Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

Ìfẹ́ kò fọ́jú, ẹni ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú: ‘Igbéyàwó ki ṣe ọjà òkùnkùn’ – Love is not blind, it is the person falling in love that is blind”: Marriage is not ‘Black Market’

Ni ayé àtijọ́, ki òbí tó gbà lati fi ọmọ fún ọkọ, wọn yio ṣe iwadi irú iwà àti àìsàn ti ó wọ́pọ̀ ni irú idile bẹ́ ẹ̀.  Nitori eyi, igbéyàwó ibilẹ̀ ayé  àtijọ́ ma npẹ́ ju ti ayé òde òni.  Bi ọmọ obinrin bá nlọ si ilé ọkọ, ikan ninu ẹrù tó ṣe pàtàki ni ki wọn gbé “ẹni” fún dáni lati fi han pé kò si àyè fun ni ilé òbi rẹ mọ nitori ó  ti di ara kan pẹ̀lú ẹbi ọkọ rẹ.

Ọkùnrin fi ìfẹ́ han obinrin - Couple in love

Ọkùnrin fi ìfẹ́ han obinrin – Couple in love

Ni idà keji, obinrin ayé òde òni, kò dúró ki òbí ṣe iwadi rara, pàtàki bi wọn bá pàdé ni ilú nla ti èrò lati oriṣiriṣi ẹ̀yà pọ̀ si tàbi ni ilé-iwé.  Ọkùnrin ri obinrin, wọn fi ìfẹ́ han si ara wọn, ó pari, ọ̀pọ̀ ki ṣe iwadi lati wo ohun ti àgbà tàbi òbí nwò ki wọn tó ṣe igbéyàwó.  Obinrin ti lè lóyún ki òbí tó gbọ́ tàbi ki wọn tó lọ si ilé Ìjọ́sìn lati ṣe ètò igbéyàwó.  Àwọn miran nkánjú, wọn kò lè dúró gba imọ̀ràn.  Irú imọ̀ràn wo ni òbí tàbi Alufa fẹ́ fún ọkùnrin àti obinrin bẹ́ ẹ̀?

 

Ki ṣe “ìfẹ́ ló fọ́jú”, ṣùgbọ́n “àwọn ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú” nitori, bi obinrin tàbi ọkùnrin miran bá ti ri owó, ẹwà, ipò agbára, wọn á dijú si àlébù miran ti ó wà lára ẹni ti wọn fẹ́ fẹ́.   Igbéyàwó ki ṣe ọjà̀ òkùnkùn, ṣùgbọ́n àwọn ti ó nwọ̀ ọ́ ni ó dijú, nitori nigbati àlébù ti wọn dijú si bá bẹ̀rẹ̀ si jade lẹhin igbéyàwó, igbéyàwó á túká.

Ki ṣe “ìfẹ́ ló fọ́jú”, ṣùgbọ́n “àwọn ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú” nitori, bi obinrin tàbi ọkùnrin miran bá ti ri owó, ẹwà, ipò agbára, wọn á dijú si àlébù miran ti ó wà lára ẹni ti wọn fẹ́ fẹ́.   Igbéyàwó ki ṣe ọjà̀ òkùnkùn, ṣùgbọ́n àwọn ti ó nwọ̀ ọ́ ni ó dijú, nitori nigbati àlébù ti wọn dijú si bá bẹ̀rẹ̀ si jade lẹhin igbéyàwó, igbéyàwó á túká.

