ÌSÌNKÚ IYÃFIN MARGARET THATCHER
Wọn ṣe ẹ̀sìn ìsìnkú fún Olõgbe Iyãfin Margaret Hilda Thatcher – Obìnrin àkọ́kọ́ Olórí Òṣèlú Ìlúọba ni Ọjọ́rú, oṣù kẹrin ọjọ́ kẹtàdìnlógún ọdún ẹgbẹrunmejiIemẹtala. Ọmọ ọdún mẹtadinladọrun ni nigbati ó dágbére fún ayé ni oṣù kẹrin ọjọ kẹjọ, ọdún ẹgbẹrunmejilemẹtala.
Yorùbá ni “Òkú nsukun òkú, akáṣolérí nsukun ara wọn” ìtumọ̀ èyí ni wípé kò sẹ́ni tí kò ní kú, olówó, aláìní, ọmọdé, arúgbó, Òṣèlú, Ọba àti Ìjòyè á kú tí àsìkò bá tó, nitorina, ẹni to sunkun, sunkun fún ara rẹ, ẹni tó mbinu, mbinu ara rẹ nitori, ẹni tó kú ti lọ.
Ojúọjọ́ dára, ètò ìsìnkú nã lọ dédé láìsí ìdíwọ́.
Sunre o, Olõgbe Iyãfin Margaret Hilda Thatcher, ó dìgbà.
ENGLISH TRANSLATION
The funeral service for Late Baroness Margaret Hilda Thatcher – the first female Prime Minister in the United Kingdom, was held on Wednesday, April 17, 2013, she bade the world farewell on April 8, 2013. She passed on at the age of 87.
A Yoruba adage says: “The dead is weeping for the dead, while the mourners are weeping for themselves”, this means that there is no one who will not die: rich, poor, young, old, Politicians, King/Queen and Chiefs will die when it is time, as a result, those weeping are weeping for themselves, those angry are angry at themselves because the dead is gone.
The weather was good, the funeral service went well without any hitch.
Sleep on, Late Baroness Margaret Hilda Thatcher, farewell.
Read the article referred to by this post at at http://www.bbc.co.uk/news/uk-22151589