Ni ai pẹ yi, Olùkọ̀wé yi bẹ ilé wò fún bi ọ̀sẹ̀ mẹta. A ṣe àwọn akiyesi wọnyi. Ilú Èkó n fẹ̀ si, ṣùgbọ́n ọ̀nà kò fẹ̀ tó bi èrò àti ọkọ̀ ti pọ̀ tó, nitori eyi, sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki ará ilú gbádùn. Àwọn ti ó nlọ si ibi iṣẹ́ agogo mẹjọ ni lati kúrò ni ilé ki agogo marun tó lù, wọn yio si wọlé ni agogo mẹwa lẹhin ti wọn bá pari iṣẹ́ ni agogo marun. Ó kéré jù, òṣìṣẹ́ yio lo wákàtí mẹfa lati lọ àti bọ ni ibi iṣẹ́ nitori sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀.
Ìjọba ko ti i ṣe ìpèsè omi ẹ̀rọ, ọ̀nà àdúgbò àti ohun amáyédẹrùn igbàlódé pàtàki ni àwọn agbègbè tuntun. Iná mọ̀nàmọ́ná ti dára di ẹ̀ si, nitori iná kò lọ púpọ̀ mọ́ bi ti tẹ́lẹ̀.
Ni àwọn olú ilú ilẹ̀ Yorùbá yókù bi Ìbàdàn, Òṣogbo, Abẹ́òkúta, Àkúrẹ́ àti Adó-Èkìtì, kò si sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ bi ti Èkó ṣùgbọ́n iná mọ̀nàmọ́ná kò ṣe déédé bi ti ilú Èkó. Ọ̀wọ́n epo-ọkọ̀ ti ó gbòde ni igbà ọdún Kérésìmesì ti ó kọjá àti ni ibẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun ti lọ ṣùgbọ́n epo-ọkọ̀ wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé epo ni àwọn olú ilú yókù ju ti Èkó. Gbogbo ohun tita ló ti wọ́n si.
Ó ṣòro lati lo ayélujára nitori ai ṣe déédé iná mọ̀nàmọ́ná àti ayélujára, pàtàki bi enia ba jade kúrò ni ilú Èkó, ṣùgbọ́n ó sàn ju ti àtẹ̀hin wá lọ. Ni àpapọ̀, ọyẹ́ jẹ́ ki ẹni ti ó bá nti Òkè-Òkun bọ̀ gbádùn nitori ooru din kù.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2016-02-09 22:16:55. Republished by Blog Post Promoter