Ìmọ̀ràn fún ọkùnrin àti obinrin ti ó nronú lati ṣe igbéyàwó ni ki wọn lajú, ki wọn si farabalẹ̀ ṣe iwadi irú iwa ti wọn lè gbà lati fi bára gbé lai wo ohun ayé bi ẹwà, owó àti ipò nitori ìwà ló ṣe kókó jù fún igbéyàwó ti yio di alẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-01-06 09:00:19. Republished by Blog Post Promoter

“Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì” – “There is no respect for a King that has no Queen”

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Bi ọmọdé bá tó ni ọkọ́, à fún lọ́kọ́”.  Ọkọ́ jẹ irinṣẹ́ pàtàki fún Àgbẹ̀.  Iṣẹ́-àgbẹ̀ ni ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́. Nitori eyi, bi bàbá ti nkọ́ ọmọ rẹ ọkùnrin ni iṣẹ-àgbẹ̀, ni ìyá nkọ́ ọmọ obinrin rẹ ni ìtọ́jú-ile lati kọ fún ilé-ọkọ.  Iṣẹ́ la fi nmọ ọmọ ọkùnrin, nitori eyi, bi ọkùnrin bá dàgbà, bàbá rẹ á fun ni ọkọ́ nitori ki ó lè dá dúró lati lè ṣe iṣẹ́ ti yio fi bọ́ ẹbi rẹ ni ọjọ́ iwájú.

Bi ọkùnrin bá ni iṣẹ́, ó ku kó gbéyàwó ti yio jẹ “Olorì” ni ilé rẹ.  Ìyàwó fi fẹ́ bu iyi kún ọkùnrin, nitori, ó fi hàn pé ó ni igbẹ́kẹ̀lé.  Àṣà Yorùbá gbà fún ọkùnrin lati fẹ́ iye ìyàwó ti agbára rẹ bá gbé lati tọ́jú.  Nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọba, Baálẹ̀, Ìjòyè àti àwọn enia pàtàki láwùjọ ma nfẹ ìyàwó púpọ̀.  Ìṣòro ni ki wọn fi ọkùnrin ti kò ni ìyàwó jẹ Ọba.  Kò wọ́pọ̀ ki Ọba ni ìyàwó kan ṣoṣo.

Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyi Adeṣida - Coronation of the Late Deji of Akure.

Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyi Adeṣida – Coronation of the Late Deji of Akure.

Ohun ti a ṣe akiyesi ni ayé òde òni, ni Ọba ti ó fẹ ìyàwó kan ṣoṣo nitori ẹ̀sìn, pàtàki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ti ó ni àlè rẹpẹtẹ.  Ọba ayé òde òni ndá nikan lọ si òde lai mú Olorì dáni.  Gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Yorùbá, “Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì”, nitori eyi, kò bu iyi kún Ọba, ki ó lọ àwùjó tàbi rin irin àjò pàtàki lai mú Olorì dáni.  Ohun ti ó yẹ Ọba ni ki a ri Ọba àti Olorì rẹ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ.

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-11 19:13:42. Republished by Blog Post Promoter

Àjàpá àti Ìyá Alákàrà – “Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun” – The Tortoise and the fried bean fritter seller – “Every day is for the thief, one day for the owner”.

Ìpolówó Àkàrà              Hawker’s advert

Àkàrà gbóná re,              Here comes hot fried bean fritters
Ẹ bámi ra àkàrà o           Buy my fried bean fritters
Àkàrà yi dùn, ó lóyin       This fried bean fritters is sweet with honey
Àkàrà gbóná re.              Here comes hot fried bean fritters

Àkàrà jẹ ikan ninu ounjẹ aládùn ilẹ̀ Yorùbá.  Ẹ̀wà (funfun tabi pupa) ni wọn fi nṣe àkàrà, wọn a bo ẹ̀wà, wọn a lọ, ki wọn to põ pẹ̀lú èlò ki wọn tó din.  A lè fi àkàrà jẹ ẹ̀ko, fi mu gaàrí tabi jẹ fún ìpanu.  Ki ṣe gbogbo enia ló mọ àkàrà din, awọn enia ma nfẹran ẹni ti ó ba mọ àkàrà din.  Àti ọmọdé àti àgbà ló fẹ́rán àkàrà.   Awọn ọmọde ma nkọrin bayi:

 

