“ABD” ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ni èdè Yorùbá́ – Alphabets is the beginning of words in Yoruba Language

Bi ó ti ẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ nipa “abd” ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kikọ ni èdè Yorùbá sẹhin, a tu kọ fún iranti rẹ ni pi pè, kikọ àti lati tọka si ìyàtọ̀ larin ọ̀rọ̀ Yorùbá àti ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́si.

Fún àpẹrẹ, èdè Gẹ̀ẹ́si ni ibere oro mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nigbati èdè Yorùbá ni marun-din-lọgbọn.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn àwòrán ti o wa ni oju ewe wonyi:

ENGLISH TRANSLATION

Even though we have written about Yoruba Alphabets in the past, it is being re-written to remind  readers on how it is pronounced, written and to point out the difference between the Yoruba and English Alphabets.

For example, English Alphabets are made up of twenty-six letter while Yoruba Alphabets are twenty-five.  Check out the slides on this page.

Diference between Yoruba & English Alphabets

View more presentations or Upload your own.
Share Button

Originally posted 2014-02-04 19:04:40. Republished by Blog Post Promoter

“Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ – Ọdún wọlé dé”: “One who acts moderately will not be disgraced – The Festive Period is here”

Ọdún Kérésì jẹ́ ọdún Onigbàgbọ́ lati ṣe iránti ọjọ́ ibi Jésù Olùgbàlà.  Ọjọ́ kẹjọ lẹhin ọdún Kérésìmesì ni ọdún  tuntun.  Fún ayẹyẹ ọdún, kò si iyàtọ̀ laarin Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ni ilẹ̀ Yorùbá nitori Yorùbá gbà wi pé “Ẹni ọdún bá láyé, ó yẹ kó dúpẹ́”.  Ọpẹ́ ló yẹ ki èniyàn dá ju igbèsè ji jẹ lati ṣe àṣe hàn ni àsikò ọdún.

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, àwọn Àgbẹ̀ á dari wálé pẹ̀lú irè oko pàtàki iṣu.  Àwọn Oniṣòwò á ri ọjà tà nitori àsikò yi ni Bàbá àti Ìyá ma nrán aṣọ ọdún fún àwọn ọmọdé àti oúnjẹ rẹpẹtẹ fún ipalẹ̀mọ́ ọdún.  Inú ọmọdé ma ndùn nitori asiko yi ni wọn nse irẹsi àti pa adiẹ fún ọdún.  Àwọn ọmọdé á lọ lati ilé ẹbi kan si ekeji, ẹbi ti wọn lọ ki, á fún wọn ni oúnjẹ àti owó ọdún.  Àwọn àgbàlagbà naa ma ndá aṣọ ẹgbẹ́ fún idúpẹ́ ọdún, ṣùgbọ́n ki owó epo rọ̀bi tó gba igboro, ki ṣe aṣọ olówó nla bi ti ayé òde òni.

Àsikò ti olè npọ̀ si niyi pàtàki ni ilú Èkó, nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ fẹ na owó ti wọn kò ni lati ṣe ọdún.  Ìpolówó ọjà pọ̀ ni àsikò yi ni Òkè-Òkun, nitori eyi, ọ̀pọ̀ nlo ike-igbèsè tàbi ki wọn ya owó-èlè lati ra ọjà ti wọn kò ni owó rẹ.  Lẹhin ọdún, wọn a fi ọdún tuntun bẹ̀rẹ̀ si san igbèsè, nitori eyi Ìyá àti Bàbá a ma a ti ibi iṣẹ́ kan lọ si ekeji lai ni ìsimi tàbi ri àyè àti bójú tó àwọn ọmọ.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ wi pé “Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ ”, nitori eyi gbogbo ọmọ Yorùbá ni ilé, ni oko, ẹ ṣe bi ẹ ti mọ, ẹ ma tori odun na ọwọ́ si nkan ti ọwọ́ yin kò tó, ki ẹ ma ba a tẹ́.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Onigbàgbọ́  ayé òde oni ki i fẹ fi èdè Yorùbá kọrin ṣùgbọ́n ẹ gbọ́ bi ọmọ Òyinbó ti kọ orin àwọn “Obinrin Rere” ni ojú iwé yi.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-18 23:18:09. Republished by Blog Post Promoter

“Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan” – “Poverty is lonesome while success has many siblings”

Ni ayé igbà kan, bi èniyàn bá jẹ́ alágbára, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, ti ó si tún ni iwà ọmọlúwàbí, iyi wà fun bi kò ti ẹ ni owó, ju olówó rẹpẹtẹ ti kò si ẹni ti ó mọ idi owó rẹ ni áwùjọ tàbi ti kò hùwà ọmọlúwàbí.  Ni ayé òde òni, ọ̀wọ̀ wà fún olówó lai mọ idi ọrọ̀, eyi ló njẹ ki irú àwọn bẹ́ ẹ̀ dé ipò Òsèlú, Olóri Ìjọ tàbi gba oyè ti kò tọ́ si wọn.

