Category Archives: Yoruba Food

English words for Yoruba food, a life saver if you end up in a Nigerian restaurant and want a leg up on the menu.

Ohun jíjẹ pàtàki ti à ńfi Iṣu Ewùrà ṣe: Ìfọ́kọrẹ́ tàbi Ìkọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀.

Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ìfọ́kọrẹ́/Ìkọ́kọrẹ́ lójú iwé yi.

Gbé epo kaná
Kó èlò bi ẹ̀jà tútù tàbi gbigbẹ, edé, pọ̀nmọ́ sinú ikòkò epo-pupa yi
Fi iyọ̀ àti iyọ̀ igbàlódé àti omi si inú ikòkò yi lati se omi ọbẹ ìkọ́kọrẹ́
Fọ Iṣu Ewùrà kan
Bẹ Ewùrà yi
Rin iṣu yi (pẹ̀lú pãnu ti a dálu lati fi rin gãri, ilá tàbi ewùrà)
Fi iyọ̀ bi ṣibi kékeré kan po ewùrà ri-rin yi
Ti ó bá ki, fi omi diẹ si lati põ
Lẹhin pi pò, dá ewùrà pi pò yi sinú omi ọbẹ̀ ti a ti sè fún bi iṣẹ́jú mẹdogun
Rẹ iná rẹ silẹ̀, se fún bi ogún iṣẹ́jú
Ro pọ
Lẹhin eyi bu fún jijẹ.

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-03-28 20:26:48. Republished by Blog Post Promoter

Ìpanu – “Kẹ́nu ma dilẹ̀ ni ti gúgúrú, gúgúrú ki ṣe oúnjẹ àjẹsùn”: Snacks – “Popcorn is eaten to keep the mouth busy, it is not an ideal night meal”.

Oúnjẹ òkèlè ni Yorùbá mọ̀ si oúnjẹ gidi.  Ni ọ̀pọ̀ igbà oúnjẹ òkèlè ni oúnjẹ àjẹsùn, ṣùgbọ́n ìpanu ni ohun amú inú dúró ni ọ̀sán.  Àwọn ìpanu bi gúgúrú àti ẹ̀pà, bọ̃li àti ẹ̀pà, gaàrí àti ẹ̀pà àti bẹ̃bẹ lọ ni Yorùbá njẹ ni ọ̀sán lati mu inu dúró ki wọn tó jẹ́ oúnjẹ alẹ́.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àwọn ìpanu wọnyi ni ojú iwé yi.

Bọli – Roasted Plantain.  Courtesy: @theyorubablog

Bọli – Roasted Plantain. Courtesy: @theyorubablog

ENGLISH TRANSLATIONS Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-10-31 17:33:49. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹgbẹ́ Iṣu kọ́ ni Ewùrà – Ìfọ́kọrẹ́/Ìkọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀ là ńfi Ewùrà ṣe”: Water Yam is no match for the Yam – Water Yam is used for Pottage and Fried Water Yam Fritters

Ewùrà - Water Yam.  Courtesy: @theyorubablog

Ewùrà – Water Yam. Courtesy: @theyorubablog

Ẹbi Iṣu ni Ewùrà ṣùgbọ́n a lè pe Iṣu ni ẹ̀gbọ́n Ewùrà nitori ohun ti a lè fi Iṣu ṣe gbayì laarin gbogbo Yorùbá ju eyi ti a lè fi Ewùrà ṣe.  Ọpọlọpọ Yorùbá fẹran oúnjẹ òkèlè bi iyán àti àmàlà ti o gbayì ni ọpọlọpọ ilẹ̀ Yorùbá.  Ohun miran ti wọn ńfi iṣu ṣe ni: Àsáró, iṣu sisè, iṣu sí-sun, iṣu dín-dín àti àkàrà iṣu.

Oúnjẹ ti ó wọ́po laarin àwọn Ijẹbu ti a ńfi Ewùrà ṣe ni “Ìfọ́kọrẹ́” tàbi bi àwọn ọmọdé ti ma ńpe “Ìkọ́kọrẹ́” ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ Yorùbá na fẹ́ràn Ìfọ́kọrẹ́. A lè jẹ Ìfọ́kọrẹ́ lásá̀n, àwọn miran lè fi jẹ ẹ̀bà.  A tún lè lo Ewùrà lati ṣe “Ọ̀jọ̀jọ̀” (àkàrà iṣu ewùrà).  Ọ̀pọ̀ Ewùrà sisè kò dùn lati jẹ bi iṣu gidi.   Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ìfọ́kọrẹ́/Ìkọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀ lójú iwé yi

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-03-26 00:39:19. Republished by Blog Post Promoter