Taló pe ìyá alákàrà ṣeré,         Who is calling fried bean fritters woman for fun
Ìyá alákàrà 2ce                        Fried bean fritters seller
Ó nta sánsán simi nímú          Its smell is inviting to my nose
Ìyá alákàrà                              Fried bean fritters seller
Ó nta dòdò sími lọ̀fun             Its smelling like fried plantain in my throat
Ìyá alákàrà.                             Fried bean fritters seller

Ki ṣe enia nikan ló fẹ́ràn àkàrà, Àjàpá naa fẹ́ràn àkàrà, ṣùgbọ́n kò ri owó raa, nitori èyi “Ojú ni Àjàpá fi nri àkàrà, ètè rẹ ko baa”.  Àjàpá wá ronú ọgbọ́n ti ó lè dá lati pèsè àkàrà fún òhun àti idilé rẹ.  Ó ronú bi wọn ti lè dá ẹ̀rù ba ọmọ alákàrà ki ó lè sá fi igbá àkàrà, rẹ silẹ̀.  Ó gbé agọ̀ wọ̀, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ fi pápá́ bora.  Bi alákàrà ba ti kiri kọjá, Àjàpá a bẹ si iwájú ọmọ alákàrà, wọn a ma ko orin bayi:

 

 

Ọlirae ma gbọ̀nà,      The Spirit has taken over the Road
Tobini tobini to 2ce   Tobini, tobini to
Olóri yara lọ,              Corn meal seller go quickly
Tobini tobini to          Tobini, tobini to
Alákàrà dá dànù        Fried bean fritter seller abandon it
Tobini tobini to.         Tobini, tobini to

Ẹ̀rù ba alákàrà, á da àkàrà dà nù.  Àjàpá àti ẹbí rẹ á bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà. Yorùbá ni “Wọ́n mú olè lẹẹkan, ó ni ohun ò wá ri, tani fi ọ̀nà han olè?”.  Ọmọ alákàrà sunkún lọ si ilé, inú Ìya-alákàrà kò dùn si ọmọ rẹ nitori o pàdánù àkàrà àti owó ti o yẹ ki ó pa.  Kò gba ìtàn ọmọ rẹ̀ gbọ́, nitorina, ó gbé àkàrà fún ni ọjọ́ keji ati ọjọ́ kẹta, ọmọ tún padà pẹ̀lú ẹkún.  Ohun fúnra rẹ̀ tẹ̀lé ọmọ rẹ̀, iwin tún yọjú, àwọn mejeeji sá eré padà si ìlú lai ranti gbé igbá àkàrà.  Ìyá alákàrà gba ọ̀dọ̀ Ọba àti àgbà ìlú lọ lati sọ ohun ti ojú wọn ri.  Ọba pe awọn òrìṣà ìlú lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ba ọrọ̀ ìlú jẹ yi.  Ninu gbogbo òrìsà, Ọ̀sanyìn nikan ló gbà lati yanjú ọ̀rọ̀ yi.

Ìyá alákàrà tungbe àkàrà fún ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun àti Ọsanyin tẹ̀lé.  Bi alákà̀rà ti bẹ̀rẹ̀ si polówó, Àjàpá tún jade gẹgẹ bi iṣe rẹ̀.  Yoruba ni “Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun”.  Ìyá alákàrà àti ọmọ rẹ̀ tún méré, ṣùgbọ́n Ọ̀sanyin ti o fi ara pamọ́ dúró lati wo ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀.  Àjàpá àti àwon idile rẹ̀ jade nwọn bọ ohun ti nwọn fi bora silẹ̀ lati tún bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà.  Orí ti Àjàpá yọ jade lati jẹ àkàrà, Ọ̀sanyin fọ igi ẹlẹgun mọ lórí, awọn ẹbi rẹ̀ sálọ.  Ọ̀sanyin gbé òkú Àjàpá lọ si ọ̀dọ̀ Ọba.  Inú ará ìlú dùn nitori àṣiri olè tú.  Ọba pàṣẹ pe Àjàpá ni ki nwọn bẹrẹ fi rúbọ si Ọ̀sanyin.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe ojúkòkòrò kò lérè, bó pẹ́, bóyá àṣírí olè á tú.  Ikú lèrè ẹ̀ṣẹ̀ – Àjàpá pàdánù ẹ̀mí nitori àkàrà.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-04-11 21:40:58. Republished by Blog Post Promoter