Ìbẹ̀rù òṣì lè jẹ́ ki èniyàn tẹpá-mọ́ṣẹ́, bẹ ló tún lè jẹ́ ki ọ̀pọ̀ fi ipá wá owó.  Ìfẹ́ owó tó gba òde kan láyé òde òni njẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ jalè tàbi wá ipò agbára ti ó lè mú ki wọn ni owó ni ọ̀nà ti kò tọ́.  Òṣèlú ki fẹ́ gbé ipò silẹ̀ nitori ìbẹ̀rù pé bi agbára bá ti bọ́, ìṣẹ́ dé.  Àpẹrẹ tani mọ̀ ẹ́ ri pọ̀ lára àwọn Òsèlú ti agbára bọ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba ti ipò rẹ bọ́, Olóri Ìjọ ti ó kó ọrọ̀ jọ ni orúkọ Ọlọrun ló nri idá mẹwa gbà ju Olóri Ìjọ ti kò ni owó.

Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan” fi hàn pé owó dára lati ni, ṣùgbọ́n kò dára lati fi ipá wá ni ọ̀nà ẹ̀bùrú.  Kò yẹ ki èniyàn fi ojú pa ẹni ti kò ni rẹ́ tàbi sá fún ẹbi ti kò ni, nitori igbà layé, igb̀a kan nlọ, igbà kan mbọ̀, ẹni ti ó ni owó loni lè di òtòṣì ni ọ̀la, ẹni ti kò ni loni lè ni a ni ṣẹ́ kù bi ó di ọ̀la.  Nitori eyi, iwà ló yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ki i ṣe owó tàbi ipò.

ENGLISH TRANSLATION

In time past, if a person is strong, hard working with good moral character, such person is honoured even though he/she may not be rich rather than a very rich person whose source of Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-19 15:23:07. Republished by Blog Post Promoter

Ọba titun, Ọọni Ifẹ̀ Kọkànlélaadọta gba Adé – The new Monarch, Ooni of Ife Received his Crown

Ọọni Ifẹ̀ Kọkànlélaadọta gba Adé – Ooni of Ife Oba Enitan Ogunwusi after receiving the AARE Crown from the Olojudo of Ido land on Monday PHOTOS BY Dare Fasub

Ilé-Ifẹ̀ tàbi Ifẹ̀ jẹ ilú àtijọ́ ti Yorùbá kà si orisun Yorùbá.  Lẹhin ọjọ mọ́kànlélógún ni Ilofi (Ilé Oyè) nigbati gbogbo ètùtù ti ó yẹ ki Ọba ṣe pari, Ọba Adéyẹyè Ẹniitàn, Ògúnwùsi gba Adé  Aàrẹ Oduduwa ni ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kọkànlá ọdún Ẹgbàálemẹ͂dógún ni Òkè Ọra nibiti Bàbá Nlá Yorùbá Oduduwa ti kọ́kọ́ gba adé yi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin.

Ọba Ogunwusi, Ọjaja Keji, di Ọba kọkànlélaadọta Ilé Ifẹ̀, lẹhin ti Ọba Okùnadé Sijúwadé pa ipò dà ni ọjọ́ kejidinlọgbọn, oṣù keje odun Ẹgbàálemẹ͂dógún.

Gẹ́gẹ́ bi àṣà àdáyébá, ẹ͂kan ni ọdún nigba ọdún  Ọlọ́jọ́ ti wọn ma nṣe ni oṣù kẹwa ọdún ni Ọba lè dé Adé Aàrẹ Oduduwa.

Adé á pẹ́ lóri o, bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀.  Igbà Ọba Adéyẹyè Ẹniitàn, Ògúnwùsi á tu ilú lára.lè dé Adé Àrẹ Oduduwa.