ẸGBẸ́́ YORÙBÁ NÍ ÌLÚỌBA: Finding Yoruba Food in the UK (Dalston Kingsland)

Yorùbá ní “Bí ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ, á dọṣẹ”,ọ̀rọ̀ yí bá ẹgbẹ́ Yorùbá ni Ìlúọba mu pàtàkì àwọn ti o ngbe ni Olú Ìlúọba.  Títí di bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, àti rí oúnjẹ Yorùbá rà ṣọ̀wọ́n.  Ní àpẹrẹ, àti ri adìẹ tó gbó rà lásìkò yi, à fi tí irú ẹni bẹ̃ bá lọ si òpópó Liverpool,  ṣùgbọ́n ní ayé òde òni, kòsí agbègbè ti ènìà kò ti lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá ra.

Lati bi ogún ọdún sẹ́hin, Yorùbá ti pọ̀si nidi àtẹ oúnjẹ títà ni Olú Ìlúọba.  Nitõtọ, oúnjẹ Yorùbá bi iṣu, epo pupa, èlùbọ́, gãri, ẹ̀wà pupa, sèmó, iyán, ẹran, adìẹ tógbó, ẹja àti bẹ̃bẹ wa ni àrọ́wọ́to lãdugbo.  Ṣùgbọ́n, bí ènìà bá fẹ́ àwọn nkan bí ìgbín, panla, oriṣiriṣi ẹ̀fọ́ ìbílẹ̀, bọkọtọ̃, edé gbígbẹ àti bẹ̃bẹ lọ tí kòsí lãdugbo, á rí àwọn nkan wọnyi ra ni ọjà Dalston àti Kingsland fún àwọn ti o ngbe agbègbè Àríwá àti ọja Pekham fún àwọn ti o ngbe ni agbègbè Gũsu ni Olú Ìlúọba.

Àwòrán àwọn ọjà wọnyi a bẹrẹ pẹ̀lú, Ọja Dalston àti Kingsland.  Ẹ fojú sọ́nà fún àwọn ọja yókù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-05 21:06:49. Republished by Blog Post Promoter

Àwòrán àti pípè orúkọ Èlò Ọbẹ̀ Yorùbá – Pictures and pronunciation of ingredients for Yoruba Soup/Stew/Sauce

Àwọn èlò ọbẹ̀ Yorùbá, ẹni ti ó bá mọ ọbẹ̀ se, yio mọ èlò ọbẹ̀ ti ohun yio ra àti bi yio ti se, ṣùgbọ́n ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se, lè lo owó ai mọye lati se ọbẹ̀, ki ọbẹ̀ rẹ má dùn.  Fún àwọn ti ó ńgbé ni Òkè-Òkun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èlò yi ni a lè ri rà ni àyiká.  Ẹṣe àyẹ̀wò èlòọbẹ̀ àti pípè rẹ ni ojú ewé yi.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba Soup/Stew/Sauce ingredients, for those who know how to prepare it, they know the type of ingredients to buy and combine for cooking, but for bad cooks, he/she can spend lots of amount to cook yet the soup/stew/sauce may be tasteless.  For those living abroad, many of these ingredients can be sourced locally.  Check out list and pronunciation of these ingredients on this page.

 

View more presentations or Upload your own.
Share Button

Originally posted 2014-08-01 18:26:06. Republished by Blog Post Promoter

“Ki Àgbàdo tó di Ẹ̀kọ, a lọ̀ ọ́ pa pọ̀: Ògì Ṣí ṣe” – “For Corn to become Pap it has to be grinded – Pap Making”

Ra Àgbàdo lọ́jà - Buy the Corn

Ra Àgbàdo lọ́jà – Buy the Corn

Àgbàdo ni wọn fi nṣe Ògì.  Ògì ni wọn fi nṣe Ẹ̀kọ́.  Ògì ṣí ṣe fẹ ìmọ́ tótó, nitori eyi, lai si omi, Ògì kò lè ṣe é ṣe.  Ọkà oriṣiriṣi ló wà ṣùgbọ́n, Ọkà Àgbàdo àti Bàbà ni wọn mọ̀ jù lati fi ṣe Ògì funfun tàbi pupa.  A lè lọ àgbàdo funfun àti pupa pọ̀, ẹlòmiràn lè lọ ẹ̀wà Sóyà pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bi àpẹrẹ àwòrán ojú iwé yi

 

 