Obinrin kò ṣe e jánípò si ìdí Àdìrò nikan, Obinrin ló ni gbogbo Ilé – Women cannot be relegated to the kitchen, women are in charge of the entire home

Ìtàn fi yé wa wi pé Yorùbá ka ọ̀rọ̀ obinrin si ni àṣà Yorùbá  bi ó ti ẹ jẹ wi pé obinrin ki jẹ Ọba nitori ni àṣà ilú, ọkunrin ló njẹ olóri.  Obinrin kò pọ̀ ni ipò agbára.  Àwọn ipò obinrin ni ‘Ìyáálé’, eyi jẹ́ iyàwó àgbà tàbi iyàwó àkọ́fẹ́ ninú ẹbí, pàtàki ni ilé o ni iyàwó púpọ̀ ṣùgbọ́n ọkùnrin ni ‘olóri ẹbí’.  Ipò obinrin kò pin si idi àdìrò àti inú ilé yókù gẹ́gẹ́ bi Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari ti sọ.

Obinrin Yorùbá ti ni àyè lati ṣe iṣẹ́ ti pẹ́, bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wi pé àwọn iṣẹ́ obinrin bi oúnjẹ ṣí ṣe, ẹní hí hun, aṣọ hí hun, aró ṣi ṣe, òwú gbi gbọ̀n, ọjà ti tà (ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé díẹ̀), oúnjẹ sí sè àti itọ́jú ẹbi ni obinrin nṣe.  Àwọn ọkùnrin nṣe iṣẹ́ agbára bi iṣẹ́ ọdẹ, alágbẹ̀dẹ, àgbẹ̀ tàbi iṣẹ́ oko (iṣẹ́ fún ji jẹ àti mimu ẹbí).  Obinrin ni ògúná gbongbo ni oníṣòwò òkèèrè, eyi jẹ ki obinrin lè ni ọrọ̀ àti lati lè gba oyè ‘Ìyálóde’.  Fún àpẹrẹ, àwọn Ìyálóde ni ó njẹ Olóri ọjà ni gbogo ilẹ̀ Yorùbá àti alá-bójútó fún ọ̀rọ̀ obinrin.

Gẹ́gẹ́ bi àṣà ibilẹ̀ Yorùbá, àwọn ọkùnrin gbà ki iyàwó  wọn ṣe iṣẹ́ lati ran ẹbí lọ́wọ́, eyi lè jẹ́ nitori àwọn ọkùnrin ni iyàwó púpọ̀, nitori èyi, kò nira bi iyàwó kan tàbi méji bá lọ ṣòwò ni òkèèrè, àwọn iyàwó yókù yio bójú tó ilé.   Àṣà òkè-òkun fi fẹ́ iyàwó  kan àti ẹ̀sìn òkèère ti Yorùbá gbà ló sọ àdìrò di ipò fún obinrin àti “Alá-bọ́dó, Ìyàwóilé tàbi Oníṣẹ́-ilé” ti ó di iṣẹ́ obinrin.  Obinrin ayé òde òní kàwé, ṣùgbọ́n bi wọn kò ti ẹ kàwé, gbogbo ẹni ti ó bá ni làákàyè fún àṣà, kò gbọdọ̀ já obinrin si ipò kankan ni ilé nitori obinrin ló ni gbogbo ilé.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-10-25 21:42:34. Republished by Blog Post Promoter

“Odò ti ó bá gbàgbé orisun gbi gbẹ ló ngbẹ” – “A river that forgets its source will eventually dry up”

Orúkọ idile Yorùbá ti ó nparẹ́ nitori èsìn.  Àwọn orúkọ ìdílé wọnyi kò di ẹlẹ́sìn lọ́wọ́ lati ṣe iṣẹ́ rere tàbi dé ọ̀run,

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba family names that are disappearing.  These traditional names should not be seen as obstacles by religious ones to doing good work or getting to heaven.

