“Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan”: “A borrowed trouser/pant, if it is not too loose on the legs, it is too tight at the thigh”.

Ìwà àti ìṣe ọ̀dọ́ ìgbàlódé, kò fi àṣà àti èdè Yorùbá hàn rárá.

Aṣọ àlòkù ti gbòde, dipò aṣọ ìbílẹ̀.  Ọpọlọpọ aṣọ àgbàwọ̀ yi kò wà fún ara àti lilò ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú.  Ọ̀dọ́ miran a wọ asọ àti bàtà òtútù ninu ooru.  Ọ̀pọ̀ Olùṣọ́-àgùntàn àti Oníhìnrere, ki wọ́ aṣọ ìbílẹ̀, wọn a di bi ìrẹ̀ pẹ̀lú aṣọ òtútù.

Èdè ẹnu wọn kò jọ Oyinbo, kò jọ Yorùbá nitori àti fi ipá sọ èdè Gẹẹsi.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan”.  Bi a bá wo òwe yi, àti tun ṣòkòtò àgbàwọ̀ ṣe lati báni mu, ni ìnáwó púpọ̀ tàbi ki ó má yẹni.  Bi a bá fi òwe yi ṣe akiyesi, aṣọ àlòkù ti wọn kó wọ̀ ìlú npa ọrọ̀ ilẹ̀ wa.  Àwọn ti ó rán-aṣọ àti àwọn ti ó hun aṣọ ìbílẹ̀, ko ri iṣẹ́ ṣe tó nitori aṣọ àlòkù/òkèrè ti àwọn ọdọ kó owó lé .  A lè fi òwe yi bá àwọn ti ó nwọ aṣọ-alaṣọ àti àwọn ti ó fẹ́ gbàgbé èdè wọn nitori èdè Gẹẹsi wi.  Òwe yi tún bá àwọn Òṣèlú ti ó nlo àṣà Òṣè́lú ti òkè-òkun/Ìlú-Oyinbo lai wo bi wọn ti lè tunṣe lati bá ìlú wọn mu.

Atunse aṣọ àlòku ju àti rán aṣọ ni titun lọ.  Ki Òṣèlú bá àwọn ará ìlú jíròrò lati ṣe òfin àti àṣà àti dari ìlú, dára ju pé ki á gba àṣà aláṣà lọ.

ENGLISH LANGUAGE

Attitude and action of the youths of nowadays, is not portraying the Yoruba culture and the language.

Second hand clothing has taken over the place of traditional/local clothing.  Many second hand/borrowed clothes are not fit for Africans in shapes and style.  Some youths even wear winter jackets and shoes in the intense heat.  Many of the Pastors and Evangelists, would not put on local/traditional clothes, instead they dressed like cricket in suit and tie.

Their language is not pure English or pure Yoruba all because of forcing themselves to speak English.

Yoruba proverb that said “A borrowed trouser/pant, if it is not too loose on the legs, it is too tight at the thigh”.  If we examine this proverb, amending a borrowed/imported second hand trouser/pant is more tedious, expensive and may not even fit.  If we use this proverb to support the fact that imported second hand clothing are impoverishing our people as it is killing our economy.  Local fabric makers and dress makers’ sales are affected as a result of the youth’s investment on imported clothing.  The proverb also applied to those whose fashion is dependent on borrowed clothes and those who have forgotten their language because of English.  It also applied to the Politicians who copied the style of politics from abroad/Europe without the thought of tailoring it to the need of their people.

Amending imported second hand clothes is more expensive than some new clothes.  The Politicians should reason with their citizens to fashion out the law and style of politics, suitable for leading their people than copying.

Share Button

Originally posted 2013-09-13 16:33:18. Republished by Blog Post Promoter

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.