Ṣí ṣe Ògì

Ra Àgbàdo lọ́jà
Da Àgbàdo rẹ fún ọjọ́ mẹta ninú omi tútù tàbi omi gbi gbóná
Ṣọn Àgbàdo kúrò ninú omi lati yọ ẹ̀gbin bi ò̀kúta kúrò
Gbe lọ si Ẹ̀rọ fún li lọ̀ tàbi gun pẹ̀lú odó lati lọ ọ.
Sẹ́ Ògì pẹ̀lú asẹ́ aláṣọ tàbi asẹ́ igbàlódé
Bẹ̀rẹ̀ si yọ omi ori Ògì si sẹ bi ó bá ti tòrò
Pààrọ̀ omi ori rẹ fún ìtọ́jú rẹ fún ji jẹ tàbi
Da Ògì sinú àpò ki ó lè gbẹ fún ìtọ́jú

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-07-17 23:46:06. Republished by Blog Post Promoter

“Ọbẹ̀ tó dùn, Owó ló pá: Àwòrán àti pi pè Èlò Ọbẹ̀” – “Tasty Soup, Cost Money – Pictures and pronunciation of Ingredients”

Òwe Yorùbá ni “Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pá”, ṣùgbọ́n kò ri bẹ̃ fún ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se.  Elomiran lè lo ọ̀kẹ́ àimọye owó lati fi se ọbẹ̀ kó má dùn nitori, bi iyọ̀ ò ja, ata á pọ̀jù tàbi ki omi pọ̀jù.

Ni tõtọ, owó ni enia ma fi lọ ra èlò ọbẹ̀ lọ́jà, ṣùgbọ́n fún ẹni ti ó mọ ọbẹ̀ se, ìwọ̀nba owó ti ó bá mú lọ si ọjà, ó lè fi ra èlò ọbẹ̀ gẹ́gẹ́ bi owó rẹ ti mọ, ki ó si se ọbẹ̀ na kó dùn.  Ẹ wo àwòrán àti pipè èlò ọbẹ ni abala ojú iwé yi.

View more presentations or Upload your own.

 

View more presentations or Upload your own.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-08 16:30:36. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹ̀mí ti ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ”: “Life devoid of consumption of pepper is trifle”

Ata-ṣọmbọ, Ata-wẹ́wẹ́, Ata-Ijọsin, Ata gbigbẹ, Ata gígún àti awọn èlò ọbẹ̀ – Jalapeno, Serrano, Cayenne & various spices. Courtesy: @theyorubablog

Ata ṣe pàtàki ninu àwọn èlò ọbẹ̀.  Yorùbá ni “Ẹ̀mí ti ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ” nitori eyi, lai si ata ninu ọbẹ̀, ọbẹ̀ o pe.  Ko si ọbẹ̀ Yoruba ti enia ma jẹ lai ni ata, fún àpẹrẹ wọn ki jẹ ila funfun tàbi Ewédú ti wọn se lai ni ata lai bu ata ọbẹ̀ si.

Oriṣiriṣi ata: Ata-rodo, Ata-ṣọmbọ, Ata-wẹ́wẹ́, Ata-Ijọsin, Tataṣe, Ata gbigbẹ, Ata gígún

Àwòrán ata ti ó wá ni ojú ewé yi wọ́pọ̀ ni ọjà Yorùbá.

 

Atarodo – Habanero pepper. Courtesy: @theyorubablog

 

Tataṣe – Bell pepper. Courtesy: @theyorubablog

 

 

 

 

Ọbẹ̀ Yorùbá ti wọn fi ata gígún àti èlò ilẹ̀ wa se ki wọn bi ọbẹ̀ ìgbà lódé ti wọn fi èlò okere se.  Bi nkan ti wọn to ni ilu, a le fi Ẹ̃dẹgbẹrin Naira se ìkòkò àwọn ọbẹ̀ Yorùbá bi: ilá-àsèpọ̀, ẹ̀gúsí funfun, àpọ̀n, àjó àti bẹ̃bẹ lọ fún idile enia mẹfa.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-06 09:00:39. Republished by Blog Post Promoter

“Bi o kò bá lágbára ohun ti o fẹ́, ni ìfẹ́ ohun ti o ni”: “If you cannot afford what you want, then love what you have”

Ẹ kú ipalẹ̀mọ́ ọdún o.  Bi ọdún bá sún mọ́ etílé, oúnjẹ àti ohun èlò gbogbo maa nwọn nitori àwọn ọlọ́jà yio ti fi owó kún ọjà nitori èrò ti ó fẹ́ ra ọjà maa n pọ̀ si ni àsikò yi.  Pa pọ̀ mọ́ ipari ọdún ni àwọn ti ó fi ayẹyẹ iyàwó, òkú, ọdún Kérésìmesì àti ṣíṣe miràn si àsikò yi.