ÒGÚN – god of iron, war and justice

Orúkọ idile Yorùbá Orúkọ igbàlódé ti ó dipò orúkọ ibilẹ̀ English/Literal meaning – IFA –Yoruba Religion
Adéògún Ogun’s crown
Ògúnadé Ogun in the crown
Ògúnbámbi Olúbambi
Ògúnbiyi Olubiyi/Biyi Ogun/God gave birth to this
Ògúnbùnmi Olúbùnmi/Bunmi Ogun/God gave me
Ògúnbọ̀wálé Adébọ̀wálé/Débọ̀
Ògúndàmọ́lá Adédàmọ́lá/Dàmọ́lá Ogun/Crown mixed with wealth
Ògúndiyimú/Ògúndimú
Ògúǹdé/Ògúnrindé Ogun has arrived
Ògúndélé Ọládélé/Délé Ogun came home
Ògúndèyi Ogun has become this
Ògúnfúnmi/Ògúnbùnfúnmi Olúwáfúnmi/Fúnmi Ogun gave me
Ògúngbadé Olúgbadé/Gbadé Ogun received the crown
Ògúngbèjà Olúgbèjà Ogun/God defends
Ògúnkọ̀yà Olúkọ̀yà/Kọ̀yà Ogun/God rejected suffering
Ogunlade Olulade
Ògúnlàjà Olulaja/Laja Ogun/God separated a fight
Ògúnlànà Olúlànà Ogun/God paved the way
Ògúnlékè Ọlálékè/Lékè Ogun/God prevailed
Ògúnléndé Ogun pursued me here
Ògúnlẹyẹ Olulẹyẹ/Lẹyẹ Ogun/God is honourable
Ògúnmọ́dẹdé Olúmọ́dẹdé Ogun/God made the hunter to arrive
Ògúnmọ́lá Olumola Ogun/God plus wealth
Ògúnmuyiwa Olúmuyiwa/Muyiwa Ogun/God brought this
Ògúnpọ́nlé/Ògúnpọ́nmilé Olúpọ́nlé/Pọ́nlé Ogun/God honoured me
Ògúnrẹ̀milẹ́kún Oluwarẹmilẹkun/Rẹmi Ogun/God consoled me
Ògúnrọ̀gbà Adérọ̀gbà Ogun/Crown has eased time
Ògúnsànyà Olúsànyà/Sànyà Ogun/God repay suffering
Ògúnṣẹ̀san Olúṣẹsan/Ṣẹ̀san Ogun/God compensate
Ògúnṣinà Olúṣinà/Ṣina Ogun/God opened the way
Ògúnṣọlá Olúṣọlá/Ṣọlá Ogun/God created wealth
Ògúnṣuyi Ọláṣuyi/Ṣuyi Ogun/God created honour
Ògúntóbi Oluwatóbi Ogun/God is great
Ògúntọ́ba Olútọ̀ba Ogun/God is equal to the King
Ògúntólú Adétólú Ogun/Crown is equal to the gods
Ògúntọ́lá Olútọ́lá Ogun/God is equal to wealth
Ògúntọ̀nà Adétọ̀nà Ogun/God leads the way
Ògúntoyinbo Ogun is equal to the white man
Ogunye Ogun survived
Ògúnyẹmi Olúyẹmi/Yẹmi Ogun suits me
Share Button

Originally posted 2016-04-05 11:47:25. Republished by Blog Post Promoter

“Ìkà gbàgbé Àjọbi, adánilóró̀ gbàgbé ọ̀la, ẹ̀san á ké lóri òṣìkà” – “The wicked forgets same parentage, an evil doer forgets tomorrow, there is consequence for the wicked”.