 

 

ENGLISH TRANSLATION

Ile-Ife or Ife is an ancient Yoruba Town that is regarded as the origin of the Yoruba people.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-11-24 20:04:10. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀YÀ ARA – ÈJÌKÁ DÉ ẸSẸ̀: PARTS OF THE BODY – SHOULDERS TO TOES

You can also download the mp3 by right clicking here: Parts of the body in Yoruba – shoulders to toes (mp3)
Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-23 21:34:14. Republished by Blog Post Promoter

“Obinrin ki ṣe Ẹrú tabi Ẹrù ti wọn njẹ mọ́ Ogún – Àsikò tó lati Dáwọ́ Àṣà ṣì Ṣúpó Dúró” – “Women are not Slaves nor Property that can be inherited – “It is Time to Stop Bequeathing Widows to the Next-of-Kin.”

 Yorùba Dáwọ́ Àṣà ṣì Ṣúpó Dúró – Yoruba Stop Bequeathing Widows.  Courtesy: @theyorubablog

Yorùba Dáwọ́ Àṣà ṣì Ṣúpó Dúró – Yoruba Stop Bequeathing Widows. Courtesy: @theyorubablog

Ni ayé àtijọ́, àṣà ṣì ṣúpó wọ́pọ̀ ni Ilẹ̀ Yorùbá. Obinrin ti ọkọ rẹ̀ bá kú wọn yio fi jogún gẹ́gẹ́ bi iyàwó fún ọmọ ọkọ ọkùnrin tàbi ẹbi ọkọ ọkùnrin. Eleyi wọ́pọ̀, pàtàki ni idilé Ọba, Ìjòyè nla, Ọlọ́rọ̀ ni àwùjọ àti àgbàlagbà ti ó fẹ́ iyàwó púpọ̀.  Bi Ọba bá wàjà, Ọba titun yio ṣu gbogbo iyàwó ti ó bá láàfin lópó.

Ni ayé ọ̀làjú ti òde òni, àṣà ṣì ṣúpó ti din kù púpọ̀, nitori ẹ̀sìn àti àwọn obinrin ti ó kàwé ti ó si ni iṣẹ́ lọ́wọ́ kò ni gbà ki wọn ṣú ohun lópó fún ẹbi ọkọ ti kò ni ìfẹ́ si.  Ọkùnrin ni ẹbi ọkọ na a ti bẹ̀rẹ̀ si kọ àṣà ṣì ṣúpó silẹ̀ pàtàki àwọn ti ó bá kàwé, nitori ó ti lè ni iyàwó tàbi ki ó ni àfẹ́sọ́nà.  Lai ti ẹ ni iyàwó, ọkùnrin ẹbi ọkọ lè ma ni ìfẹ́ si iyàwó ti ọkọ rẹ̀ kú.  Àṣa ṣì ṣúpó kò wọ́pọ̀ mọ laarin àwọn ti ó jade, àwọn ti ó ngbé ilú nla àti Òkè-òkun tàbi àwọn ti ó kàwé, ṣùgbọ́n ó wọ́pọ̀ laarin àwọn ti kò jade kúrò ni Abúlé àti àwọn ti kò kàwé.

Idilé ti ifẹ bá wà laarin ẹbi, iyàwó pàápàá kò ni fẹ́ kúrò ni irú ẹbi bẹ́ ẹ̀ lati lọ fẹ́ ọkọ si idilé miran pàtàki nitori àwọn ọmọ tàbi ó dàgbà jù lati tun lọ fẹ ọkọ miran.  Ọmọ ọkọ tàbi ẹbi ọkọ ọkùnrin lè fi àṣà yi kẹ́wọ́ lati fẹ opó ni tipátipá, omiran lè pa ọkọ lati lè jogún iyàwó. Bi iyàwó bá kú, wọn kò jẹ́ fi ọkọ rẹ jogún fún ẹbi iyàwó.

Àsikò tó lati dáwọ́ àṣà ṣì ṣúpó dúró nitori obinrin ki ṣe ẹrú tàbi ẹrù ti wọn njẹ mọ́ ogún.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-09-18 19:53:23. Republished by Blog Post Promoter

“Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” – “Not all that glitters is Gold”

