Ìnáwó rẹpẹtẹ ni ìsìnkú arúgbó jẹ́ ni ilé Yorùbá. Bi arúgbó bá kú ni ilé Yorùbá ki ṣe òkú ọ̀fọ̀ ṣùgbọ́n òkú ijọ àti ji jẹ, mi mu ni pàtàki bi irú arúgbó bá bi àwọn ọmọ ti ó ti dàgbà. Gbogbo ẹbi, ará àti ilú yi ó parapọ̀ lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún irú arúgbó bẹ́ ẹ̀. Àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ yi o ṣe oriṣiriṣi ẹ̀yẹ ìbílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ lati gbé ìyá tàbi àgbà bàbá àgbà relé. Bi eléré ìbílẹ̀ kan ti nlọ ni òmíràn yio de, eleyi lo njẹ́ ki ilú kékeré dùn.
A o ṣe àpẹrẹ àṣà ìsìnkú ìbílẹ̀ fún arúgbó pẹ̀lú ni Ìbòròpa Àkókó ilú Yorùbá ni ẹ̀gbẹ́ Ìkàrẹ́-Àkókó ti Ipinle Ondo, orile-ede Nigeria.
ENGLISH TRANSLATION
Burial of the old one is often an expensive affair In Yoruba land. When an old person dies, it is not mournful, but of celebration marked with dancing and feasting particularly when the old person is survived by successful grown up children. All the families, contemporaries and the entire community often join hands to perform the last rites for such old person. The children and grand-children would join hands in the performance of several days’ traditional burial ceremonies held to give the deceased old mother or father a befitting last rites. As one traditional performer is departing another one is replacing, this is a contributory factor to the fun enjoyed in the smaller Yoruba communities.
Video recording example of traditional burial of the elderly held in Iboropa Akoko, a small town near Ikare-Akoko, Ondo State, Nigeria are here below.
Originally posted 2017-05-19 23:07:52. Republished by Blog Post Promoter