Yorùbá ni ètò àti òfin ti àwọn Àgbà, Ọba àti Ìjòyè fi nto ilú ki aláwọ̀-funfun tó dé.  Onirúurú ọ̀nà ni wọn ma fi nṣe idájọ́ ìkà laarin àwùjọ.  Wọn lè fi orin tú àṣiri òṣìkà ni igbà ọdún ibilẹ, tàbi ki wọn fa irú ẹni bẹ ẹ si iwájú Àgbà idilé, Baálẹ̀ tàbi Ọba fún ìdájọ́ ti ó bá tọ́ si irú ẹni bẹ ẹ.  Lati agbo ilé dé ilé iwé àti àwùjọ ni  Yorùbá ti ma nlo òwe, ọ̀rọ̀ àti orin ṣe ikilọ fún ọmọdé àti àgbà pé ẹ̀san wà fún oniṣẹ ibi tàbi òṣìkà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Eléré àti Olórin, pàtàki àwọn Ọ̀gá ninú Eléré àti Olórin Yorùbá ni ó fi ẹ̀san òsìkà hàn ninú eré àti orin.  Ọ̀gá Eléré bi: Lere Paimọ, Olóògbe Kọla Ogunmọla, Olóògbe, Oloye Ogunde àti ọpọ ti a kò dárúkọ, àti àwọn ọ̀gá Olórin bi: Olóògbé, Olóyè I.K. Dairo, Oloogbe Adeolu Akinsanya (Baba Ètò), Olóyè (Olùdari) Ebenezer Obey, Olóògbe Orlando Owoh, Dele Ojo, Olóògbe Sikiru Ahinde Barrister àti ọ̀pọ̀ ti a kò dárúkọ nitori àyè.   Ẹ gbọ́ ikan ninú àwọn orin ikilọ fún òsìkà ti àwọn ọmọ ilé-iwé ma nkọ ni ojú ewé yi bi Olùkọ̀wé yi ti kọ:

Ṣìkà-ṣìkà gbàgbé àjọbí
Adániloró gbàgbé ọ̀la
Ẹ̀san á ké, á ké o
Ẹ̀san á ké lorí òsìkà
Ṣe rere ò, ko tó lọ ò.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-04 18:35:39. Republished by Blog Post Promoter

ỌRỌ ÌYÀNJÙ (WORD OF ADVICE): Ẹni tólèdè lóni ayé ibi ti wọn ti nsọ

R ÌYÀNJÙ (WORD OF ADVICE)

Ẹyin ọmọ Odùduwà ẹjẹ ki a ran rawa létí wípé “Ẹni tólèdè lóni ayé ibi ti wọn ti nsọ”.  Mo bẹ yin  ẹ maṣe jẹki  a tara wa  lọpọ nitorina ẹ maṣe jẹki èdè Yorùbà parẹ. Èdè ti a kọ silẹ, ti a ko sọ, ti a ko fi kọ ọmọ wa, piparẹ ni yio parẹ.  Ẹjẹ ki a gbiyanju lati ṣe atunṣe nipa sísọ èdè Yorùbà botiyẹ kasọ lai si idaru idapọ pẹlu  èdè miran.

Yorùbá lọkunrin ati lobirin ẹ ranti wipe “Odò to ba gbagbe orisun rẹ, gbigbe lo ma ngbe”   Lágbára Ọlọrun, aoni tajo sọnu sajo o, ao kere oko délé o (Àṣẹ).

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-01-31 20:18:56. Republished by Blog Post Promoter

Àwòrán ati Orúkọ àwọn Ẹiyẹ ni èdè Yorùbá – Pictures and names of Birds in Youruba

 

 

 

Share Button

Originally posted 2014-10-17 13:00:55. Republished by Blog Post Promoter

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú/burúkú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa” – Plantain – “Unripe/rotten plantain is no easy snack, beating a bad behaved child to death is not an option”.

