ÓDÌGBÀ, ÓDÌGBÓṢE, ÌYÁÀFIN MARGARET THATCHER: Farewell Prime Minister Thatcher

Former UK Prime Minister Margaret Thatcher, love her or hate her, she broke new ground for women everywhere. Image is from the BBC, click the image to read the BBC article.

Òkìkí ikú Ìyáàfin Margaret Thatcher, obìnrin àkọ́kọ́ lati dé ipò Olórí Òṣel̀ú Ìlúọba kàn ní oṣù kẹrin, ọjọ́ kẹjọ, ọdún ẹgbẹ̀rúnméjìlémẹ́tàlá.

Ebenezer Obey, ọ̀gá pàtàkì nínú olórin Jùjú ní ilẹ̀ aláwọ̀dúdú àti àgbáyé kọ̃ lórin wípé “kò sọ́gbọ́n tolèdá, kò síwà tolèhù, kò sọ́nà tolèmọ̀, tolèfi táyé lọ́rùn, ilé ayé fún gbà díẹ̀ ni, ọmọ aráyé ẹ ṣe rere”.  Orin yi ba ìgbà ayé Olõgbe Ìyáàfin Margaret Thatcher mu.  Gẹ́gẹ́bí Obìnrin àkọ́kọ́ tó di Olórí Òṣèlú Ìlúọba, ó ṣe ìwọ̀n tó lèṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ìlù rẹ̀.  Bi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti nṣe ìrántí rẹ fún iṣẹ́ ribiribi to ṣe lóríoyè, bẹ̃ni àwọn kan bu ẹnu àtẹ́ lu͂.

Ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀ ni “Lẹ́hìn ọkùnrin tó ṣorire, obìnrin wa nbe”, ṣùgbọ́n wíwo ìgbésí ayé àwọn og̀bójú obìnrin bi Olõgbe Fúrnmiláyọ̀ Ransome Kútì àti Olõgbe Margaret Thatcher fihàn wípé “lẹ́hìn obìnrin tó bá́ ṣe orire, ọkùnrin wa nbẹ”, ọkọ wọn dúró tìwọn gbọingbọin, èyí fi ọkàn àwọn aṣájú nínú àwọn obìnrin àgbáyé yi balẹ̀ lati tọ́jú àwọn ọmọ pẹ̀lú iṣẹ́ Òṣèlú tí obìnrin kò wọ́pọ̀ lásìkò tiwọn.  A tún ri ẹ̀kọ́ kọ wípé “kòsí ohun ti ọkùnrin ṣe ti obìnrin kò lè ṣe dãda” nítorí Olõgbe Ìyáàfin Fúnmiláyọ̀ Ransome Kútì ṣe iṣẹ́ ribiri lati kọ ìwọ̀sí àti jà fún obìnrin ni ilẹ̀ Yorùbá àti ni ilẹ̀ aláwọ̀dúdú, bẹ͂ni Ìyáàfin Margaret Thatcher ṣe iṣẹ́ tómú ìlọsíwájú bá ara iìúọba lai wo ariwo ọjà.

Sùn re o, Ìyáàfin Thatcher.

ENGLISH TRANSLATION

The report of the death of Mrs Margaret Thatcher was announced on Monday, April 8, 2013.

As a prominent Juju Musician, Ebenezer Obey once sang, “there is no amount of wisdom, character or any way you know, that can please the entire world, life is short, and human beings should do  good”.   This song is apt in reference to the life of the late Mrs Margaret Thatcher.  As the first female Prime Minister of the United Kingdom, she did her best for the love of her country.   As many are remembering her for great contributions during her time as the Prime Minister many others are some condemning the period.

A popular adage says “Behind every successful man, there is a woman”, but looking at the lives of stern women like Funmilayo Ransome Kuti and Mrs Margaret Thatcher makes one think that “behind every successful woman, there is a man”, their husbands stood strongly with them, this gave them the peace of mind of combining raising children with politics even back when women were rare in politics.  There is another lesson learnt from the saying that “what a man can do, a woman can do better”, as Late Funmilayo Kuti fought gallantly for women in Yoruba land as well as in Africa while Late Mrs Margaret Thatcher did her best to bring progress to the United Kingdom without concentrating on distractions.

Rest in peace Prime Minister Thatcher.

Share Button

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.