A ki yin lati Ilé – Greetings from Home

Ni ai pẹ yi, Olùkọ̀wé yi bẹ ilé wò fún bi ọ̀sẹ̀ mẹta.  A ṣe àwọn akiyesi wọnyi.  Ilú Èkó n fẹ̀ si, ṣùgbọ́n ọ̀nà kò fẹ̀ tó bi èrò àti ọkọ̀ ti pọ̀ tó, nitori eyi, sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki ará ilú gbádùn.  Àwọn ti ó nlọ si ibi iṣẹ́ agogo mẹjọ ni lati kúrò ni ilé ki agogo marun tó lù, wọn yio si wọlé ni agogo mẹwa lẹhin ti wọn bá pari iṣẹ́ ni agogo marun.  Ó kéré jù, òṣìṣẹ́ yio lo wákàtí mẹfa lati lọ àti bọ ni ibi iṣẹ́ nitori sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀.

Sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ - Traffic Jam.  Cpurtesy: @theyorubablog

Sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ – Traffic Jam. Cpurtesy: @theyorubablog

Ìjọba ko ti i ṣe ìpèsè omi ẹ̀rọ, ọ̀nà àdúgbò àti ohun amáyédẹrùn igbàlódé pàtàki ni àwọn agbègbè tuntun.  Iná mọ̀nàmọ́ná ti dára di ẹ̀ si, nitori iná kò lọ púpọ̀ mọ́ bi ti tẹ́lẹ̀.

Ni àwọn olú ilú ilẹ̀ Yorùbá yókù bi Ìbàdàn, Òṣogbo, Abẹ́òkúta, Àkúrẹ́ àti Adó-Èkìtì, kò si sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ bi ti Èkó ṣùgbọ́n iná mọ̀nàmọ́ná kò ṣe déédé bi ti ilú Èkó.  Ọ̀wọ́n epo-ọkọ̀ ti ó gbòde ni igbà ọdún Kérésìmesì ti ó kọjá àti ni ibẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun ti lọ ṣùgbọ́n epo-ọkọ̀ wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé epo ni àwọn olú ilú yókù ju ti Èkó.  Gbogbo ohun tita ló ti wọ́n si.

Ó ṣòro lati lo ayélujára nitori ai ṣe déédé iná mọ̀nàmọ́ná àti ayélujára, pàtàki bi enia ba jade kúrò ni ilú Èkó, ṣùgbọ́n ó sàn ju ti àtẹ̀hin wá lọ.  Ni àpapọ̀, ọyẹ́ jẹ́ ki ẹni ti ó bá nti Òkè-Òkun bọ̀ gbádùn nitori ooru din kù.

ENGLISH TRANSLATION

Recently, this writer visited home for about three weeks.  Some observations were made.  Lagos has been expanding in terms of population and vehicular movement at a faster rate than the provision of road infrastructure, hence, heavy traffic has made life difficult for commuters.   Workers have to leave home before five o’clock in the morning for a resumption at eight o’clock and they get home at about ten o’clock at night after closing from work at about five o’clock in the evening.  On average workers spend at least six hours commuting as a result of the traffic jam.

Government has not lived up to expectation in the provision portable water, neighbourhood roads and modern infrastructure particularly in new development areas.  Electricity supply has improved slightly as power cuts has reduced than in the previous period.

In other Yoruba capital cities like Ibadan, Osogbo, Abeokuta, Akure and Ado-Ekiti, there is no traffic grid lock like in Lagos but electricity supply is not as regular as in Lagos.  The scarcity of petrol/gasoline that was prevalent during Christmas and in the early part of the year has abated but pump price is higher in other cities than Lagos.  Most consumer products has become more expensive.

Access to internet use is slow and irregular because of power cuts and availability of internet service, particularly outside Lagos, though it is still slow but it has improved than in the past.  In all, the cold spell (harmattan) has made it bearable for those visiting from Oversea as it reduced the heat wave.

Share Button

Originally posted 2016-02-09 22:16:55. Republished by Blog Post Promoter

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.