Dairo, Oloogbe Adeolu Akinsanya (Baba Ètò), Olóyè (Olùdari) Ebenezer Obey, Olóògbe Orlando Owoh, Dele Ojo, Olóògbe Sikiru Ahinde Barrister àti ọ̀pọ̀ ti a kò dárúkọ nitori àyè.   Ẹ gbọ́ ikan ninú àwọn orin ikilọ fún òsìkà ti àwọn ọmọ ilé-iwé ma nkọ ni ojú ewé yi bi Olùkọ̀wé yi ti kọ:

Ṣìkà-ṣìkà gbàgbé àjọbí
Adániloró gbàgbé ọ̀la
Ẹ̀san á ké, á ké o
Ẹ̀san á ké lorí òsìkà
Ṣe rere ò, ko tó lọ ò.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-04 18:35:39. Republished by Blog Post Promoter