Gẹ́gẹ́ bi a ti kọ tẹ́lẹ̀, ẹrù àti owó àna yàtọ̀ lati idilé kan si ekeji, ṣùgbọ́n àwọn ohun àdúrà bára mu ni ilẹ̀ Yorùbá pàtàki Oyin, Obi, Ataare, Orógbó. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbi Yorùbá, ogoji ni oye àwọn ẹrù bi Obi, Orógbó, Ataare, Ẹja-gbígbẹ àti Iṣu ti idile ma ngba. Olóri ẹbi lè din oye ẹrù ku lati din ìnáwó ọkọ iyàwó kù. Lẹhin igbéyàwó ibilẹ̀, wọn yio pin ẹrù yi (yàtọ̀ si ẹrù fún Iyàwó), si ọ̀nà meji lati kó apá kan àti apá keji fún Idilé Bàbá àti Ìyá Iyàwó. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ ẹrú ati owó àna fún Idilé Arinmájàgbẹ̀ ni Ìbòròpa-Àkókó, Ipinlẹ̀ Ondó ni ojú iwé yi.
Yorùbá /English Translation
Ẹrù Àdúrà Ìwọ̀n Traditional Prayer items/Quantity
Ataare Ogún Alligator Pepper 20
Obi Àbàtà Ogún Traditional Kolanut 20
Obi Gbànja Ogún Kolanut 20
Orógbó Ogún Bitter Kola 20
Ẹja gbigbẹ Abori Ẹyọ Meji Dry Fish 02
Oyin Ìgò Meji Honey 02 Bottles
Iyọ̀ ìrèké Páálí Meji Sugar 02 pkts
Apẹ̀rẹ̀ ti a pin àwọn èso oriṣiriṣi wọnyi si: Baskets of assorted fruits
Àgbọn Mẹjọ Cocoanut 08
Ọ̀gẹ̀dẹ̀-wẹ́wẹ́ Ẹ̀ya Meji Banana 02 Bunches
Òrombó/Ọsàn Méjìlá Oranges 12
Ọ̀pẹ̀-òyinbó Méjì Pineapple 02
Àwọn Oún ji jẹ: Food Items
Epo-pupa Garawa kan Palm Oil 01 Keg (25kg)
Iyọ̀ Àpò Kan Salt 01 Bag
Iṣu Ogóji Yam 40 Tubers
Abo Ewúrẹ́ kékeré Ẹyọ kan She Goat 01
Àkàrà òyinbó Páálí nla Meji Biscuits/Cookies 02 Cartons
Ohun Mimu/Ọti Òyinbó; Assorted Local and foreign Drinks
Ọti Àdúrà Ìgò Meji Local Gin 02 Bottles
Ọti Ṣẹ̀kẹ̀tẹ́ Garawa Meji Local Malt 02 Keg (25ltr)
Ẹmu-ọ̀pẹ Garawa Meji Palm Wine 02 Keg (25ltr)
Ọti Òyinbó Páálí nla Meji Gulder 02 Cartons
Ọti Òyinbó Páálí Meji Stout 02 Cartons
Omi aládùn Páálí Meji Mineral/Soft Drink 02 Cartons/Crate
Ẹrù Iyàwó Items for the Bride
Àpóti Aṣọ kan 01 Suitcase of Assorted Clothes
Bibeli kan 01 Bible
Agboòrùn kan 01 Umbrella
Àpò Owó Money: Envelopes for
Owó Ìyá-gbọ́ Bride’s Mother’s consent
Owó Bàbá gbọ́ Bride’s Father’s consent
Owó Ọmọ ilé Children
Owó Ìyàwó ilé Wives
Owó Ẹpọnsi Bride’s Elder Sisters
ENGLISH TRANSLATION
As written earlier, Yoruba traditional marriage gift lists from the Groom’s family to the Bride’s family differ from one family to the other, but the items for prayers such as Honey, Kola, Alligator Pepper, Bitter-kola are common to all. For many Yoruba families, the number of items collected such as Kola, Bitter-kola, Alligator Pepper, Dry Fish and Yam are forty. The Paternal Head of the Bride’s family can use his initiative to limit the items on the list in order to reduce the Groom’s expenses. After the ceremony, the items are shared equally between the Bride’s Paternal and Maternal family with exception of the items for the Bride. Check below a sample of Traditional Bridal List from Arinmajagbe family of Iboropa-Akoko, Ondo State.
Originally posted 2015-08-28 19:37:22. Republished by Blog Post Promoter