Kò si ẹni ti kò ni nkankan.  Pé èniyàn ni ara li le tàbi ó lè jẹun, ó tó nkan.  Ilẹ̀ Yorùbá ni ohun ọrọ̀ ajé àti oúnjẹ ni oriṣiriṣi tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lati igbà ti Ìjọba àpapọ̀ ti da gbogbo ẹ̀yà orilẹ̀ èdè Nigeria pọ̀ ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si pin owó epo rọ̀bì ni ìfẹ́ oúnjẹ àti ọjà òkèèrè/òkè-òkun ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọ̀lẹ àti ẹni ti kò ni ìrònú.

Oúnjẹ ilẹ̀ wa - Home grown food. Courtesy: @theyorubablog

Oúnjẹ ilẹ̀ wa – Home grown food. Courtesy: @theyorubablog

Àsikò tó lati ṣe àyípadà, ki a jẹ ohun ti a ba gbin ni ilẹ̀ wa, nitori owó epo rọ̀bì ti gbogbo ilú gbójúlé ti fidi janlẹ̀.  Ki owó epo rọ̀bì tó dé, a nfi ìrẹsì ṣe ọdún pàtàki fún àwọn ọmọdé, ṣùgbọ́n iresi ti wọn gbin ni ilẹ̀ wa ni a njẹ.  Bi a ra oúnjẹ ilẹ̀ wa dipò oúnjẹ òkè-òkun, àgbẹ̀ yi o ri owó, a o si mọ irú oúnjẹ ti a njẹ ju ìrẹsì oníke ti wọn nkó wọ ilú.

Ki ṣe dandan ni ki a se ìrẹsì fún ọdún, a lè fi oúnjẹ ẹ̀yà miràn ṣe ọdún fún àwọn ọmọ.  Fún àpẹrẹ, Ìjẹ̀bú lè se ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ rirò àti iyán dipò ìkọ́kọrẹ́ fún ọdún tàbi ki Èkìtì se ìkọ́kọrẹ́ fún ọdún dipò iyán àti ẹ̀fọ́ rirò àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.  Ẹ jẹ́ ki a gbé oúnjẹ ilẹ̀ wa lárugẹ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-12-13 18:51:54. Republished by Blog Post Promoter

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú/burúkú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa” – Plantain – “Unripe/rotten plantain is no easy snack, beating a bad behaved child to death is not an option”.

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ – Bunch of unripe Plantains and Bananas Banana

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ – Bunch of unripe Plantains and Bananas Banana

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ èso ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ohun ọgbin ti a lè ri ni ilẹ̀ Yorùbá pàtàki ni agbègbè Okitipupa ni ipinlẹ Ondo.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ pé oriṣiriṣi, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ni à nsè fun jijẹ, nigbati ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ dára fún jijẹ bi èso lai sè.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tóbi ju ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ lọ.

Ọkọ̀ tó kó Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – Lorry load of Plantain. Courtesy: theyorubablog

Ọkọ̀ tó kó Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – Lorry load of Plantain. Courtesy: theyorubablog

Ni ayé àtijọ́, ohun ọgbin ti ó bá pọ̀ ni agbègbè ni èniyàn ma njẹ, nitori ko si ọkọ̀ tàbi ohun irinna tó yá  lati kó irè oko kan lọ si ekeji.  Eleyi jẹ ki àwọn ti iṣu pọ ni ọ̀dọ̀ wọn lo iṣu lati ṣe oúnjẹ ni oriṣiriṣi ọ̀nà, àwọn ti o ni àgbàdo pupọ nlo fún onírúurú oúnjẹ ti a lè fi àgbàdo ṣe, àwọn ti ó ni ẹ̀gẹ́/gbaguda ma nlo lati ṣe oriṣiriṣi oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìyàtọ laarin iṣu ati ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni pé, wọn wa iṣu ninú ebè nigbati wọn nbẹ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ lóri igi rẹ.  Kò si iyàtọ̀ laarin Èlùbọ́ iṣu àti Èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀, ṣugbon bi a bá ro fun àmàlà, àmàlà iṣu dúdú díẹ ju èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ gbigbẹ, àmàlà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ tútù kò dúdú ó pọ́n fẹ́rẹ́fẹ́.  Iṣu tútù kò ṣe e bùṣán nitori yio yún èniyàn ni ọ̀fun, nibi ti ó burú dé, bi omi ti wọn fi fọ iṣu bá ta si ni lára, yio fa ara yin yún. Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá ti ó ni “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú/burúkú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa”, ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú kò dùn lati jẹ ni tútù, eyi ti ó bá ti kẹ̀ naa kò ṣe é jẹ, ṣùgbọ́n ọ̀gẹ̀dẹ̀ ti ó pọ́n ṣe jẹ ni pi pọ́n lai sè nitori adùn rẹ.  Àti ewé àti èso ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ó wúlò fún jijẹ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-02 19:09:48. Republished by Blog Post Promoter