Yorùbá fẹ́ràn àlejò púpọ̀. Ìwà ti ọmọ ilú lè hù ti yio fa ibinú, bi àlejò bá hu irú ìwà bẹ́ ẹ̀, wọn yio ni àlejò ni, ki wọn fori ji i. Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Ojú àlejò ni a ti njẹ igbèsè, ẹhin rẹ la nsaán”. Eyi fi hàn bi Yorùbá ti fẹ́ràn lati ma ṣe àlejò tó.
Ìbàdàn ni olú-ilú ipinlẹ̀ Yorùbá ni Ìwọ̀-Oorun Nigeria tẹ́lẹ̀ ki Ìjọba Ológun ti Aguiyi Ironsi ti jẹ Olóri tó kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria pọ si aarin lẹhin ti wọn fi ibọn gba Ìjọba lọ́wọ́ Òṣèlú ni aadọta ọdún sẹhin. Lẹhin oṣù keje ni aadọta ọdún sẹhin, àwọn Ológun fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji. Ti àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nigbati wọn fi ibọn lé àwọn Òṣèlú àkọ́kọ́ lẹhin òmìnira kúrò ni ọjọ́ karùndinlógún, oṣù kini ọdún Ẹdẹgbaalemẹrindinlaadọrin. Lẹhin oṣù meje, àwọn Ológun tún fi ibọn gbà Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Ológun ti wọn fi ibọn gbé wọlé ti Aguiyi Ironsi jẹ olóri rẹ. Lára Ìjọba Ológun àkọ́kọ ti Ọ̀gágun Aguiyi Ironsi ti jẹ́ Olóri Ìjọba ni wọn ti fi Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi jẹ Olóri ni ipinlẹ̀ Yorùbá dipò Òṣèlú Ládòkè Akintọ́lá ti àwọn Ológun pa.
Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi gba Olóri-ogun Aguiyi Ironsi ni àlejò ni ibùgbé Ìjọba ni Ìbàdàn nigbati àwọn Ológun dé lati fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji. Nigbati àwọn Ajagun dé lati gbé Olóri Ogun Aguiyi Ironsi lọ, gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá, Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi bẹ̀bẹ̀ ki wọn fi àlejò òhun silẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kọ. Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fi ara rẹ ji pé ti wọn ba ma a gbee, ki wọn gbé òhun pẹ̀lú. Nitori eyi àwọn Ológun gbe pẹ̀lú àlejò rẹ wọn si pa wọ́n pọ ni Ìbàdàn.
Ni ọjọ́ kọkandinlọgbọn oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rindinlógún, ilú péjọ pẹ̀lú ẹbi àti ará ni Adó-Èkìtì lati ṣe iranti Olóògbé Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fún iranti iwà iṣòótọ ti ó hù titi dé ojú ikú pẹ̀lú àlejò àti ọ̀gá rẹ Olóri Ogun Aguiyi Ironsi ni aadọta ọdún sẹhin.
ENGLISH TRANSLATION
Yoruba people love visitors. The behaviour that cannot be tolerated from indigene is often waved aside for visitors on the excuse that the visitor did not know better. One of the Yoruba adage said “the debt owed while hosting a visitor, is often paid while the guest is gone”. This showed the extent that Yoruba people will go to ensure they make their guest comfortable.
Before the first Military incursion through a Coup, Ibadan was the capital of Western Region in Nigeria. Fifty years ago, the first Military Head of State, Late Maj. Gen Aguiyi Ironsi merged all the Regions into a Centralised Government to consolidate military rule after taking over from the first Democratic Government after independence from the Colonial Empire. The first military coup was staged on January fifteen, nineteen sixty-six, after seven months of military rule a counter coup was staged against the military government headed by Maj. General Aguiyi Ironsi. Late Lt. Col. Adekunle Fajuyi was then the Military Governor of the Western Region in replacement of the Premier of Western Region, late Chief Ladoke Akintola who was killed during the military coup.
Late Lt. Col. Adekunle Fajuyi was hosting the Head of State, Late Maj. Gen. Aguiyi Ironsi at the Government House Ibadan when the army began the counter coup. On arrival at the State House to arrest the Head of State, his host, Lt. Col. Adekunle Fajuyi in accordance with Yoruba culture of showing concern for their visitors, he pleaded with the military officers to spare his boss. When his plea was refused, he insisted that were they to take him away, they would have to arrest him as well. Both of them were then taken away and were executed together at Ibadan.
On the twenty-ninth of July, twenty sixteen, people gather to support his family at his hometown Ado-Ekiti to mark the fiftieth anniversary of his gallantry and loyalty to his guest and boss, Maj. Aguyi Ironsi to death.
Originally posted 2016-07-29 22:27:39. Republished by Blog Post Promoter