Wúrà jẹ ikan ninú ohun àlùmọ́ni iyebiye, pàtàki fún ohun ẹ̀ṣọ́.  Ẹwà Wúrà ki hàn, titi di ìgbà ti wọn bá yọ gbogbo ẹ̀gbin rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iná tó gbóná rara.    Àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi fihàn pé bi Wúrà bá ti pọ̀ tó lára ohun ẹ̀sọ́ ló ṣe má wọn tó, ki ṣé bi ohun ẹ̀ṣọ́ bá ti dán tó tàbi tóbi.  Fún àpẹrẹ, àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà kini tóbi, ó si dán ju àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà keji, ṣùgbọ́n ohun ẹ̀sọ́ Wúrà ninú aworan keji wọn ju ohun eso Wúrà kini ni ìlọ́po mẹwa.  Ìyàtọ̀ ti ó wà ni Wúrà gidi àti àfarawé ni pé, Wúrà gidi ṣe é tà fún owó iyebiye lẹhin ti èniyàn ti lo o, kò lè bàjẹ, bi ó bá kán, ó ṣe túnṣe; ṣùgbọ́n àfarawé kò bá ara ẹlòmiràn mu, bi ó bá kán, kò ṣe é túnse; kò ki léwó.

Gẹ́gẹ́bi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà”, bẹni ki ṣe gbogbo  èniyàn ti wọ̀n pè ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ló tó bi àwọn èniyàn ti rò.  Ọ̀pọ̀ irú àwọn wọnyi, jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati ṣe àṣe hàn, òmiràn ja olè, gbọ́mọgbọ́mọ àti onirúurú iṣẹ́ ibi yoku.  Gbogbo ohun ti wọn fi ọ̀nà èrú kó jọ wọnyi kò tó nkankan lára ọrọ̀ ti ẹlòmiràn ti ó ni iwà-irẹ̀lẹ̀ ni.  Fún àpẹrẹ, owó ti àwọn Òṣèlú àti Òṣiṣẹ́-Ìjọba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fi èrú kó jọ, ti wọn nkó wá si Òkè-òkun tàbi fi mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú, kò tó ọrọ̀ ti ọmọdé ti ó ni ẹ̀bun-Ọlọrun ni Òkè-òkun ni.

A lè fi òwe “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” gba ẹnikẹ́ni ni iyànjú pé ki wọn ma ṣe àfarawé, tàbi kánjú lati kó ọrọ̀ jọ.  Àfarawé léwu, nitori ki ṣe gbogbo ohun ti èniyàn ri ló mọ idi rẹ̀.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-30 22:55:23. Republished by Blog Post Promoter

“Ògòngò lọba ẹiyẹ” – “Ostrich is the King of Birds”

Ògòngò - Ostrich.  Courtesy: @theyorubablog

Ògòngò – Ostrich. Courtesy: @theyorubablog

Ògòngò jẹ ẹiyẹ ti ó tóbi jù ninú gbogbo ẹiyẹ, ẹyin rẹ ló tún tóbi jù.  Ọrùn àti ẹsẹ̀ rẹ ti ó gún jẹ́ ki ó ga ju gbogbo ẹiyẹ yoku.  Ògòngò ló lè sáré ju gbogbo eiye lọ lóri ilẹ̀.  Eyi ló jẹ́ ki Yorùbá pe Ògòngò ni Ọba Ẹiyẹ.  Ọpọlọpọ ẹiyẹ bi Ògòngò kò wọ́pọ̀ mọ́ nitori bi ilú ti nfẹ si bẹni àwọn eiye wọnyi nparẹ́, a fi bi èniyàn bá lọ si Ilé-ikẹransi lati ri wọn.

Àwọn onírúurú ẹiyẹ ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá, àwọn eyi ti ó wọ́pọ̀ ni ilú tàbi ilé (ẹiyẹ ọsin)ni, Adiẹ (Àkùkọ àti Àgbébọ̀ adiẹ), Pẹ́pẹ́yẹ, Ẹyẹlé, Awó, Ayékòótó/Odidẹrẹ́ àti Ọ̀kín.  Àwọn ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ninú igbó ṣùgbọ́n ti ará ilú mọ̀ ni: Àṣá, Ìdì, Òwìwí, Igún/Àkàlàmàgbò àti Lekeleke.  Àwọ̀ oriṣirisi ni ẹiyẹ ni, irú ẹiyẹ kan lè ni àwọ̀ dúdú bi aró, kó́ tun ni pupa tàbi funfun, ṣùgbọ́n orin Yorùbá ni ojú ewé yi fi àwọ̀ ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ẹiyẹ miran hàn.  Fún àpẹrẹ, Lekeleke funfun bi ẹfun, Agbe dúdú bi aró, bẹni Àlùkò pọn bi osùn. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àti pipè orúkọ di ẹ ninú àwon ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ni ojú ewé yi.