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ – Bunch of unripe Plantains and Bananas Banana

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ – Bunch of unripe Plantains and Bananas Banana

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ èso ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ohun ọgbin ti a lè ri ni ilẹ̀ Yorùbá pàtàki ni agbègbè Okitipupa ni ipinlẹ Ondo.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ pé oriṣiriṣi, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ni à nsè fun jijẹ, nigbati ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ dára fún jijẹ bi èso lai sè.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tóbi ju ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ lọ.

Ọkọ̀ tó kó Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – Lorry load of Plantain. Courtesy: theyorubablog

Ọkọ̀ tó kó Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – Lorry load of Plantain. Courtesy: theyorubablog

Ni ayé àtijọ́, ohun ọgbin ti ó bá pọ̀ ni agbègbè ni èniyàn ma njẹ, nitori ko si ọkọ̀ tàbi ohun irinna tó yá  lati kó irè oko kan lọ si ekeji.  Eleyi jẹ ki àwọn ti iṣu pọ ni ọ̀dọ̀ wọn lo iṣu lati ṣe oúnjẹ ni oriṣiriṣi ọ̀nà, àwọn ti o ni àgbàdo pupọ nlo fún onírúurú oúnjẹ ti a lè fi àgbàdo ṣe, àwọn ti ó ni ẹ̀gẹ́/gbaguda ma nlo lati ṣe oriṣiriṣi oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìyàtọ laarin iṣu ati ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni pé, wọn wa iṣu ninú ebè nigbati wọn nbẹ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ lóri igi rẹ.  Kò si iyàtọ̀ laarin Èlùbọ́ iṣu àti Èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀, ṣugbon bi a bá ro fun àmàlà, àmàlà iṣu dúdú díẹ ju èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ gbigbẹ, àmàlà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ tútù kò dúdú ó pọ́n fẹ́rẹ́fẹ́.  Iṣu tútù kò ṣe e bùṣán nitori yio yún èniyàn ni ọ̀fun, nibi ti ó burú dé, bi omi ti wọn fi fọ iṣu bá ta si ni lára, yio fa ara yin yún. Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá ti ó ni “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú/burúkú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa”, ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú kò dùn lati jẹ ni tútù, eyi ti ó bá ti kẹ̀ naa kò ṣe é jẹ, ṣùgbọ́n ọ̀gẹ̀dẹ̀ ti ó pọ́n ṣe jẹ ni pi pọ́n lai sè nitori adùn rẹ.  Àti ewé àti èso ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ó wúlò fún jijẹ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-02 19:09:48. Republished by Blog Post Promoter

“Bi a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” – “If one lives long enough, one will consume as much meat as an elephant”

Erin - Elephant

Erin – Elephant

Erin jẹ ẹran ti ó tóbi ju gbogbo ẹranko ti a mọ̀ si ẹran inú igbó àti ẹran-àmúsìn, ti a mọ̀ ni ayé òde òni.  Bi a bá ṣe àyẹ̀wò bi Yorùbá ti ńgé ẹran ọbẹ̀, ó ṣòro lati ro oye ẹran ti enia yio jẹ ki ó tó Erin.

Isọ̀  Eran – Meat Stall. Courtesy: @theyorubablog

 

 

 

 

Bawo ni òwe Yorùbá ti ó ni “Bi  a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” ti wúlò fún ẹni ti ki jẹ ẹran ti a mọ̀ si “Ajẹ̀fọ́”?  Àti Ajẹ̀fọ́ àti Ajẹran ni òwe yi ṣe gbà ni iyànjú pé “Ohun ti kò tó, ḿbọ̀ wá ṣẹ́ kù”. Fún àpẹrẹ, bi enia bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nibi kékeré, bi ó bá tẹramọ́, yi o di ọ̀gá, yio si lè ṣe ohun ti ẹgbẹ́ rẹ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ibi giga ṣe.  Bi enia bá ni oreọ̀fẹ́ lati pẹ́ láyé, ti ó dúró tàbi ni sùúrù, yio ri pé ohun jẹ ẹran ti ó tó Erin.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-12 18:29:05. Republished by Blog Post Promoter