Agbe ló laró ————— ki rá ùn aró
Àlùkò ló losùn ———— ki rá ùn osùn
Lekeleke ló lẹfun ——– ki rá ùn ẹfun
Ka má rá ùn owó, ka má rá ùn ọmọ
Ohun tá ó jẹ, tá ó mu, kò mà ni wọn wa ò.

ENGLISH TRANSLATION

Ostrich is the biggest and has the largest eggs among the birds.  The long neck and legs made it taller than all the other birds.  Ostrich is also the fastest runner on land more than all the birds.  This is why Yoruba crowned Ostrich as the King of Birds.  Many wild birds such as Ostrich are almost extinct as a result of the expansion of towns and cities displacing the wild birds which can now be seen at the Zoo.

There are various types of birds in Yoruba land, the most common at home or in town (domestic birds) are: Chicken (Cock and Hen), Duck, Pigeon, Guinea Fowl, Parrot, and Peacock.  The common wild birds that are known in the town or communities are: Falcon/Kite, Eagle, Owl, Vulture and Cattle-egret.  Birds are of various colours, one species of bird can come in various colours, while some are black like the dye, some are red like the camwood, and some are white, but the Yoruba song on this page depicted the common colours that are peculiar with some species of birds.  For example, Cattle-Egret are white like chalk, Blue Turaco are coloured like the dye and Red Turaco are reddish like the camwood.   Check out the pictures and prononciation of some of the birds that are common in Yoruba land on this page.

Share Button

Originally posted 2014-10-17 12:27:16. Republished by Blog Post Promoter

Síse Àpọ̀n – Preparing Wild Mango Seed Soup

Ẹ fọ ẹja, edé àti irú, ẹ dàápọ̀ pẹ̀lú ẹran bibọ, ẹja gbígbẹ, iyọ̀, irú, iyọ̀ igbàlódé àti omi sinú ikòkò kan. Ẹ gbe ka iná fún sisè.  Bi ẹ ti nse lọ, ẹ da epo-pupa sinú ikòkò keji.  Ẹ yọ epo díẹ̀, ki ẹ da àpọ̀n si lati yọ àpnọ̀ yi, bi ó ba ti gbónọ́ díẹ̀, ẹ da gbogbo èlò ọbẹ̀ inú ikòkò kini ni gbí-gbónọ́ sinú ikòkò keji ti epo àti àpọ̀n wa.  Ẹ ro pọ, ẹ yi iná rẹ silẹ̀ díẹ, ki ẹ ro titi yio fi jiná.  Ti ọbẹ̀ na bá ki jù, ẹ bu omi gbi-gbónọ́ díẹ si titi yio ri bi ẹ ṣe fẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-20 10:15:26. Republished by Blog Post Promoter

“Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà” – “Headship of a Family is the Father of Responsibilities”

Olóri Ẹbi - Head of the Family connotes responsibiliies.  Courtesy: @theyorubablog

Olóri Ẹbi – Head of the Family connotes responsibiliies. Courtesy: @theyorubablog

Olóri Ẹbi jẹ àkọ́bi ọkùnrin ni idilé.  Bi àkọ́bi bá kú, ọkùnrin ti ó bá tẹ̀le yio bọ si ipò.  Iṣẹ́ olóri ẹbi ni lati kó ẹbi jọ fún ilọsiwájú ẹbi, nipa pi pari ijà, ijoko àgbà ni ibi igbéyàwó, ìsìnkú, pi pin ogún, ìsọmọ-lórúkọ, ọdún ìbílẹ̀ àti ayẹyẹ yoku.

Ni ayé òde òni, wọn ti fi owó dipò ipò àgbà, nitori ki wọn tó pe olóri ẹbi ti ó wà ni ìtòsí, wọn yio pe ẹni ti ó ni owó ninú ẹbi ti ó wà ni òkèrè pàtàki ti ó bá wà ni Èkó àti àwọn ilú nla miran tàbi Ilú-Òyinbó/Òkè-Òkun. Ai ṣe ojúṣe Ìjọba nipa ipèsè ilé-iwòsàn ti ó péye, Ilé-iwé, omi mimu àti ohun amáyédẹrùn yoku jẹ ki iṣẹ́ pọ fún olóri ẹbi.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ wi pé “Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà”, iṣẹ́ nla ni lati jẹ Olóri Ẹbi, ó gba ọgbọ́n, òye àti ìnáwó lati kó ẹbi jọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-02-12 10:30:05. Republished by Blog Post Promoter